Wednesday, October 29
Jẹ́ kí n yin Jèhófà; kí gbogbo ohun tó wà nínú mi yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.—Sm. 103:1.
Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń yin orúkọ ẹ̀ tọkàntọkàn. Ọba Dáfídì mọ̀ pé tá a bá ń yin orúkọ Jèhófà, Jèhófà náà là ń yìn yẹn. Tá a bá gbọ́ orúkọ Jèhófà, ó máa ń jẹ́ ká rántí àwọn ìwà rere tó ní àti àwọn ohun rere tó máa ń ṣe. Ó wu Dáfídì pé kó ya orúkọ Bàbá ẹ̀ sí mímọ́, kó sì máa yìn ín. Ó sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn pẹ̀lú “gbogbo ohun tó wà nínú” ẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn ọmọ Léfì ló máa ń ṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n bá fẹ́ yin Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n gbà pé kò sí báwọn ṣe lè yin Jèhófà tó bó ṣe yẹ káwọn yìn ín. (Neh. 9:5) Ó dájú pé bí wọ́n ṣe fìrẹ̀lẹ̀ yin Jèhófà, tí wọ́n sì ṣe é tọkàntọkàn máa múnú ẹ̀ dùn gan-an. w24.02 9 ¶6
Thursday, October 30
Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.—Fílí. 3:16.
Jèhófà ò ní sọ pé aláṣetì ni ẹ́ tọ́wọ́ ẹ ò bá tẹ àfojúsùn tágbára ẹ ò gbé. (2 Kọ́r. 8:12) Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn nǹkan tí ò jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ. Máa rántí àwọn nǹkan tó o ti ṣe láṣeyọrí. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín.” (Héb. 6:10) Torí náà, kò yẹ kíwọ náà gbàgbé iṣẹ́ tó o ti ṣe. Ronú nípa àwọn nǹkan tó o ti ṣe láṣeyọrí. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti ṣiṣẹ́ kára láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kó o máa sọ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, o sì ti lè ṣèrìbọmi. Bó o ṣe tẹ̀ síwájú, tọ́wọ́ ẹ sì tẹ àwọn àfojúsùn ẹ láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kó o máa tẹ̀ síwájú kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ní. Inú ẹ máa dùn nígbà tí Jèhófà bá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ. Bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àfojúsùn ẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, jẹ́ kí inú ẹ máa dùn bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó sì ń bù kún ẹ. (2 Kọ́r. 4:7) Torí náà tó ò bá jẹ́ kó sú ẹ, Jèhófà máa bù kún ẹ lọ́pọ̀lọpọ̀.—Gál. 6:9. w23.05 31 ¶16-18
Friday, October 31
Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi, ẹ sì ti gbà gbọ́ pé mo wá bí aṣojú Ọlọ́run.—Jòh. 16:27.
Jèhófà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, inú òun sì ń dùn sí wọn. Nínú Bíbélì, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ fún Jésù pé àyànfẹ́ òun ni, òun sì ti tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:17; 17:5) Ṣé ìwọ náà fẹ́ kí Jèhófà sọ fún ẹ pé inú òun dùn sí ẹ? Lónìí, Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ tààràtà látọ̀run, àmọ́ ó máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ láti bá wa sọ̀rọ̀. Síbẹ̀ a lè “gbọ́” ohùn Jèhófà tó ń sọ fún wa pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Lọ́nà wo? Tá a bá ń ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ délẹ̀délẹ̀. Torí náà, tá a bá ń kà nípa bí Jésù ṣe gbóríyìn fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìpé tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́, ṣe ló máa dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fáwa náà pé inú òun dùn sí wa. (Joh. 15:9, 15) Tá a bá níṣòro, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ń bínú sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìṣòro máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó àti bá a ṣe gbẹ́kẹ̀ lé e tó.—Jém. 1:12. w24.03 28 ¶10-11