Orin 142
À Ń Wàásù fún Gbogbo Onírúurú Èèyàn
- A fẹ́ máa fara wé Ọlọ́run wa, - Ká jẹ́ ẹni tí kì í ṣojúsàájú. - Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn rí’gbàlà; - Gbogbo onírúurú èèyàn ló ń pè. - (ÈGBÈ) - Ibi yòówù kí wọ́n wà; - Ọkàn ló ṣe pàtàkì. - À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn. - Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, - À ń wàásù níbi gbogbo: - “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.” 
- Ibi yòówù kí a ti pàdé wọn - Tàbí irú ẹni tí wọ́n lè jẹ́. - Ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú ni Jáà rí— - Ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù sí i. - (ÈGBÈ) - Ibi yòówù kí wọ́n wà; - Ọkàn ló ṣe pàtàkì. - À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn. - Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, - À ń wàásù níbi gbogbo: - “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.” 
- Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó pinnu - Láti má ṣe jẹ́ apá kan ayé. - A mọ èyí, a sì fẹ́ káyé mọ̀, - Torí náà à ń wàásù fáwọn èèyàn. - (ÈGBÈ) - Ibi yòówù kí wọ́n wà; - Ọkàn ló ṣe pàtàkì. - À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn. - Torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, - À ń wàásù níbi gbogbo: - “Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.” 
(Tún wo Jòh. 12:32; Ìṣe 10:34; 1 Tím. 4:10; Títù 2:11.)