ORIN 84
Wá Wọn Lọ
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà mọ àwọn ohun - Tó máa fún wa láyọ̀ tòótọ́. - Ó wá pèsè ọ̀pọ̀ ọ̀nà - Tá a lè fi sìn ín, ká ṣiṣẹ́ rẹ̀. - (ÈGBÈ) - Wá wọn lọ, sapá gan-an, - ṣiṣẹ́ Ọlọ́run. - A ṣe tán láti lọ sìn níbi - tí àìní bá wà. 
- 2. Iṣẹ́ pọ̀ fún wa láti ṣe - Ní gbogbo orílẹ̀-èdè. - À ń yọ̀ǹda ara wa láti - Ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn èèyàn. - (ÈGBÈ) - Wá wọn lọ, sapá gan-an, - ṣiṣẹ́ Ọlọ́run. - A ṣe tán láti lọ sìn níbi - tí àìní bá wà. 
- 3. Lágbègbè wa, à ń ṣèrànwọ́ - Fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé. - A sì tún máa ń kọ́ èdè mí ì, - Kí aráyé lè gbọ́ ‘wàásù. - (ÈGBÈ) - Wá wọn lọ, sapá gan-an, - ṣiṣẹ́ Ọlọ́run. - A ṣe tán láti lọ sìn níbi - tí àìní bá wà. 
(Tún wo Jòh. 4:35; Ìṣe 2:8; Róòmù 10:14.)