Ìfẹ́ Mi fún Ilẹ̀ Ayé Yóò Ṣẹ Títí Láé
Gẹ́gẹ́ bí Dorothy Connelly ṣe sọ ọ́
Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, wọ́n sọ pé n óò lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì nítorí pé mo jẹ́ Aborigine. Lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, ní 1936, mo gbọ́ àwíyé Bíbélì tí a gbà sílẹ̀, tó ṣàlàyé pé kò sí ọ̀run àpáàdì, tó sì fún mi nírètí. Ìrètí yẹn wá lágbára nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Kí n tó sọ ìdí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ ṣàlàyé díẹ̀ nípa ara mi fún yín.
ABÍ mi ní nǹkan bí ọdún 1911. Mo sọ pé “nǹkan bí” nítorí pé nígbà yẹn, àwa Aborigine kì í ṣèyọnu nípa déètì tàbí ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí. Àwọn òbí mi jẹ́ òṣìṣẹ́kára àti olùbẹ̀rù-Ọlọ́run. A ń gbé ìlú kékeré tí ń jẹ́ Springsure, nítòsí àwọn Àsokọ́ra Òkè Carnarvon rírẹwà, tó rí págunpàgun, ní àáríngbùngbùn Queensland, Ọsirélíà.
Ìdílé aláwọ̀ funfun kan ló tọ́ baba mi dàgbà nínú ìjọ Roman Kátólíìkì. Síbẹ̀, àwọn òbí mi tó jẹ́ Aborigine gbin àwọn àṣà ìbílẹ̀ wọn àti ìfẹ́ wọn fún ilẹ̀ ayé sí mi lọ́kàn. A máa ń ṣọdẹ àwọn kangaroo, emu, ìjàpá, àti ejò, a sì máa ń pa ẹja, a sì ń ṣa ògòǹgò. Àmọ́, èmi kì í jẹ ẹran emu. Èmi nìkan ni mo ní èèwọ̀ yẹn nínú ilé wa nítorí pé ó jẹ́ òòṣà tèmi. Nínú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, tàbí “Àsìkò àlá,” àwa Aborigine, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ẹ̀yà náà ní òòṣà tirẹ̀, ìdílé tàbí ẹ̀yà náà sì máa ń rin kinkin mọ́ èèwọ̀ náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ni orísun níní òòṣà tẹni, pípa èèwọ̀ yìí mọ́ ń ránni létí pé ìwàláàyè jẹ́ mímọ́. Àwọn Aborigine kì í wulẹ̀ pa ẹran ṣáá. Mo rántí bí mo ṣe ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nígbà tí Baba bínú sí mi, nígbà tí mo ń já apá àwọn labalábá kan lóòyẹ̀, nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Ó wí pé: “Ìyẹn burú jáì! O kò mọ̀ pé Ọlọ́run kórìíra ìwà ìkà ni? Ṣé inú tìrẹ náà yóò dùn bí ẹnì kan bá ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ?”
Ọ̀pọ̀ ohun asán la gbà gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí willie wagtail (ẹyẹ kékeré kan) bá wá ṣeré lórí àgọ́ tí a pa, ó túmọ̀ sí ìròyìn búburú kan; bí òwìwí kan bá bà lé kùkùté kan nítòsí lójúmọmọ, a gbà pé ẹnì kan fẹ́ kú ni. A tún máa ń wo àwọn àlá kan gẹ́gẹ́ bí àmì kan. Bí àpẹẹrẹ, bí a bá rí omi ẹlẹ́rẹ̀ nínú àlá, ó túmọ̀ sí pé ara ẹnì kan kò yá nínú ìdílé náà. Ṣùgbọ́n bí omi náà bá ń sun ẹrẹ̀ jáde, a gbà pé ẹnì kan ti kú ni. Lóòótọ́, Kátólíìkì ni wá, àmọ́, èyí kò mú kí a kọ gbogbo ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti ẹ̀yà wa sílẹ̀.
Ìdílé mi tún ń sọ èdè ìbílẹ̀ Aborigine wa nìṣó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní báyìí, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ń parẹ́ lọ. Síbẹ̀, mo ṣì ń lò ó nígbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Bí ó ti wù kí ó rí, èdè Gẹ̀ẹ́sì tàbí àdàmọ̀di-Gẹ̀ẹ́sì tí a ń lò ládùúgbò ni mo ń sọ jù.
