ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sísọ Ohun Gbogbo Di Tuntun—Bí A Ti Sọ ọ́ Tẹ́lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2000 | April 15
    • 10. Báwo ló ṣe yẹ ká lóye “ilẹ̀ ayé” tuntun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀?

      10 Nínú Bíbélì, “ilẹ̀ ayé” kì í fi gbogbo ìgbà tọ́ka sí àgbáyé wa. Fún àpẹẹrẹ, Sáàmù ìkẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún, ẹsẹ ìkíní sọ ní ṣangiliti pé: ‘Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ilẹ̀ ayé.’ A mọ̀ pé pílánẹ́ẹ̀tì wa—ilẹ̀ lásán àti agbami òkun tó lọ salalu—kò lè kọrin. Àwọn èèyàn ló ń kọrin. Dájúdájú, àwọn èèyàn orí ilẹ̀ ayé ni Sáàmù ìkẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún, ẹsẹ ìkíní ń tọ́ka sí.a Àmọ́, Aísáyà orí karùnlélọ́gọ́ta ẹsẹ ìkẹtàdínlógún tún mẹ́nu kan “ọ̀run tuntun.” Tí “ilẹ̀ ayé” bá dúró fún àwùjọ tuntun ti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ àwọn Júù, kí wá ni “ọ̀run tuntun”?

  • Sísọ Ohun Gbogbo Di Tuntun—Bí A Ti Sọ ọ́ Tẹ́lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2000 | April 15
    • a Bí The New English Bible ṣe tú Sáàmù ìkẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún, ẹsẹ ìkíní ni pé: “Ẹ kọrin sí OLÚWA, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.” The Contemporary English Version kà pé: “Gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé yìí, ẹ kọrin ìyìn sí OLÚWA.” Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú òye náà pé “ilẹ̀ ayé tuntun” tí Aísáyà ń tọ́ka sí ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́