ORIN 110
“Ìdùnnú Jèhófà”
- 1. Ìhìnrere là ń kéde fún aráyé - Pé Ìjọba náà ti bẹ̀rẹ̀. - Ẹ gbórí yín sókè, ìgbàlà dé tán; - Ìdáǹdè wa ti sún mọ́lé! - (ÈGBÈ) - Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa. - Ká fi ayọ̀ kọrin ìyìn. - Ká fìmọrírì hàn fún ‘rètí táa ní, - Ká fọpẹ́ àt’ìyìn f’Ọ́lọ́run. - Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa. - Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé. - Ká jọ́sìn Ọlọ́run wa tọkàntọkàn, - Ká sì máa láyọ̀ lẹ́nu ‘ṣẹ́ rẹ̀. 
- 2. Ẹ̀yin tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, - Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má fòyà. - Ẹ fi ìtara gbé ohùn yín sókè, - Kẹ́ ẹ kọrin ìyìn s’Ọ́lọ́run! - (ÈGBÈ) - Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa. - Ká fi ayọ̀ kọrin ìyìn. - Ká fìmọrírì hàn fún ‘rètí táa ní, - Ká fọpẹ́ àt’ìyìn f’Ọ́lọ́run. - Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa. - Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé. - Ká jọ́sìn Ọlọ́run wa tọkàntọkàn, - Ká sì máa láyọ̀ lẹ́nu ‘ṣẹ́ rẹ̀. 
(Tún wo 1 Kíró. 16:27; Sm. 112:4; Lúùkù 21:28; Jòh. 8:32.)