Ìtọ́ni Níníyelórí Nígbà Èwe
Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́wàá, ìdílé wa ń gbé oko ẹran kan, ní nǹkan bi 30 kìlómítà sí Springsure. Lójoojúmọ́ ni mo máa ń rin kìlómítà mélòó kan láti ahéré oko ẹran náà láti ṣe àwọn iṣẹ́ ilé tí mo ní. Agolo wàrà kékeré kan àti ìṣù búrẹ́dì kan ni owó iṣẹ́ òòjọ́ mi. Ahéré tí a fi èèpo igi kọ́, ibùgbé àdáyébá àwọn Aborigine, ni ìdílé wa ń gbé. Bí òjò bá rọ̀, inú àwọn ihò àpáta tó wà nítòsí la ó sùn. Ǹjẹ́ mo ka ọ̀nà ìgbésí ayé ṣákálá yìí sí ìnira? Rárá o. Bí àwọn Aborigine ṣe ń gbé ayé wọn láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá nìyẹn, a sì gbà á bẹ́ẹ̀.
Ní gidi, inú mi dùn pé a kò bí mi sínú ìdílé tó ti rí já jẹ yàtọ̀ sí pákò, àti pé, mo ní àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n jẹ́ kí n ṣiṣẹ́ kára, tí wọ́n sì kọ́ mi láti pèsè àwọn ohun ìgbọ́bùkátà láti inú ilẹ̀ wá. Ní 1934, láìpẹ́ tí a kó dé ilẹ̀ kan tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Aborigine nítòsí Woorabinda, Queensland, mo jáde nílé ní ìgbà àkọ́kọ́, mo sì lọ ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ ní àwọn ahéré oko ẹran níhà ìwọ̀ oòrùn. Níkẹyìn, iṣẹ́ mú kí n ṣí lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ni ẹ̀yìn odi ìlú Rockhampton tó wà létíkun. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé ọkọ mi tó ti dolóògbé báyìí, Martin Connelly, tí baba rẹ̀ jẹ́ ará Ireland. A ṣègbéyàwó ní 1939.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bíbélì
Nígbà gbogbo ni mo ń ní ọ̀wọ̀ gidigidi fún Bíbélì. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ìyáálé ahéré oko ẹran máa ń kó àwa ọmọdé jọ—àti Aborigine àti aláwọ̀ funfun—ó sì máa ń pa ìtàn nípa Jésù fún wa. Nígbà kan, ó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: ‘Ẹ má ṣe dá àwọn ọmọdé lẹ́kun láti wá sọ́dọ̀ mi.’ (Mátíù 19:14, Ìtumọ̀ King James) Ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí mo rí ohun tó fún mi nírètí lẹ́yìn tí wọ́n sọ pé inú iná ọ̀run àpáàdì ni n óò lọ.
Lẹ́yìn náà ni mo gbọ́ àwíyé tí a gbà sílẹ̀ nípa pé hẹ́ẹ̀lì kò gbóná, tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú, n kò bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé mọ́ títí di 1949. Emerald la ń gbé nígbà náà, ní nǹkan bí 250 kìlómítà níhà ìwọ̀ oòrùn Rockhampton. R. Bennett Brickell,a tó kàn sí wa, bá wa sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ilé wa ni Ben máa ń dé sí nígbàkigbà tó bá wá sí àgbègbè wa. Gbogbo wa, àti Martin àti àwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, bọ̀wọ̀ fún un gidigidi. Ọ̀rọ̀ Bíbélì kò jẹ Martin lọ́kàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń ní inúure àti ìfẹ́ àlejò sí Àwọn Ẹlẹ́rìí, ní pàtàkì, sí Ben.
Ben fún mi ní ọ̀pọ̀ ìwé ìrànwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n ìṣòro ńlá kan wà—n kò mọ̀wé. Nítorí náà, Ben máa ń fara balẹ̀ ka Bíbélì àti àwọn ìwé tí ń ṣàlàyé Bíbélì fún èmi àti àwọn ọmọ, ó sì máa ń ṣàlàyé ohun tí ó ń kà bí ó ti ń kà á lọ. Ẹ wo bí ó ti yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà tó, àwọn tó ṣe pé, ní gbàrà tí wọ́n bá ti parí àwọn ìṣe àṣà ìsìn, wọn kò jẹ́ lo ìṣẹ́jú márùn-ún péré láti fi kọ́ wa bí a ṣeé kàwé! Ben fi hàn wá láti inú Bíbélì pé, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ló fa àwọn ìgbàgbọ́ rẹpẹtẹ tí àwọn ènìyàn, títí kan àwọn ènìyàn tèmi náà pẹ̀lú, ní nínú ohun asán, tí ó ti gbé wọn dè. Ẹ wo bí mo ṣe wá mọrírì ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Òtítọ́ yóò . . . dá yín sílẹ̀ lómìnira” tó!—Jòhánù 8:32.
