ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 2/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ni Ìyàwó Kéènì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Ọmọ Ìyá Kan Náà Tí Ìwà Wọ́n Yàtọ̀ Síra
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Rírú Ẹbọ Tí Jèhófà Yóò Tẹ́wọ́ Gbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ibo Ni Kéènì Ti Rí Ìyàwó Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 2/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ọlọrun kìlọ̀ fún Kaini pé ‘ẹ̀ṣẹ̀ ba ní ẹnu ọ̀nà àti pé lọ́dọ̀ rẹ ni ìfẹ́ rẹ̀ yóò máa fà sí,’ èyí tí ó dàbí ẹni pé ó dọ́gbọ́n sọ̀rọ̀ nípa ẹranko ẹhànnà kan àti ohun-ọdẹ rẹ̀. (Genesisi 4:⁠7) Èéṣe tí a fi níláti lo èdè yẹn bí ó bá jẹ́ pé ewéko-ìgbẹ́ nìkan ni àwọn ẹranko ń jẹ ṣáájú Ìkún-Omi?

Nínú àwọn ìwé tí Mose kọ, a rí àwọn ẹsẹ mélòókan tí ó ṣe ìgbéyọ àwọn òtítọ́ tàbí ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀-ìtàn tí ó lè dàbí èyí tí kò yẹ ní àyíká ibi tí wọ́n ti ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn.

Fún àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ tí ó wà ní Genesisi 2:​10-⁠14 fúnni ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ìrísí ojú-ilẹ̀ nípa ọgbà Edeni. Mose kọ̀wé pé odò kan ni “èyí tí ń ṣàn lọ sí ìhà ìlà-oòrùn Assiria.” Ṣùgbọ́n ilẹ̀ Assiria rí orúkọ rẹ̀ fàyọ láti inú Aṣṣuri, ọmọkùnrin Ṣemu tí a bí lẹ́yìn Ìkún-Omi. (Genesisi 10:​8-11, 22; Esekieli 27:23; Mika 5:⁠6) Lọ́nà híhàn-gbangba, nínú àkọsílẹ̀ onímìísí rẹ̀, tí ó péye, Mose wulẹ̀ lo èdè-ìsọ̀rọ̀ náà “Assiria” láti tọ́kasí ẹkùn-ilẹ̀ kan tí àwọn òǹkàwé rẹ̀ mọ̀ dunjú.

Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀wò láti inú àwọn orí tí ó bẹ̀rẹ̀ ìwé Genesisi. Lẹ́yìn tí Adamu àti Efa ti dẹ́ṣẹ̀ tí a sì lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà, Jehofa ṣèdílọ́wọ́ fún wọn láti padà. Báwo? Genesisi 3:24 sọ pé: “Ó lé ọkùnrin náà jáde; ó sì fi àwọn kerubu àti idà iná de ìhà ìlà-oòrùn Edeni tí ń jù káàkiri, láti máa ṣọ́ ọ̀nà igi ìyè náà.” Ṣàkíyèsí, “idà iná.” Ọlọrun ha hùmọ̀ àwọn idà bí?

Kò sí ìdí fún wa láti parí èrò pé Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ni ẹni àkọ́kọ́ láti ṣe ohun tí a mọ̀ sí idà. Adamu àti Efa ríi tí ohun kan tí ń jówòwò ń yípo bíríbírí níwájú àwọn angẹli náà. Kí ni ohun náà jẹ́ níti gidi? Nígbà tí Mose kọ ìwé Genesisi, idà wọ́pọ̀ gan-an wọ́n sì ń lò ó nínú ogun-jíjà. (Genesisi 31:26; 34:26; 48:22; Eksodu 5:21; 17:13) Nítorí náà àwọn ọ̀rọ̀ Mose “idà iná” mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti fojú inú wòye ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àbáwọlé Edeni dé ìwọ̀n ààyè kan. Àwọn ìsọfúnni tí a mọ̀ ní ọjọ́ Mose fikún lílóye irú àwọn kókó-ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Èdè tí Mose lò sì ti níláti péye, nítorí pé Jehofa mú kí a fi í sínú Bibeli.​—⁠2 Timoteu 3:⁠16.

