Tuesday, October 28
[Jèhófà] ló ń mú kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ láwọn àkókò rẹ.—Àìsá. 33:6.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a máa ń níṣòro, a sì máa ń ṣàìsàn bíi tàwọn yòókù. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń fara da àtakò àti inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn tó kórìíra àwa èèyàn Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro, ó ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. (Àìsá. 41:10) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè láyọ̀, ká ṣe ìpinnu tó tọ́, ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí i kódà nígbà tí ìṣòro bá mu wá lómi. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa ní àlàáfíà tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run.” (Fílí. 4:6, 7) Àlàáfíà yìí jẹ́ ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní torí pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àlàáfíà yìí “kọjá gbogbo òye,” ó sì ju gbogbo ohun téèyàn lè rò lọ. Ṣé ìgbà kan wà tó o ní ìdààmú ọkàn, àmọ́ tọ́kàn ẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ lẹ́yìn tó o gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn? “Àlàáfíà Ọlọ́run” ló mú kíyẹn ṣeé ṣe. w24.01 20 ¶2; 21 ¶4
Wednesday, October 29
Jẹ́ kí n yin Jèhófà; kí gbogbo ohun tó wà nínú mi yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.—Sm. 103:1.
Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń yin orúkọ ẹ̀ tọkàntọkàn. Ọba Dáfídì mọ̀ pé tá a bá ń yin orúkọ Jèhófà, Jèhófà náà là ń yìn yẹn. Tá a bá gbọ́ orúkọ Jèhófà, ó máa ń jẹ́ ká rántí àwọn ìwà rere tó ní àti àwọn ohun rere tó máa ń ṣe. Ó wu Dáfídì pé kó ya orúkọ Bàbá ẹ̀ sí mímọ́, kó sì máa yìn ín. Ó sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn pẹ̀lú “gbogbo ohun tó wà nínú” ẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn ọmọ Léfì ló máa ń ṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n bá fẹ́ yin Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n gbà pé kò sí báwọn ṣe lè yin Jèhófà tó bó ṣe yẹ káwọn yìn ín. (Neh. 9:5) Ó dájú pé bí wọ́n ṣe fìrẹ̀lẹ̀ yin Jèhófà, tí wọ́n sì ṣe é tọkàntọkàn máa múnú ẹ̀ dùn gan-an. w24.02 9 ¶6
Thursday, October 30
Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.—Fílí. 3:16.
Jèhófà ò ní sọ pé aláṣetì ni ẹ́ tọ́wọ́ ẹ ò bá tẹ àfojúsùn tágbára ẹ ò gbé. (2 Kọ́r. 8:12) Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn nǹkan tí ò jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ. Máa rántí àwọn nǹkan tó o ti ṣe láṣeyọrí. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín.” (Héb. 6:10) Torí náà, kò yẹ kíwọ náà gbàgbé iṣẹ́ tó o ti ṣe. Ronú nípa àwọn nǹkan tó o ti ṣe láṣeyọrí. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti ṣiṣẹ́ kára láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kó o máa sọ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, o sì ti lè ṣèrìbọmi. Bó o ṣe tẹ̀ síwájú, tọ́wọ́ ẹ sì tẹ àwọn àfojúsùn ẹ láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kó o máa tẹ̀ síwájú kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ní. Inú ẹ máa dùn nígbà tí Jèhófà bá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ. Bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àfojúsùn ẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, jẹ́ kí inú ẹ máa dùn bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó sì ń bù kún ẹ. (2 Kọ́r. 4:7) Torí náà tó ò bá jẹ́ kó sú ẹ, Jèhófà máa bù kún ẹ lọ́pọ̀lọpọ̀.—Gál. 6:9. w23.05 31 ¶16-18