Inú mi dùn gan-an láti mọ̀ nípa ète Ọlọ́run láti pèsè párádísè ilẹ̀ ayé kan fún àwọn tí ń ṣègbọràn sí i. Ju ohun gbogbo lọ, mo ń yánhànhàn fún àjíǹde àwọn òkú; Màmá ti kú ní 1939, Baba sì ti kú ní 1951. Ìgbà gbogbo ni mo ń wọ̀nà fún ọjọ́ tí n óò tún lè gbá wọn mọ́ra, kí n sì kí wọn káàbọ̀ sórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n fọkàn ṣìkẹ́ tó bẹ́ẹ̀. Ẹ sì wo bí yóò ti dùn mọ́ mi tó láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀!
Oníwàásù Tí Kò Mọ̀wé
Bí ìmọ̀ Bíbélì tí mo ní ṣe ń pọ̀ sí i, mo fẹ́ sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Mo bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀, àmọ́ mo fẹ́ mú iṣẹ́ ìsìn mi gbòòrò sí i. Nítorí náà, nígbà tí Ben tún wá sí Emerald, mo kó àwọn ọmọ jáde ní wàràǹṣeṣà, gbogbo wa sì jáde lọ wàásù pẹ̀lú rẹ̀. Ó fi ọ̀nà rírọrùn láti wàásù hàn mí, ó sì kọ́ mi láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà. Ó yẹ kí n jẹ́wọ́ pé, ìwàásù mi kò fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán, àmọ́, ó wá láti inú ọkàn mi.
Lákọ̀ọ́kọ́, mo ń sọ fún àwọn onílé pé n kò mọ̀wé; lẹ́yìn náà, mo ń rọ̀ wọ́n láti ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo ń tọ́ka sí fún wọn. Mo ti kọ́ àwọn ẹsẹ náà sórí. Ní ìlú tí àwọn aláwọ̀ funfun pọ̀ sí yìí, ọ̀pọ̀ ń wò mí tìyanutìyanu, àmọ́ àwọn ènìyàn kì í sábà ṣàìbọ̀wọ̀fúnni. Láìpẹ́, mo kọ́ ìwé kíkà. Ẹ wo bí èyí ti túbọ̀ fún ìgboyà mi àti ipò tẹ̀mí mi lókun sí i tó!
Àpéjọpọ̀ Àkọ́kọ́ Tí Mo Lọ
Ní March 1951, lẹ́yìn tí mo ti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì méjì tó kàn nínú ìgbésí ayé mi: ìrìbọmi àti àpéjọpọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí mo kọ́kọ́ lọ. Ṣùgbọ́n ìyẹn túmọ̀ sí lílọ sí ìlú ńlá Sydney—ohun kan tí ń ba ọmọbìnrin ará oko kan lẹ́rù. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, n kò tilẹ̀ ní owó ọkọ̀ lọ́wọ́. Nítorí náà, kí ni mo lè ṣe?
Mo pinnu láti ta tẹ́tẹ́, kí n lè rówó ọkọ̀. Mo ronú pé: ‘Jèhófà ni mo ń ṣe é fún, nítorí náà, ó dájú pé yóò jẹ́ kí n jẹ.’ Nígbà tí mo fi ta ọwọ́ bí mélòó kan, mo rò pé ó ti ràn mí lọ́wọ́, nítorí pé mo ti ní ìwọ̀nba owó ọkọ̀ tàlọtàbọ̀.
Ben mọ ìwéwèé mi láti lọ sí Sydney, nítorí náà, nígbà tí ó tún wá, ó bi mí bóyá mo ní owó púpọ̀ tó. Mo dáhùn pé: “Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni! Mo ti rí owó ọkọ̀ nípa títa tẹ́tẹ́.” Lọ́gán, ojú rẹ̀ yí padà, mo sì mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé mo ti sọ ohun kan tó lòdì. Nítorí náà, láti gbèjà ara mi, mo fi kún un pé: “Kí ló ṣe ọ́? Ṣebí n ò jí i!”
