Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń làkàkà láti jẹ́ aláìlábòsí, tí wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara wọn, èé ṣe tí wọ́n fi rò pé ó ṣe pàtàkì láti ṣe ìwé àdéhùn nígbà tí òwò bá dà wọ́n pọ̀?
Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọn bá Ìwé Mímọ́ mu, ó mọ́gbọ́n dání, ó sì fi ìfẹ́ hàn. Lọ́nà wo? Ó dára, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn apá àdéhùn ìṣòwò wọ̀nyẹn yẹ̀ wò.
Bíbélì ní àkọsílẹ̀ ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó bá dá májẹ̀mú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó ní okòwò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn olùjọsìn tòótọ́ nínú. Àkọsílẹ̀ kan wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 23, tí a lè gbé yẹ̀ wò. Nígbà tí Sárà, olólùfẹ́ rẹ̀ kú, Ábúráhámù fẹ́ láti ra ilẹ̀ ìsìnkú kan. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn ará Kénáánì tí ń gbé nítòsí Hébúrónì. Ẹsẹ 7 sí 9 fi hàn pé ó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti san iye kan pàtó fún ilẹ̀ tí ó fẹ́ náà. Ẹsẹ 10 fi hàn pé ó sọ iye owó tí ó fẹ́ san yìí ní gbangba, ní etígbọ̀ọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ẹnu ibodè ìlú. Ẹsẹ 13 fi hàn pé ẹni tí ó ni ilẹ̀ náà fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti bun Ábúráhámù, ṣùgbọ́n ó fèsì pé òun yóò gba ilẹ̀ náà kìkì gẹ́gẹ́ bí ohun tí òun rà. Ẹsẹ 17, 18, àti 20 sì ṣàlàyé pé, bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn, “ní ojú àwọn ọmọ Hẹ́tì, ní ojú gbogbo àwọn tí ń wọ ẹnubodè ìlú rẹ̀” ni ó ti ṣẹlẹ̀.
Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn yóò ha yàtọ̀ bí àwọn méjì tí òwò dà pọ̀ bẹ́ẹ̀ bá jẹ́ olùjọsìn tòótọ́ bí? Orí 32 ìwé Jeremáyà dáhùn ìbéèrè náà. Láti ẹsẹ 6 lọ, a rí i pé Jeremáyà fẹ́ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ ìbátan rẹ̀. Ẹsẹ 9 fi hàn pé àwọn méjèèjì fohùn ṣọ̀kan lórí iye tí ó mọ níwọ̀n. Nísinsìnyí, ka ẹsẹ 10 sí 12: “Mo [Jeremáyà] sì kọ ọ́ sínú ìwé, mo sì dì í, mo sì pe àwọn ẹlẹ́rìí sí i, mo sì wọn owó náà nínú òṣùwọ̀n. Mo sì mú ìwé rírà náà èyí tí a dì nípa àṣẹ àti ìlànà, àti èyí tí a ṣí sílẹ̀. Mo sì fi ìwé rírà náà fún Bárúkù, ọmọ Neráyà, ọmọ Maseáyà, ní ojú Hánámélì, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi, àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó kọ orúkọ wọn sí ìwé rírà náà, níwájú gbogbo ọkùnrin Júdà tí ó jókòó ní àgbàlá ilé túbú.”
Bẹ́ẹ̀ ni, bí Jeremáyà tilẹ̀ ń ṣòwò pẹ̀lú olùjọsìn bíi tirẹ̀, tí ó tún jẹ́ ìbátan rẹ̀ pàápàá, ó gbé àwọn ìgbésẹ̀ òfin tí ó bọ́gbọ́n mu bíi mélòó kan. Wọ́n ṣe ìwé àkọsílẹ̀ méjì—wọn kò di ọ̀kan, kí ó baà lè rọrùn láti yẹ̀ wò, wọ́n di èkejì, kí ó baà lè jẹ́ àfikún ẹ̀rí, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé iyè méjì èyíkéyìí dìde nípa ìpéye èyí tí wọn kò dì. Wọ́n ṣe gbogbo èyí, “ní ojú wọn” gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 13 ṣe sọ. Nítorí náà, ó jẹ́ òwò tí a ṣe ní gbangba, tí ó bófin mu, tí ó sì ní àwọn ẹlẹ́rìí. Ó ṣe kedere, nígbà náà pé, kí àwọn olùjọsìn tòótọ́ bójú tó àwọn ọ̀ràn ní irú ọ̀nà tí ó fìdí múlẹ̀ dáradára, tí ó sì lákọsílẹ̀, ní àpẹẹrẹ ìṣáájú nínú Ìwé Mímọ́.
