ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 9/8 ojú ìwé 24-25
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí A Máa Di Ẹrù Ẹ̀ṣẹ̀ Wa Lé Sátánì Lórí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí A Máa Di Ẹrù Ẹ̀ṣẹ̀ Wa Lé Sátánì Lórí?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dènà Èṣù
  • Bí A Ṣe Lè “Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù”
  • Ìjà Tí A Óò Jà Láti Inú
  • Gbà Pé Ìwọ Lo Lẹ̀bi
  • “Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù” bí Jésù Ti Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ẹ Kọ Ojú Ìjà Sí Sátánì, Yóò Sì Sá!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ǹjẹ́ O Gbà Pé Èṣù Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Èṣù Kì Í Ṣe Ẹni Ìtàn Àròsọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 9/8 ojú ìwé 24-25

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí A Máa Di Ẹrù Ẹ̀ṣẹ̀ Wa Lé Sátánì Lórí?

SÁTÁNÌ ni a di ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn kọ́kọ́ dá lé lórí. Éfà sọ pé: “Ejò—òun ni ó tàn mí, nítorí náà, mo sì jẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:13) Láti ìgbà yẹn ni “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì” ti ń bá ìran ènìyàn wọ̀dìmú, ‘tí ó ń fọ́ èrò inú’ àwọn ènìyàn ‘lójú,’ tí ó sì ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9; 2 Kọ́ríńtì 4:4) Kò sí ènìyàn tí ó lè bọ́ lọ́wọ́ wàhálà rẹ̀, àmọ́, èyí ha túmọ̀ sí pé a kò lè dènà ìdarí rẹ̀ bí? Ṣé òun ló lẹ̀bi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí a ń dá?

Bíbélì ṣàlàyé pé òtítọ́ ni Sátánì tan Éfà jẹ. (1 Tímótì 2:14) Ó tàn án tí ó fi ronú pé tí òun bá rú òfin Ọlọ́run, òun lè ní ìjìnlẹ̀ òye àti òmìnira bí ti Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5) Pẹ̀lú èrò yẹn lọ́kàn, ó dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, Ọlọ́run bá a wí, ó sì dájọ́ ikú fún un. Èé ṣe? Nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irọ́ ni Sátánì pa, obìnrin náà mọ òfin Ọlọ́run dunjú. A kò fipá mú un láti ṣàìgbọràn; kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní agbára láti ṣe ohun tí ó bá fẹ́, ó sì dáńgájíá tó láti dènà ìdarí Sátánì.

Dènà Èṣù

Àwa ènìyàn lè dènà Èṣù. Éfésù 6:12 wí fún wa pé, “àwa ní gídígbò kan” lòdì sí “àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” Ó hàn gbangba nígbà náà pé, Ọlọ́run retí pé kí a gbógun ti ìdarí Sátánì. Àmọ́, báwo ni ènìyàn ṣe lè bá Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ tí wọ́n lágbára ju ẹ̀dá lọ jà? Ṣé a ń sọ pé kí a ja ogun tí ó fì sápá kan, tí ó dájú pé a kò lè borí ni? Rárá, nítorí pé Ọlọ́run kò sọ pé kí a fi agbára wa bá Èṣù jà. Jèhófà pèsè onírúurú ọ̀nà tí a lè gbà dènà àwọn ẹ̀tàn Èṣù, kí a sì ṣẹ́gun. Bíbélì sọ fún wa nípa irú ẹni tí Èṣù jẹ́, bí ó ṣe ń ṣe nǹkan, àti bí a ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ rẹ̀.—Jòhánù 8:44; 2 Kọ́ríńtì 2:11; 11:14.

Bí A Ṣe Lè “Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù”

Ìwé Mímọ́ dámọ̀ràn ọ̀nà kan tí ó ní ìgbésẹ̀ méjì tí a lè gbà dènà Èṣù. Ó rọ̀ wá pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jákọ́bù 4:7) Ìgbésẹ̀ kìíní tí a lè gbà fi ara wa sábẹ́ Ọlọ́run ni ṣíṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀. Níní wíwà Ọlọ́run, ìṣoore rẹ̀, agbára àti àṣẹ àgbàyanu rẹ̀, àti àwọn ìlànà gíga rẹ̀ lọ́kàn nígbà gbogbo yóò máa fún wa ní okun láti kọjú ìjà sí Sátánì. Ó tún ṣe pàtàkì láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà.—Éfésù 6:18.

Ronú nípa ìgbà tí Èṣù dán Jésù wò. Rírántí onírúurú àṣẹ tí Ọlọ́run ti pa àti ṣíṣe àyọlò wọn ló ran Jésù lọ́wọ́ láti dènà rẹ̀. Nígbà tí Sátánì rí i pé òun kò lè tan Jésù dẹ́ṣẹ̀, ó fi í sílẹ̀. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ agbonijìgì náà, Jèhófà lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ki Jésù láyà. (Mátíù 4:1-11) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lè fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níṣìírí pẹ̀lú ìdánilójú pé kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti ‘dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’—Mátíù 6:13.