Nígbà tí ara Ben rọlẹ̀ sípò, ó fara balẹ̀ ṣàlàyé ìdí tí àwọn Kristẹni kì í fi ta tẹ́tẹ́, ó sì fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀bi rẹ kọ́. N kò sọ fún ọ tẹ́lẹ̀.”
A Mú Kí N Nímọ̀lára Ìtẹ́wọ́gbà
Àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yẹn, March 22 sí 25, 1951, ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo máa bá ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí pàdé. Nígbà tó jẹ́ pé Ben àti àwọn mélòó kan mìíràn ni mo mọ̀ tẹ́lẹ̀, n kò ní ìdánilójú nípa bí a óò ṣe tẹ́wọ́ gbà mí. Nítorí náà, o lè ronú nípa bí inú mi ti dùn tó nígbà tí àwọn tí yóò wá di arákùnrin àti arábìnrin mi nípa tẹ̀mí, tí wọn kò ṣàfihàn ẹ̀tanú kankan, ń kí mi káàbọ̀. Ní gidi, bí pé ilé mi ni mo wà ni, ara mi sì balẹ̀.
Mo ṣì ń rántí àpéjọpọ̀ yẹn dáradára, ní pàtàkì, nítorí pé mo wà lára àwọn 160 tí a batisí nínú Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Botany. Ní kedere, mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Aborigine ilẹ̀ Ọsirélíà tó kọ́kọ́ di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwòrán mi jáde nínú ìwé ìròyìn ọjọ́ Sunday àti nínú àwọn àwòrán sinimá tí wọ́n ń gbé jáde ní àwọn ilé ìwosinimá.
Ẹlẹ́rìí Kan Ṣoṣo Nílùú
Ní oṣù kan lẹ́yìn tí mo ti Sydney dé, ìdílé wa kó lọ sí Òkè Ńlá Isa, ìlú tí wọ́n ti ń wa kùsà níhà ìwọ̀ oòrùn àríwá Queensland. A gbé ọdún mẹ́fà nínú ahéré kan, a sì ń bójú tó ilẹ̀ ńlá kan lẹ́yìn odi ìlú náà. Igi tí a gé nínú igbó etílé kan la fi ṣe ògiri ahéré wa. Àwọn ògbólógbòó gorodóòmù ọ̀dà bítúmẹ́nì tí a là lẹ́gbẹ̀ẹ́, tí a wá nà pẹlẹbẹ, la fi bo orí rẹ̀. Martin gbaṣẹ́ nílé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin, àmọ́ ọtí àmujù sọ ọ́ di aláìsàn níkẹyìn. Nígbà náà, gbígbọ́ gbogbo bùkátà ìdílé di ẹrù tèmi nìkan. Ó kú ní 1971.
Níbẹ̀rẹ̀, èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí ní Òkè Ńlá Isa. Ben máa ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ̀kan lóṣù mẹ́fà, nítorí Òkè Ńlá Isa wà lára àgbègbè ìwàásù gbígbòòrò tí a yàn fún un. Bí ó bá wà níbẹ̀ lákòókò Ìṣe Ìrántí ikú Jésù Kristi—ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan fún Ben, níwọ̀n bí ó ti ní ìrètí ìyè ti ọ̀run—yóò ṣayẹyẹ náà pẹ̀lú ìdílé mi, ó sì máa ń jẹ́ lábẹ́ igi kan lọ́pọ̀ ìgbà.
Lọ́pọ̀ ìgbà, Ben kì í dúró pẹ́, nítorí náà, èmi àti àwọn ọmọ ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìwàásù wa fúnra wa. Lóòótọ́, a dá wà; àmọ́ ẹ̀mí Jèhófà ń fún wa lágbára, bẹ́ẹ̀ sì ni ètò àjọ rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. Àwọn adúróṣinṣin alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn ìyàwó wọn ń kojú ooru mímúhánhán, àwọn eṣinṣin, erukuru, àti ọ̀nà jágajàga láti wá fún wa níṣìírí ní Òkè Ńlá Isa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwùjọ wa kéré púpọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bákan náà ni Àwọn Ẹlẹ́rìí láti ìjọ Darwin tó sún mọ́ wa, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, tó jẹ́ nǹkan bí 1,200 kìlómítà sí wa, ń bẹ̀ wá wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
A Dá Ìjọ Kan Sílẹ̀
Ní December 1953, a dá ìjọ kan sílẹ̀ ní Òkè Ńlá Isa. Wọ́n yan Ben sípò alábòójútó, èmi àti ọmọbìnrin mi, Ann, nìkan sì ni a tún ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà náà. Àmọ́ láìpẹ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn kó wá sílùú náà. Bí àkókò sì ti ń lọ, àgbègbè ìpínlẹ̀ wa pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí méso ọmọ ẹ̀yìn jáde, tí àwọn Aborigine sì wà lára wọn.
