ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Jèhófà Ọlọ́run Rẹ Ni O Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • “Tí O Bá Wólẹ̀, Tí O sì Jọ́sìn Mi Lẹ́ẹ̀kan Ṣoṣo”

      8. Báwo ni Sátánì ṣe sọ ohun tó ń fẹ́ gan-an nígbà tó dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta?

      8 Ka Mátíù 4:​8-11. Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta, kò wulẹ̀ fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ mọ́, ṣe ló sọ ohun tó ń fẹ́ ní tààràtà. Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” han Jésù (ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nínú ìran), àmọ́ kò fi ìwà ìbàjẹ́ inú wọn hàn án. Ó wá sọ fún Jésù pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni màá fún ọ tí o bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.”b Ìjọsìn ni ohun ti Sátánì ń fẹ́! Ó fẹ́ kí Jésù pa Bàbá rẹ̀ tì, kó sì gbà pé Adánniwò yìí ni ọlọ́run òun. Ohun tó dà bíi pé kò le rárá ni Sátánì fẹ́ kí Jésù ṣe. Ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé gbogbo agbára àti ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè máa jẹ́ ti Jésù. Ìyà kankan ò ní jẹ ẹ́, kò ní dé adé ẹ̀gún, kò ní sí pé wọ́n ń nà án lẹ́gba, wọn ò sì ní kàn án mọ́ òpó igi oró. Àdánwò yìí kì í ṣọ̀rọ̀ eré rárá. Jésù ò bá Sátánì jiyàn pé kì í ṣe aláṣẹ àwọn ìjọba ayé. (Jòh. 12:31; 1 Jòh. 5:19) Ó dájú pé kò sí ohun tí Sátánì ò ní fún Jésù, kó lè mú kí Jésù pa ìjọsìn mímọ́ tó jẹ́ ti Bàbá rẹ̀ tì.

      Ìdílé kan ń ṣe ìjọsìn ìdílé wọn.

      ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 1A: Kí Ni Ìjọsìn?

      9. (a) Kí ni Sátánì fẹ́ kí àwa tá à ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ ṣe, báwo ló sì ṣe máa ń fẹ́ tàn wá? (b) Kí ni ìjọsìn wa ní nínú? (Wo àpótí náà, “Kí Ni Ìjọsìn?”)

      9 Bákan náà, lóde òní, ṣe ni Sátánì fẹ́ ká máa jọ́sìn òun, yálà ní tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà. Bó ṣe jẹ́ pé òun ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” òun ló ń gba gbogbo ìjọsìn èké tí àwọn ẹ̀sìn Bábílónì Ńlá ń ṣe. (2 Kọ́r. 4:4) Àmọ́, bí àwọn tó ń ṣe ìjọsìn èké ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ ò tíì tẹ́ Sátánì lọ́rùn, ó ṣì fẹ́ máa dán àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ wò kí wọ́n lè ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó fẹ́ dọ́gbọ́n tàn wá ká lè máa wá ọrọ̀ àti agbára nínú ayé tó wà níkàáwọ́ rẹ̀, dípò ká máa hùwà tó yẹ Kristẹni, èyí tó lè mú ká “jìyà nítorí òdodo.” (1 Pét. 3:14) Tá a bá gba Sátánì láyè pẹ́nrẹ́n, tá a pa ìjọsìn mímọ́ tì, tá a wá ń ṣe ohun táyé ń ṣe, ṣe ló máa dà bíi pé a ti ń forí balẹ̀ fún Sátánì, a ti ń jọ́sìn rẹ̀, a sì ti sọ ọ́ di ọlọ́run wa. Kí la lè ṣe tá ò fi ní gba Sátánì láyè?

      10. Kí ni Jésù ṣe nígbà tí Sátánì dán an wò lẹ́ẹ̀kẹta, kí sì nìdí?

      10 Kíyè sí ohun tí Jésù ṣe nígbà tí Sátánì dán an wò lẹ́ẹ̀kẹta. Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà nìkan lòun jẹ́ adúróṣinṣin sí, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lé Adánniwò náà dà nù, ó ní: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” Bíi ti àwọn àdánwò méjì àkọ́kọ́, Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Diutarónómì, níbi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn, ó ní: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’ ” (Mát. 4:10; Diu. 6:13) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ kọ̀ jálẹ̀ láti gba ipò tó fani mọ́ra, tó sì gbayì gan-an nínú ayé, àmọ́ tí kò ní tọ́jọ́, ó sì tún kọ ayé ìdẹ̀rùn tí kò ní mú kó jìyà. Ó mọ̀ pé Bàbá òun nìkan ni ìjọsìn tọ́ sí àti pé tí kò bá tiẹ̀ ju ‘ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ téèyàn jọ́sìn’ Sátánì, onítọ̀hún ti fi ara rẹ̀ sábẹ́ Sátánì nìyẹn. Jésù jẹ́ adúróṣinṣin, ó kọ̀ láti fi Adánniwò burúkú náà ṣe ọlọ́run. Bí Jésù ò ṣe gbọ́ ti Sátánì yìí mú kí ‘Èṣù fi í sílẹ̀.’c