Genesisi 4:⁠7 wá ń kọ́ nígbà náà? Níbẹ̀ Ọlọrun kìlọ̀ fún Kaini pé: “Bí ìwọ bá ṣe rere, ara kì yóò ha yá ọ? bí ìwọ kò bá sì ṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ ba ní ẹnu-ọ̀nà, lọ́dọ̀ rẹ ni ìfẹ́ rẹ̀ yóò máa fà sí, ìwọ ó sì máa ṣe alákòóso rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí a ti kíyèsi, ó dàbí ẹni pé èdè náà ṣàgbéyọ àwòrán ẹranko ẹhànnà kan tí ebi ń pa tí ó ba láti fò mọ́ ohun-ọdẹ rẹ̀ lójijì kí ó sì jẹ ẹ́ lájẹtán.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí inú Bibeli tọ́kasí wíwà tí Adamu àti Efa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹranko. Àwọn kan lára àwọn ìṣẹ̀dá náà ti lè ní ìtura gan-⁠an láyìíká ènìyàn, kódà kí wọ́n máa jàǹfààní láti inú ìsúnmọ́ra náà. Àwọn mìíràn jẹ́ ẹranko ẹhànnà, àwọn ẹranko tí wọ́n máa ń wá ibùgbé wọn jìnnà sí sàkáání ènìyàn lọ́nà ti àdánidá. (Genesisi 1:25, 30; 2:19) Síbẹ̀, Bibeli kò fihàn pé èyíkéyìí lára àwọn ẹranko náà dọdẹ àwọn ẹranko mìíràn tàbí àwọn ènìyàn. Ní ìpilẹ̀sẹ̀, Ọlọrun fi ewéko-ìgbẹ́ ní pàtó fún ẹranko àti ènìyàn gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ. (Genesisi 1:29, 30; 7:14-⁠16) Ìyẹn kò yípadà títí di ẹ̀yìn Ìkún-Omi, gẹ́gẹ́ bí Genesisi 9:​2-⁠5 ti fihàn.

Nígbà náà, kí ni nípa ti ìkìlọ̀ Ọlọrun fún Kaini, gẹ́gẹ́ bí a ti kà ní Genesisi 4:7? Dájúdájú àwòrán ẹranko ẹhànnà kan tí ó ba tí ó sì múratán láti fò mọ́ ohun-ọdẹ rẹ̀ lójijì ni a óò ti tètè lóye ní ọjọ́ Mose, àwa sì lóye rẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí náà, lẹ́ẹ̀kan síi, Mose ti lè máa lo èdè kan tí a mú bá àwọn òǹkàwé tí wọ́n mọ ayé tí ó ṣáájú Ìkún-Omi dunjú mu. Bí ó bá sì jẹ́ pé Kaini kò tíì rí irú ìṣẹ̀dá bẹ́ẹ̀ rí, yóò ti ṣeéṣe fún un láti lóye kókó ìkìlọ̀ kan tí ó fi ìfẹ́-ọkàn tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ̀ wé ẹranko ọ̀yánnú, tí ebi ń pa.

Apá-ìhà ṣíṣepàtàkì tí ó níláti ní ipá-ìdarí lórí wa nìwọ̀nyí: inúrere Ọlọrun ní kíkìlọ̀ fún Kaini, ìníyelórí fífi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gba ìmọ̀ràn, bí owú ṣe lè tètè sọnidìbàjẹ́, àti bí ó ṣe yẹ kí a fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìkìlọ̀ àtọ̀runwá mìíràn tí Ọlọrun fi sínú Ìwé Mímọ́ fún wa.​—⁠Eksodu 18:20; Oniwasu 12:12; Esekieli 3:17-⁠21; 1 Korinti 10:11; Heberu 12:11; Jakọbu 1:​14, 15; Juda 7, 11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́