ORIN 69
Máa Wàásù Ìjọba Náà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ẹ tẹ̀ síwájú, ẹ máa wàásù. - Ẹ kéde orúkọ Jáà. - Ẹ wá àwọn onírẹ̀lẹ̀ lọ - Torí ‘fẹ́ tẹ́ ẹ ní sí wọn. - Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ - Láti bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́. - Torí náà, ká máa fayọ̀ wàásù; - Ká kéde òótọ́ fáráyé. - (ÈGBÈ) - Tẹ̀ síwájú, fìgboyà wàásù - ‘Jọba náà fáráyé. - Tẹ̀ síwájú, kó o jẹ́ adúróṣinṣin - sí Jèhófà. 
- 2. Àwọn ẹni àmì òróró - Àti àgùntàn mìíràn; - Gbogbo wa lọ́kùnrin, lóbìnrin - Ni ká máa tẹ̀ síwájú. - Ó yẹ kí gbogbo ayé gbọ́ pé - Ìjọba Ọlọ́run dé tán. - Bá a ṣe ń wàásù, ẹ̀rù kìí bà wá. - Jèhófà ló wà lẹ́yìn wa. - (ÈGBÈ) - Tẹ̀ síwájú, fìgboyà wàásù - ‘Jọba náà fáráyé. - Tẹ̀ síwájú, kó o jẹ́ adúróṣinṣin - sí Jèhófà. 
(Tún wo Sm. 23:4; Ìṣe 4:29, 31; 1 Pét. 2:21.)