      Àwòrán: Jésù kò gba ìdẹwò láyè. 1. Jésù jókòó sórí àpáta nínú aginjù Jùdíà, ó ń ṣàṣàrò. 2. Jésù dúró lórí ògiri tẹ́ńpìlì. 3. Jésù ní kí Sátánì kúrò lọ́dọ̀ òun.

      “KÚRÒ LỌ́DỌ̀ MI, SÁTÁNÌ!” (Wo ìpínrọ̀ 10)

      11. Kí la lè ṣe láti gbéjà ko Sátánì àtàwọn ìdẹwò tó ń gbé wá?

      11 A lè gbéjà ko Sátánì àti àwọn ìdẹwò ayé búburú rẹ̀ torí pé bíi ti Jésù, a lè pinnu ohun tá a fẹ́ ṣe. Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn ni òmìnira láti yan ohun tó wù wá. Torí náà, kò sẹ́ni tó lè fipá mú wa láti pa ìjọsìn mímọ́ tì, títí kan Adánniwò burúkú náà tó jẹ́ alágbára. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin, tá a sì ‘kọjú ìjà sí Sátánì’ tá a “dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,” ṣe là ń sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” (1 Pét. 5:9) Má gbàgbé pé, Sátánì fi Jésù sílẹ̀ nígbà tí Jésù kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ohun tó fẹ́. Bákan náà, Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”​—Jém. 4:7.

      Àwòrán: Jésù kò gba ìdẹwò láyè. 1. Arábìnrin kan tó ń tún yàrá òtẹ́ẹ̀lì ṣe rí nǹkan ọ̀ṣọ́ tí àlejò kan gbàgbé síbẹ̀. 2. Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń wò ó. 3. Arákùnrin kan kọ̀ láti tún dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n jọ ń mu sìgá àti ọtí tí wọ́n sì jọ ń ta tẹ́tẹ́ tẹ́lẹ̀.

      A lè pinnu pé a ò ní kó sínú ìdẹwò ayé Sátánì (Wo ìpínrọ̀ 11 àti 19)

      Ọ̀tá Ìjọsìn Mímọ́

      12. Báwo ni ohun tí Sátánì ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì ṣe fi hàn pé òun ni ọ̀tá ìjọsìn mímọ́?

      12 Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò lẹ́ẹ̀kẹta, Sátánì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni olórí ọ̀tá ìjọsìn mímọ́. Inú ọgbà Édẹ́nì ni Sátánì ti kọ́kọ́ fi hàn pé òun kórìíra ìjọsìn Jèhófà, ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà tó wá dán Jésù wò. Bí Sátánì ṣe tan Éfà jẹ, tí Éfà náà sì sún Ádámù láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó mú kí wọ́n wá sábẹ́ àkóso òun, ó sì ń darí wọn. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:​1-5; 2 Kọ́r. 11:3; Ìfi. 12:9) Bí wọn ò tiẹ̀ mọ ẹni tó ń ṣì wọ́n lọ́nà ní tààràtà, ohun tí Sátánì ṣe gan-an ni pé ó sọ ara rẹ̀ di ọlọ́run wọn, àwọn náà sì ń jọ́sìn rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, bí Sátánì ṣe pilẹ̀ ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, kì í kàn ṣe pé ó fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ tàbí pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, ṣe ló tún gbéjà ko ìjọsìn mímọ́. Lọ́nà wo?

  • “Jèhófà Ọlọ́run Rẹ Ni O Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • b Ìwé kan tó dá lórí Bíbélì sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ Sátánì yìí pé: “Bó ṣe rí nígbà ìdẹwò àkọ́kọ́, tí Ádámù àti Éfà kó sọ́wọ́ Sátánì . . . , ọ̀rọ̀ yìí dá lórí ṣíṣe ìfẹ́ Sátánì tàbí ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ní láti pinnu ẹni tí wọ́n máa jọ́sìn nínú àwọn méjèèjì. Ṣe ni Sátánì ń gbéra ga, tó sì ń fi ara rẹ̀ ṣe ọlọ́run dípò Ọlọ́run kan ṣoṣo náà.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́