ORIN 141
Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọmọ jòjòló, ọ̀wààrà òjò, - Ìmọ́lẹ̀ oòrùn àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ; - Gbogbo wọn ló jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run. - Wọ́n jẹ́rìí síṣẹ́ ìyanu ojoojúmọ́. - (ÈGBÈ) - Ẹ̀bùn yìí ṣọ̀wọ́n ó sì ṣeyebíye. - Báwo la ṣe lè fi hàn pá a mọyì ẹ̀bùn yìí? - Ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká fìmọrírì hàn; - Ẹ̀bùn ìyanu ńlá ni ìwàláàyè jẹ́. 
- 2. Àwa kò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ láé, - Bíi taya Jóòbù tó sọ fọ́kọ rẹ̀ pé: - ‘Bú Ọlọ́run rẹ, ṣe tán láti kú.’ - Àwa yóò máa yin Ọlọ́run wa títí láé. - (ÈGBÈ) - Ẹ̀bùn yìí ṣọ̀wọ́n ó sì ṣeyebíye. - Báwo la ṣe lè fi hàn pá a mọyì ẹ̀bùn yìí? - Ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká fìmọrírì hàn; - Ẹ̀bùn ìyanu ńlá ni ìwàláàyè jẹ́. 
(Tún wo Jóòbù 2:9; Sm. 34:12; Oníw. 8:15; Mát. 22:37-40; Róòmù 6:23.)