ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • “Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”

      15. Kí ni Bíbélì sọ nípa ànímọ́ Jèhófà náà ìfẹ́, tí kò sọ nípa àwọn ànímọ́ ẹ̀ tó kù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      15 Nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà mẹ́rin tó gbawájú, Bíbélì sọ nǹkan kan nípa ìfẹ́ tí kò sọ nípa àwọn mẹ́ta tó kù. Ìwé Mímọ́ kò sọ pé Ọlọ́run jẹ́ agbára tàbí pé Ọlọ́run jẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ọgbọ́n. Ó ní àwọn ànímọ́ yẹn ni, òun ni Orísun wọn, ọ̀nà tó sì ń gbà lò wọ́n ló dáa jù. Àmọ́, Bíbélì sọ ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ànímọ́ kẹrin. Ó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”b (1 Jòhánù 4:8) Kí lọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?

      16-18. (a) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́”? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu pé èèyàn ni Jèhófà fi ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́?

      16 Nígbà tí Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run àti ìfẹ́ dọ́gba. Ó ṣe tán, a ò lè yí ọ̀rọ̀ yẹn pa dà ká wá sọ pé “ìfẹ́ jẹ́ Ọlọ́run.” Jèhófà kọjá ẹni tá a lè fi wé ìwà àti ìṣe lásánlàsàn. Ọlọ́run wà lóòótọ́, ó máa ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára, ó sì ní oríṣiríṣi ànímọ́ míì láfikún sí ìfẹ́. Àmọ́, ìfẹ́ làkọ́kọ́ lára ìwà àti ìṣe Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì fi sọ nípa ẹsẹ yìí pé: “Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń ṣe ló ń fi ìfẹ́ hàn.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Òótọ́ ni pé agbára tí Jèhófà ní ló fi máa ń ṣe nǹkan, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ ló sì máa ń darí ẹ̀ tó bá ń ṣe nǹkan náà. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló máa ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Ìfẹ́ rẹ̀ sì máa ń hàn nínú bó ṣe ń lo àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù.

      17 A sábà máa ń sọ pé Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá di pé ká fìfẹ́ hàn. Torí náà, ọ̀nà tó dáa jù téèyàn lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ ni pé kó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àwa èèyàn náà máa ń fìfẹ́ hàn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ kíyè sóhun tí Jèhófà sọ fún Ọmọ rẹ̀ nígbà tó fẹ́ dá àwa èèyàn, ó sọ pé: “Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa, kí wọ́n jọ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá sí ayé, àwa èèyàn nìkan la lè pinnu pé a máa fìfẹ́ hàn, ìyẹn ló sì jẹ́ ká fìwà jọ Baba wa ọ̀run. Jèhófà fi onírúurú ohun alààyè ṣàpẹẹrẹ àwọn ìwà àti ìṣe pàtàkì tó ní. Àmọ́, Jèhófà lo àwa èèyàn, tó jẹ́ èyí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lára àwọn ohun tó dá sáyé, láti ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́, tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù.​—Ìsíkíẹ́lì 1:10.

  • “Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
    • b Àwọn gbólóhùn míì nínú Ìwé Mímọ́ fara jọ èyí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀” àti pé “Ọlọ́run . . . jẹ́ iná tó ń jóni run.” (1 Jòhánù 1:5; Hébérù 12:29) Àmọ́, ó ṣe kedere pé ńṣe ni Bíbélì kàn ń fi Jèhófà wé àwọn nǹkan yẹn. Jèhófà dà bí ìmọ́lẹ̀, torí pé ó jẹ́ mímọ́ àti adúróṣinṣin. Kò sí “òkùnkùn,” ìyẹn àìmọ́, nínú rẹ̀ rárá. A sì tún lè fi Jèhófà wé iná torí bó ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti fi pa nǹkan run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́