Dídá tí Ọlọ́run ń dá wa nídè kò túmọ̀ sí pé yóò mọ odi ààbò kan yí wa ká. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní kí a máa wá àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, bí òtítọ́, òdodo, àlàáfíà, àti ìgbàgbọ́. Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ bí “ìhámọ́ra ogun,” tí ń jẹ́ kí a lè “dúró gbọn-ingbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11, 13-18) Nítorí náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a lè dojú àwọn àdánwò Èṣù délẹ̀.

Ìgbésẹ̀ kejì tí a dámọ̀ràn nínú Jákọ́bù 4:7 ni pé kí a “kọ ojú ìjà sí Èṣù.” Èyí ní ìgbésẹ̀ onígboyà, sísá fún àwọn ipá apanilára rẹ̀ nínú. A gbọ́dọ̀ yẹra fún fífa ara wa sábẹ́ ipò agbára ìtannijẹ tí ó ní, kí a sì kọ àwọn èrò onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti oníwà pálapàla tí ó wọ́pọ̀ nínú ayé lónìí. Lílòdì sí Èṣù lọ́nà yìí àti gbígbé ìgbésí ayé tí a yà sí mímọ́ fún títẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kò ṣeé fojú kéré nínú ìjà tí a ń bá Sátánì jà. Ṣùgbọ́n ṣé ìdarí Èṣù ló ń fa kí a máa dá gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí a ń dá?

Ìjà Tí A Óò Jà Láti Inú

Òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Jákọ́bù, ṣàlàyé pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Ó ṣeni láàánú pé a kò lè ṣẹ́pá àwọn àìlera àti àìpé tí a jogún pátápátá. (Róòmù 5:12) Bíbélì sọ pé: “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.”—Oníwàásù 7:20.

Èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí a ń dá ni a kò lè ṣẹ́pá rẹ̀ páàpáà. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a máa ń fa àdánwò wá sórí ara wa nípa yíyàn láti ṣe ohun tí kò tọ̀nà. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìpé àwa alára tàbí ìdarí Sátánì ló ń mú kí a ní ìfẹ́-ọkàn tí kò tọ́, ọwọ́ wa ló wà bí a bá rò ó lọ́kàn tàbí a kọ̀ ọ́. Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.”—Gálátíà 6:7.

Gbà Pé Ìwọ Lo Lẹ̀bi

Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ṣòro kí ènìyàn tó gbà pé òun lòún lẹ̀bi àṣìṣe, àìdójú-ìwọ̀n—pé òun dẹ́ṣẹ̀. (Sáàmù 36:2) Ohun kan tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbà pé àwa ni a lẹ̀bi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ń dá ni mímọ̀ pé Ọlọ́run kò béèrè pé kí a di ẹni pípé nísinsìnyí. Onísáàmù náà, Dáfídì, sọ pé: “Òun kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa.” (Sáàmù 103:10) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ń dárí jini, síbẹ̀ ó retí kí a sakun gan-an, kí a kó ara wa níjàánu, lòdì sí àwọn ìdẹwò Èṣù àti àwọn ìwà tiwa alára tí ń sún wa dẹ́ṣẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 9:27.

A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó yé wa pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run mọ̀ pé Èṣù lè lo àwọn ìgbésẹ̀ wa láti mú wa kọsẹ̀, tí ó sì jẹ́ òun ló fa ipò ẹ̀ṣẹ̀ tí aráyé wà lọ́nà gíga, èyí kò yọ wá kúrò nínú gbígbà pé àwa alára lẹ́bi tiwa. Ìdí nìyẹn tí Róòmù 14:12 fi wí pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí a bá “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú,” tí a sì “rọ̀ mọ́ ohun rere,” a lè ṣẹ́gun ibi. (Róòmù 12:9, 21) Obìnrin àkọ́kọ́ náà, Éfà, kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì jìyà àìgbọràn rẹ̀; ì bá ti kọ̀, kí ó sì ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Àmọ́, Ọlọ́run kò fọwọ́ rọ́ ipa tí Èṣù kó láti tan obìnrin náà jẹ sẹ́yìn. Ó gégùn-ún fún Èṣù, ó sì dájọ́ ìparun tí yóò wá sórí rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15; Róòmù 16:20; Hébérù 2:14) Láìpẹ́, a kò tún ní máa bá ìdarí ibi rẹ̀ yí mọ́.—Ìṣípayá 20:1-3, 10.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Erich Lessing/Art Resource, NY

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́