-
Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí AyéÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
11, 12. (a) Kí ni “obìnrin” yìí rí bó ṣe bojú wo ìhà ìwọ̀ oòrùn? (b) Kí nìdí tí àwọn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi ń kánjú lọ sí Jerúsálẹ́mù?
11 Jèhófà wá pàṣẹ fún “obìnrin” yìí pé kí ó wo òkè réré níhà ìwọ̀ oòrùn, ó sí béèrè pé: “Ta ni ìwọ̀nyí tí ń fò bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà, àti bí àdàbà sí ihò ilé ẹyẹ wọn?” Jèhófà fúnra rẹ̀ dáhùn, ó ní: “Èmi ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò máa retí, àti àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àkọ́kọ́, láti lè kó àwọn ọmọ rẹ láti ibi jíjìnnàréré wá, bí fàdákà wọn àti wúrà wọn ti ń bẹ pẹ̀lú wọn, fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ àti fún Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, nítorí pé yóò ti ṣe ọ́ lẹ́wà.”—Aísáyà 60:8, 9.
12 Fojú inú wò ó pé ìwọ pẹ̀lú “obìnrin” yẹn ló jọ dúró, tí ẹ jọ ń wo ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọdá Òkun Ńlá. Kí lo rí? Lọ́ọ̀ọ́kán, o rí àwọn nǹkan funfun tó-tò-tó tí ó lọ súà, tí wọ́n ń fẹ́ lẹlẹ bọ̀ lójú omi. Lókèèrè wọ́n dà bí ẹyẹ, àmọ́ bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, o rí i pé àwọn ọkọ̀ òkun tó ta ìgbòkun ni. “Ibi jíjìnnàréré” ni wọ́n ti ń bọ̀.a (Aísáyà 49:12) Àwọn ọkọ̀ òkun tó ń sáré bọ̀ ní Síónì yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi dà bí agbo àwọn àdàbà tó ń fò bọ̀ wálé. Kí ló ń lé ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun yìí léré? Ńṣe ló tètè fẹ́ sọ àwọn olùjọsìn Jèhófà tí ó ń kó bọ̀ láti àwọn èbúté tó jìnnà réré kalẹ̀. Ní ti gidi, Jerúsálẹ́mù ni gbogbo àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí ń kánjú bọ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àjèjì, ì báà jẹ́ láti ìlà oòrùn tàbí ìwọ̀ oòrùn àti láti ilẹ̀ itòsí tàbí ti ọ̀nà jíjìn réré, wọ́n fẹ́ wá ya gbogbo ohun ìní wọn àtàwọn fúnra wọn sí mímọ́ fún orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run wọn.—Aísáyà 55:5.
-
-
Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí AyéÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
a Ó jọ pé ibi táa mọ̀ sí Sípéènì nísinsìnyí ni Táṣíṣì wà láyé ìgbà yẹn. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé kan ṣe wí, wọ́n ní irú àwọn ọkọ̀ òkun kan, ìyẹn “àwọn ọkọ̀ onígbòkun ńlá tó ń rìn lójú agbami òkun,” tó jẹ́ pé irú wọn ló “kúnjú òṣùwọ̀n láti máa wá sí Táṣíṣì,” ni gbólóhùn náà, “ọkọ̀ òkun Táṣíṣì” ń tọ́ka sí, ìyẹn ni pé, ó tọ́ka sí àwọn ọkọ̀ òkun tó ṣeé lò fún ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ sí àwọn èbúté ti ilẹ̀ òkèèrè.—1 Àwọn Ọba 22:48.
-