-
‘Ẹ Pọkàn Pọ̀ Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ’Ilé Ìṣọ́—2002 | September 15
-
-
‘Ẹ Pọkàn Pọ̀ Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ’
“Ó . . . pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.”—HÉBÉRÙ 2:1.
1. Ṣàpèjúwe bí ìpínyà ọkàn ṣe lè yọrí sí jàǹbá?
ÌJÀǸBÁ ohun ìrìnnà ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì [37,000] lọ́dọọdún ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan ṣoṣo. Àwọn ògbógi sọ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni ì bá máà wáyé tó bá jẹ́ pé àwọn awakọ̀ túbọ̀ fojú síbi tí wọ́n ń lọ. Ohun tó ń gba àfiyèsí àwọn awakọ̀ kan ni pátákó ìsọfúnni, pátákó ìpolówó ọjà tàbí fóònù alágbèérìn tí wọ́n ń lò. Àwọn kan tún máa ń jẹun nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀ lọ́wọ́. Ohun tí gbogbo èyí ń fi yéni ni pé ìpínyà ọkàn lè yọrí sí jàǹbá.
2, 3. Ọ̀rọ̀ ìṣílétí wo ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni, kí sì nìdí tí ìmọ̀ràn rẹ̀ fi bọ́ sásìkò?
2 Nǹkan bí ẹgbàá ọdún ṣáájú àkókò tí wọ́n ṣe ohun ìrìnnà jáde ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan oríṣi ìpínyà ọkàn kan tó hàn pé ó kó jàǹbá bá àwọn kan lára àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé a ti gbé Jésù Kristi tó jíǹde sí ipò kan tó ga ju ti gbogbo àwọn áńgẹ́lì lọ, nítorí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run ló jókòó sí. Àpọ́sítélì náà wá sọ pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má bàa sú lọ láé.”—Hébérù 2:1.
3 Kí nìdí táwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni fi ní ‘láti fún àwọn ohun tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ’? Ìdí ni pé nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn Hébérù kan tó jẹ́ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ sí sú lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ nítorí pé Ọ̀gá wọn ò sí lọ́dọ̀ wọn mọ́. Ìsìn àwọn Júù, tó jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jọ́sìn tẹ́lẹ̀ ti ń pín ọkàn wọn níyà.
Wọ́n Ní Láti Túbọ̀ Pọkàn Pọ̀
4. Kí ló lè mú kó máa ṣe àwọn Hébérù kan tó jẹ́ Kristẹni bíi pé kí wọ́n padà sínú ìsìn àwọn Júù?
4 Kí nìdí tó fi lè máa ṣe àwọn Kristẹni kan bíi pé kí wọ́n padà sínú ìsìn àwọn Júù? Tóò, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn lábẹ́ Òfin jẹ mọ́ àwọn ohun tó ṣeé fojú rí. Àwọn èèyàn lè rí àwọn àlùfáà kí wọ́n sì gbóòórùn àwọn ẹbọ sísùn. Àmọ́ ìsìn Kristẹni yàtọ̀ pátápátá síyẹn láwọn ọ̀nà kan. Àwọn Kristẹni ní Àlùfáà Àgbà kan, ìyẹn Jésù Kristi, àmọ́ láti bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ìgbà yẹn ò tì rí i mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. (Hébérù 4:14) Wọ́n ní tẹ́ńpìlì kan, àmọ́ ọ̀run ni ibi mímọ́ rẹ̀ wà. (Hébérù 9:24) Dípò ìdádọ̀dọ́ tó ṣeé fojú rí lábẹ́ Òfin, ìdádọ̀dọ́ Kristẹni jẹ́ “ti ọkàn-àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí.” (Róòmù 2:29) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí ìsìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ sí dà bí ohun tí kò nítumọ̀ mọ́ lójú àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni.
5. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé ọ̀nà ìjọsìn tí Jésù gbé kalẹ̀ ga lọ́lá ju èyí tí ń bẹ lábẹ́ Òfin lọ?