Ìjọ náà ń gbèrú sí i, kò sì pẹ́ tí ó fi ṣe kedere pé a nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí a óò ti máa ṣe àwọn ìpàdé wa. Ní May 1960, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣekára, a parí kíkọ́ gbọ̀ngàn wa tuntun. Láàárín ọdún 15 tó tẹ̀ lé e, a fẹ̀ ẹ́ sí i lẹ́ẹ̀mejì. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó fi di agbedeméjì àwọn ọdún 1970, àwa bí 120 ní ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba, gbọ̀ngàn náà sì kéré jù fún wa lẹ́ẹ̀kan sí i. Nítorí náà, a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun jíjojúnígbèsè kan, tó gba 250 ènìyàn, a sì yà á sí mímọ́ ní 1981. Nítorí bí ilé náà ṣe tóbi tó, a tún ti ń lò ó fún àpéjọ tó tóbi sí i, tí a ń pè ní àpéjọ àyíká.
Ìbísí Láàárín Àwọn Aborigine
Ohun kan tó dùn mọ́ mi púpọ̀ ni ìdásílẹ̀ àwùjọ kan fún àwọn Aborigine àti àwọn Olùgbé Erékùṣù tí ń dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Òkè Ńlá Isa ní 1996. Àwọn Olùgbé Erékùṣù ni àwọn Aborigine tó wá láti àwọn erékùṣù ìtòsí Ọsirélíà. Ète pàtàkì tí àwùjọ yìí wà fún ni láti jẹ́rìí lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ fún àwọn Aborigine, tí ara kì í rọ àwọn kan nínú wọn tó bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n bá wà láàárín àwọn aláwọ̀ funfun.
Nǹkan bí 20 irú àwùjọ Aborigine bẹ́ẹ̀ mìíràn wà káàkiri Ọsirélíà. Láfikún sí i, a ti dá àwọn ìjọ àwọn Aborigine sílẹ̀ ní Adelaide, Cairns, Ipswich, Perth, àti Townsville. Nǹkan bí 500 ènìyàn—tó ní àwọn mọ̀lẹ́bí tèmi alára nínú—wà nínú àwọn àwùjọ àti ìjọ wọ̀nyí. Àwọn akéde Aborigine tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún!
Mo di alárùn àtọ̀gbẹ ní 1975, àrùn yìí, tí ń bá ọ̀pọ̀ Aborigine jà, sì ti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ọ̀pọ̀ ọdún wá. Kíkàwé ti túbọ̀ ń nira sí i. Síbẹ̀, Jèhófà ń gbé mi ró nìṣó, ó sì ń fún mi láyọ̀.
Mo dúpẹ́ fún àwọn òjíṣẹ́ onígboyà tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ fún èmi àti ìdílé mi. Ìtara wọn tí kò ṣeé ṣẹ́pá, ìfẹ́ wọn, àti àwọn ohun àlùmọ́nì tẹ̀mí tí wọ́n ń fi kẹ̀kẹ́ wọn rù kiri bí wọ́n ṣe ń gba àwọn ojú ọ̀nà eléruku, tí ń dá, àti àwọn ọ̀nà àgbègbè àrọko àdádó Queensland ti mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì. Ní báyìí, mo ń fìdánilójú dúró de àkókò tí ìfẹ́ mi fún ilẹ̀ ayé yóò ṣẹ títí láé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn ìgbésí ayé gbígbàfiyèsí ti Ben Brickell wà nínú Ile-Iṣọ Na July 15, 1973, ojú ìwé 440 sí 443.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Perth
Darwin
Cairns
Townsville
Òkè Ńlá Isa
Rockhampton
Emerald
Springsure
Woorabinda
Ipswich
Adelaide
Sydney
Dorothy lónìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àkókò àfidánrawò pẹ̀lú Ben lágbedeméjì àwọn ọdún 1950