Kí Ni Àwòjíìji náà Ṣí Payá?
WO ÀWÒJÍÌJI kan. Kí ni o rí? Nígbà mìíràn, wíwo àwòjíìji kan fìrí lè ṣí àlèébù kan tí ń tinilójú payá nínú ìrísí rẹ tí inú rẹ yóò dùn láti túnṣe kí àwọn ẹlòmíràn tó kíyèsí i.
Bibeli dàbí àwòjíìji kan gan-an. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye aláìlábòsí nípa ara wa, èyí tí yóò dènà kí a máa ronú púpọ̀ jù—tàbí lọ́nà tí ó kéré jù—nípa bí a ti níyelórí tó lójú Ọlọrun. (Matteu 10:29-31; Romu 12:3) Ní àfikún síi, Bibeli lè ṣí àwọn àlèébù tí ń bẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀, ìṣe, tàbí ìṣarasíhùwà wa tí ó yẹ kí a túnṣe payá. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ìwọ yóò ha ṣá ohun tí àwòjíìji náà bá ṣípayá tì bí?
Òǹkọ̀wé Bibeli náà Jakọbu sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ naa, tí kò sì jẹ́ olùṣe, ẹni yii dàbí ènìyàn kan tí ń wo ojú àdánidá rẹ̀ ninu jígí. Nitori ó wo ara rẹ̀, ó sì lọ kúrò ati lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó gbàgbé irú ènìyàn tí oun jẹ́.”—Jakọbu 1:23, 24.
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Jakọbu ṣàpèjúwe ọkùnrin mìíràn, bí ẹnì kan tí “ń wo inú òfin pípé naa tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn.” (Jakọbu 1:25) Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí ‘wò ní àwòfín’ túmọ̀ sí láti tẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ tàbí garùn wo nǹkan. Ìwé atúmọ́ èdè náà Theological Dictionary of the New Testament sọ pé: “Ọ̀ràn náà ní nínú ju ìwòfìrí lọ́gán lọ.” Ọ̀rọ̀ náà dọ́gbọ́n túmọ̀ sí fífarabalẹ̀ wá ohun kan tí ó farasin. Alálàyé kan lórí Bibeli R. V. G. Tasker kọ̀wé pé: “Ohun kan wà tí ó ṣe pàtàkì tí ẹni tí ń wo nǹkan ní ọkàn-ìfẹ́ láti rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro fún un láti rí i kí ó sì lóye ìtúmọ̀ rẹ̀ ní kíámọ́sá.”
Ìwọ yóò ha tipa báyìí yẹ ara rẹ wò fínnífínní nínú àwòjíìji Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí o sì mú ara rẹ bá àwọn ohun tí ó béèrè fún mu bí? Jakọbu ń bá a nìṣó ní sísọ pé: “Ẹni yii, nitori tí oun kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bíkòṣe olùṣe iṣẹ́ naa, yoo láyọ̀ ninu ṣíṣe é.”—Jakọbu 1:25.