5 Àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ní láti mọ ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an nípa ọ̀nà ìjọsìn tí Kristi gbé kalẹ̀. Ó gbé e karí ìgbàgbọ́ ju orí ohun tó ṣeé fojú rí lọ, síbẹ̀ ó ga lọ́lá ju Òfin tá a fún wọn nípasẹ̀ wòlíì Mósè. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí ó di ẹlẹ́gbin bá ń sọni di mímọ́ dé àyè ìmọ́tónítóní ara, mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni tí ó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n, yóò wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè?” (Hébérù 9:13, 14) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìdáríjì téèyàn ń rí gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ga lọ́lá gan-an ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà ju èyí téèyàn ń rí gbà nípasẹ̀ ẹbọ tí wọ́n ń rú lábẹ́ Òfin.—Hébérù 7:26-28.
6, 7. (a) Ipò wo ló mú kó di ọ̀ràn kánjúkánjú pé káwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ‘fún àwọn ohun tí wọ́n gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ’? (b) Báwo ni ìparun Jerúsálẹ́mù ṣe sún mọ́lé tó lákòókò tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn Hébérù? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Ìdí mìíràn tún wà táwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni fi ní láti fún ohun tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù ní àfiyèsí gidi. Ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé a óò pa Jerúsálẹ́mù run. Jésù sọ pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé bá ọ, nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká, wọn yóò sì ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo, wọn yóò sì fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tí ń bẹ nínú rẹ mọ́lẹ̀, wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ, nítorí pé ìwọ kò fi òye mọ àkókò tí a ó bẹ̀ ọ́ wò.”—Lúùkù 19:43, 44.
7 Ìgbà wo lèyí máa ṣẹlẹ̀? Jésù ò sọ ọjọ́ àti wákàtí náà. Dípò ìyẹn, ó fún wọn nítọ̀ọ́ni yìí pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:20, 21) Àwọn Kristẹni kan ní Jerúsálẹ́mù ti pàdánù ẹ̀mí pé ọ̀ràn jẹ́ kánjúkánjú tí wọ́n ní, ọkàn wọn sì ti pínyà ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ìyẹn ni pé wọ́n ti yíjú kúrò lójú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lọ. Bí wọn ò bá yí èrò wọn padà, ó dájú pé wọ́n á ko àgbákò. Yálà wọ́n rò bẹ́ẹ̀ o tàbí wọn ò rò bẹ́ẹ̀, ìparun ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Jerúsálẹ́mù!a Ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù mú káwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù ta jí kúrò lójú oorun tẹ̀mí tí wọ́n ń sùn.
Pípọkànpọ̀ “Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ” Lónìí
8. Èé ṣe tá a fi ní láti “fún” òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí tó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ”?
8 Bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, a ní láti “fún” òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.” Kí nìdí? Nítorí pé àwa náà dojú kọ ìparun kan tó sún mọ́lé, kì í ṣe ti orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo bí kò ṣe ti ètò àwọn nǹkan látòkèdélẹ̀. (Ìṣípayá 11:18; 16:14, 16) Lóòótọ́, a ò mọ ọjọ́ náà gan-an àti wákàtí tí Jèhófà yóò gbé ìgbésẹ̀ yìí. (Mátíù 24:36) Síbẹ̀, à ń fojú ara wa rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1-5) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti dènà ohunkóhun tó lè pín ọkàn wa níyà. A ní láti máa fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láfiyèsí ká sì máa ní ẹ̀mí pé ọ̀ràn jẹ́ kánjúkánjú nìṣó. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan la fi lè “kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.”—Lúùkù 21:36.
-
-
‘Ẹ Pọkàn Pọ̀ Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ’Ilé Ìṣọ́—2002 | September 15
-
-
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọdún 61 Sànmánì Tiwa ló kọ lẹ́tà náà sáwọn Hébérù. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, nǹkan bí ọdún márùn-ún péré lẹ́yìn náà ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Cestius Gallus yí Jerúsálẹ́mù ká. Kò sì pẹ́ tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀hún fi káńgárá wọn, táwọn Kristẹni tó wà lójúfò fi lè sá lọ. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ìyẹn ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù lábẹ́ Ọ̀gágun Titus wá pa ìlú ńlá náà run.
-