Ó tún mọ́gbọ́n dání. A mọ bí ọ̀rọ̀ náà, ‘ìgbà àti èèṣì ń ṣe sí gbogbo wọn,’ ṣe jẹ́ òtítọ́ tó. (Oníwàásù 9:11) Ìyẹn kan àwọn Kristẹni olùfọkànsìn àti olùṣòtítọ́ pẹ̀lú. Jákọ́bù 4:13, 14 sọ ọ́ lọ́nà yí pé: “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ̀yin tí ẹ máa ń wí pé: ‘Lónìí tàbí lọ́la àwa yóò rin ìrìn àjò lọ sí ìlú ńlá yìí dájúdájú a óò sì lo ọdún kan níbẹ̀, dájúdájú àwa yóò sì kó wọnú iṣẹ́ òwò a óò sì jèrè,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀yin kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.” Nítorí náà, a lè dáwọ́ lé ohun kan, irú bíi ríra ọjà, ṣíṣe iṣẹ́ kan tí a ti fohùn ṣọ̀kan lé lórí, tàbí mímú ohun kan jáde fún ẹnì kan. Ṣùgbọ́n, kí ni ọ̀la—tàbí oṣù tí ń bọ̀ tàbí ọdún tí ń bọ̀—yóò mú wá? Tí jàǹbá bá ṣe àwa tàbí ẹnì kejì ńkọ́? Ìyẹn lè jọ bí ohun tí yóò mú kí pípàdéhùn náà mọ́ di ohun tí kò ṣeé ṣe. Kí a sọ pé a kò lè ṣe iṣẹ́ náà mọ́, tàbí tí kò ṣeé ṣe fún ẹni tọ̀hún láti san owó náà fún wa tàbí kí ó má lè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ ńkọ́? Bí ẹ kò bá ṣèwé àdéhùn, ìṣòro ńlá lè dìde, èyí tí ẹ lè dènà rẹ̀ tàbí yanjú, ká ní ẹ ní ìwé àdéhùn kékeré kan.
Síwájú sí i, kò yẹ kí a gbàgbé pé, àìdánilójú ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé lè túmọ̀ sí pé ẹlòmíràn ni yóò tẹ́rí gba òwò wa (tàbí tirẹ̀) tàbí bójú tó o. Jákọ́bù fi kún un ní ẹsẹ 14 pé: “Nítorí ìkùukùu ni yín tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà tí ń dàwátì.” Ní ti gidi, a lè kú lójijì. Ìwé àdéhùn lè mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn ẹlòmíràn láti máa bójú tó ọ̀ràn lọ, tí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ohun kan tí a kò retí ṣẹlẹ̀ ní ìhà kíní tàbí èkejì.
Ní ọ̀nà kan, èyí mú wa dé orí apá kẹta—ìwé àdéhùn ń fi ìfẹ́ hàn. Ó dájú pé, bí ọ̀kan lára àwọn tí ó kó wọnú àdéhùn bá kú tàbí tí ìjàǹbá tí ń sọni di alábùkù ara bá ṣẹlẹ̀ sí i, yóò fi ìfẹ́ hàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, tí ó bá ti pèsè ìwé àdéhùn, tí ń sọ nípa ojúṣe rẹ̀ tàbí owó tí ó yẹ kí ó san. Nígbà tí a bá ṣèwé àdéhùn, tí ó fi ohun tí ó yẹ kí arákùnrin tí à ń bá ṣòwò ṣe tàbí ohun tí ó yẹ kí ó gbà, hàn kedere, kàkà tí ì bá fi fi àìnígbẹkẹ̀lé hàn, ó ń fi ìfẹ́ hàn fún un. Ìgbésẹ̀ onífẹ̀ẹ́ yìí yóò dín ohunkóhun tí ó lè fa ìkùnsínú tàbí ìbínú kù, tí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn aláìpé tí ó ṣàdéhùn náà gbàgbé kúlẹ̀kúlẹ̀ tàbí ẹrù iṣẹ́ kan. Èwo nínú wa ni kì í sì í ṣe aláìpé, tí kì í gbàgbé nǹkan, tàbí tí kì í ní ìtẹ̀sí láti ṣi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tàbí èrò lóye?—Mátíù 16:5.
Àwọn ọ̀nà míràn ń bẹ́ tí ṣíṣe ìwé àdéhùn òwò gbà ń fi ìfẹ́ hàn fún arákùnrin wa, fún ìdílé wa, àti fún ìjọ lápapọ̀. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí pé ó ń fi ìfẹ́ hàn, irú ìwé àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀, tí ó ní kúlẹ̀kúlẹ̀ pípéye nínú, mọ́gbọ́n dání, ó sì bá Ìwé Mímọ́ mu.