-
Ìjọba Ọlọrun Ń ṢàkósoÌmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
-
-
9 Lọ́nà kan náà, Jehofa fún wa ní ìdánilójú pé Ìjọba náà jẹ́ òtítọ́ gidi. Bí ìwé Bibeli náà Heberu ti fi hàn, ọ̀pọ̀ apá Òfin náà jẹ́ òjìji ìṣáájú fún ìṣètò Ìjọba náà. (Heberu 10:1) Ìjọba Israeli lórí ilẹ̀-ayé tún pèsè ẹ̀rí àrítẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun. Ìyẹn kì í ṣe àkóso kan lásán, nítorí pé àwọn alákòóso rẹ̀ jókòó sórí “ìtẹ́ Oluwa.” (1 Kronika 29:23) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ti sọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pá-aládé kì yóò ti ọwọ́ Judah kúrò, bẹ́ẹ̀ ni olófin kì yóò kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣiloh yóò fi dé; òun ni àwọn ènìyàn yóò gbọ́ tirẹ̀.” (Genesisi 49:10)a Bẹ́ẹ̀ni, sínú ìlà àwọn ọba Judah yìí ni a óò bí Jesu, Ọba títílọ gbére ti àkóso Ọlọrun sí.—Luku 1:32, 33.
-
-
Ìjọba Ọlọrun Ń ṢàkósoÌmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
-
-
a Orúkọ náà Ṣiloh túmọ̀ sí “Ti Ẹni Tí Ó Jẹ́; Ẹni náà Tí Ó Jẹ́ Tirẹ̀.” Nígbà tí ó yá, ó dájú pé Jesu Kristi ni “Ṣiloh” náà, “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Judah.” (Ìṣípayá 5:5) Díẹ̀ lára àwọn Targum wulẹ̀ fi ọ̀rọ̀ náà “Messia” tàbí “ọba Messia” rọ́pò “Ṣiloh.”
-