ORIN 151
Òun Yóò Pè
- 1. Bí ìrì òwúrọ̀ lẹ̀mí wa rí, - Tó bá dọ̀sán yóò pòórá. - Téèyàn bá kú, ó ti dẹni àná, - Ẹkún, òṣé yóò tẹ̀ lée. - Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè jí? - Gbọ́ ìlérí Ọlọ́run: - (ÈGBÈ) - Yóò pè wọ́n, pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀. - Àwọn òkú yóò sì jí. - Jèhófà yóò ṣàfẹ́rí - Èèyàn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. - Nígbàgbọ́, sì fọkàn balẹ̀, - Àwọn òkú ṣì máa jí. - Aó sì wà láàyè láéláé, - Ìlérí Jèhófà ni. 
- 2. Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tó ti kú, - Ọlọ́run kò gbàgbé wọn. - Gbogbo wọn ni yóò jí dìde pa dà, - Wọn yóò wà láàyè láéláé. - Ayé á wá rí b’Ọlọ́run ṣe fẹ́: - Párádísè títí láé. - (ÈGBÈ) - Yóò pè wọ́n, pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀. - Àwọn òkú yóò sì jí. - Jèhófà yóò ṣàfẹ́rí - Èèyàn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. - Nígbàgbọ́, sì fọkàn balẹ̀, - Àwọn òkú ṣì máa jí. - Aó sì wà láàyè láéláé, - Ìlérí Jèhófà ni. 
(Tún wo Jòh. 6:40; 11:11, 43; Jém. 4:14.)