ORIN 24
Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Bojú wòkè, kó o rí - Òkè ilé Jèhófà. - Ó ga ju gbogbo òkè - Mìíràn tó wà lónìí. - Láti ibi gbogbo - Jákèjádò ayé yìí, - Àwọn èèyàn ń pera wọn - Wá jọ́sìn Ọlọ́run. - Ọlọ́run ń darí wa, - Ó sì ń bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀. - A sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i; - A ti di orílẹ̀-èdè ńlá. - Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé - Jèhófà lọba ‘láṣẹ. - Wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, - Wọ́n rọ̀ mọ́ Jèhófà. 
- 2. Jésù ti pàṣẹ pé - Ká wàásù ìhìnrere. - Ká jẹ́ kí gbogbo èèyàn - Gbọ́rọ̀ Ìjọba náà. - Kristi ń jọba lọ́run, - Ó ń pe gbogbo aráyé. - Ó ń fi Bíbélì darí - Àwọn ẹni yíyẹ. - Gbogbo wa là ń sapá - Láti jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀. - Ayọ̀ kún inú wa, - Torí ogunlọ́gọ̀ ńlá ń pọ̀ sí i. - Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa - Pe àwọn èèyàn wá sí - Òkè ilé Jèhófà; - Kí wọ́n má kúrò láé. 
(Tún wo Sm. 43:3; 99:9; Àìsá. 60:22; Ìṣe 16:5.)