ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Máa Bá A Nìṣó Ní Dídi Ohun Tí Ìwọ Ní Mú Ṣinṣin”
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 12. Kí nìdí táwọn tó ń jọ́sìn nínú sínágọ́gù àwọn Júù tó wà ní Filadẹ́fíà ò fi ní ṣàìta gìrì bí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn á “tẹrí ba” fún àwùjọ àwọn Kristẹni àdúgbò náà?

      12 Àfàìmọ̀ làwọn tó ń lọ sí sínágọ́gù Júù ní Filadẹ́fíà ò fi ní ta gìrì bí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn kan lára wọn á ní láti “wárí” fún àwùjọ àwọn Kristẹni àdúgbò náà. Torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù ló wà nínú ìjọ yẹn, wọn á retí pé kó má rí bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Nítorí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọba [tí kì í ṣe ti àwọn Júù] yóò sì di olùtọ́jú fún ọ [ìyẹn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì], àwọn ọmọ aládé wọn obìnrin yóò sì di obìnrin olùṣètọ́jú fún ọ. Pẹ̀lú ìdojúbolẹ̀ ni wọn yóò sì tẹrí ba fún ọ.” (Aísáyà 49:23; 45:14; 60:14) Bákan náà, Sekaráyà lábẹ́ ìmísí kọ̀wé pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé ọkùnrin mẹ́wàá [ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù] láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tí kì í ṣe Júù ló máa tẹrí ba fáwọn Júù, kì í ṣe òdì kejì rẹ̀!

  • “Máa Bá A Nìṣó Ní Dídi Ohun Tí Ìwọ Ní Mú Ṣinṣin”
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 14. Báwo ni Aísáyà 49:23 àti Sekaráyà 8:23 ṣe nímùúṣẹ tó fa kíki lóde òní?

      14 Lóde òní, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ irú bí Aísáyà 49:23 àti Sekaráyà 8:23 ti nímùúṣẹ tó fa kíki. Torí pé iṣẹ́ ìwàásù tí ẹgbẹ́ Jòhánù ń ṣe ti mú kí ògìdìgbó àwọn èèyàn bá ilẹ̀kùn ṣíṣísílẹ̀ náà wọlé sínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run.b Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn wọ̀nyí ló jáde wá látinú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n fi èké pera wọn ní Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Fi wé Róòmù 9:6.) Àwọn wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, fọ aṣọ wọn, wọ́n sì sọ ọ́ di funfun nípasẹ̀ lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ ìrúbọ Jésù. (Ìṣípayá 7:9, 10, 14) Wọ́n ń ṣègbọràn sí Kristi tó jẹ́ ọba Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n bàa lè jogún àwọn ìbùkún tó máa mú wá sórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n wá sọ́dọ̀ àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù ‘wọ́n sì tẹrí ba’ fún wọn nípa tẹ̀mí, nítorí ‘wọ́n gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn.’ Wọ́n ń ṣèránṣẹ́ fáwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn, bákan náà, wọ́n wà níṣọ̀kan pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará kárí ayé.—Mátíù 25:34-40; 1 Pétérù 5:9.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́