Bibeli Lédè Goth—Àṣeyọrí Pípẹtẹrí
ÀWỌN ọmọ ilẹ̀ Goth wà nínú àjùmọ̀ṣepọ̀ kan náà pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Germany, tí ó ṣeéṣe kí wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti Scandinavia. Ní àwọn ọ̀rúndún ìbẹ̀rẹ̀ Sànmánì Tiwa, wọ́n ṣílọ sí àwọn ibi jíjìnnà réré níhà gúúsù dé Òkun Dúdú àti odò Danube, àwọn ìlú ààlà ẹnubodè Ilẹ̀-Ọba Romu gan-an.
Ìwé tí a kọ́kọ́ mújáde ní èdè Germany èyíkéyìí ni Bibeli lédè Goth. Lónìí kìkì àjákù ẹ̀dà yìí ni ó wà. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣì jẹ́ ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ tí kò lẹ́gbẹ́ tí a sì kà sí iyebíye. Èéṣe?
Ulfilas—Míṣọ́nnárì àti Atúmọ̀ Bibeli
Ẹni tí ó túmọ̀ Bibeli yìí ni Ulfilas, a sì tún mọ̀ ọ́n sí Wulfila tíí ṣe orúkọ rẹ̀ ní èdè Goth. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn náà Philostorgius ti sọ, Ulfilas jẹ́ ọmọ ìran àwọn ìgbèkùn tí a kó nígbà tí àwọn Goth gbógunti Cappadocia, tí ó jẹ́ apákan ilẹ̀ Turkey ti ìhà ìlà-oòrùn nísinsìnyí. A bíi ní nǹkan bíi 311 C.E., a fi í joyè láti ọwọ́ Eusebius ti Nicomedia ní nǹkan bíi 30 ọdún lẹ́yìn náà ó sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì láàárín àwọn Goth.
Òpìtàn Will Durant sọ pé, “Láti fún àwọn tí ó yílọ́kànpadà ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí ó sì mú wọn pọ̀ síi, ó fi sùúrù ṣe ìtumọ̀ gbogbo Bibeli, àyàfi Ìwé Àwọn Ọba, láti èdè Griki sí èdè Goth.” (The Age of Faith) Lónìí, yàtọ̀ sí àjákù ìwé Nehemiah, ìwé-àfọwọ́kọ Bibeli lédè Goth kanṣoṣo mìíràn tí ó ṣì wà ni àwọn apákan Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki.
Èdè Goth kìí ṣe èdè tí a ń kọsílẹ̀. Nítorí náà Ulfilas dojúkọ ìpèníjà ìṣètumọ̀ tí ó béèrè fún ọgbọ́n ìhùmọ̀ àrà-ọ̀tọ̀. Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ìgbàanì tí wọ́n jẹ́ òpìtàn sọ pé òun ni ó hùmọ̀ álífábẹ́ẹ̀tì èdè Goth tí ó ní lẹ́tà 27, tí a pilẹ̀ gbékarí àwọn álífábẹ́ẹ̀tì Griki àti ti Latin. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé “ó hùmọ̀ èdè ìsọ̀rọ̀ Kristian lédè Germany, èyí tí a ṣì ń lo díẹ̀ nínú wọn síbẹ̀.”
Ìtàn Ìjímìjí ti Bibeli Lédè Goth
Ulfilas parí ìtumọ̀ rẹ̀ ṣáájú 381 C.E. ó sì kú ní ọdún méjì tàbí mẹ́ta lẹ́yìn náà. Bí iṣẹ́ rẹ̀ ti gbajúmọ̀ tó ni gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana jẹ́rìí sí, èyí tí ó sọ pé “ìtumọ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Goth tí wọ́n ṣílọ sí Spain àti Italy lò ní gbogbogbòò.” Níti tòótọ́, ní gbígbé àyẹ̀wò karí àwọn àjákù tí ó làájá, ó jọ bí ẹni pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀dà Bibeli lédè Goth yìí ni a ṣe. Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ pé, mélòókan àwọn ẹ̀dà ìwé-àfọwọ́kọ yìí ni a mújáde ní àwọn iyàrá ìṣàdàkọ ti Ravenna àti Verona, ní agbègbè ibi tí àwọn Goth fìdí ìjọba wọn múlẹ̀ sí. Àwọn iyàrá ìṣàdàkọ jẹ́ àwọn iyàrá nínú ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé níbi tí a ti ń kọ àwọn ìwé-àfọwọ́kọ tí a sì ń ṣàdàkọ wọn.
Àwọn Goth wá sí òpin wọn gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan ní nǹkan bíi 555 C.E., lẹ́yìn tí olú-ọba ilẹ̀ Byzantine náà Justinian Kìn-ín-ní ti tún ṣẹ́gun Italy. Lẹ́yìn òpin àwọn Goth, Tönnes Kleberg sọ pé, “èdè Goth àti àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti Goth ní Italy pòórá, agbárá káká ni a sì fi lè rí ìràlẹ̀rálẹ̀ kankan. Àwọn ìwé-àfọwọ́kọ ní èdè Goth ni a kò tún lọ́kàn-ìfẹ́ sí mọ́. . . . Dé ìwọ̀n àyè púpọ̀ a kó wọn sọ́tọ̀ tí a sì ha wọ́n láti pa ìkọ̀wé inú rẹ̀ rẹ́. Àwọn ìwé-awọ gbígbówólórí náà ni a túnlò lẹ́yìn náà fún kíkọ àwọn nǹkan titun.”
Àwọn Ìwé-Àfọwọ́kọ tí Ó Làájá
Wọn kò pa ìwé náà rẹ́ dáradára lórí díẹ̀ lára àwọn ìwé-àfọwọ́kọ wọ̀nyí, tí ìyẹn sì mú kí àwọn lẹ́tà tí a fọwọ́kọ ní ìpilẹ̀sẹ̀ hàn fírífírí. Mélòókan nínú àwọn awọ tí a kò pa ìkọ̀wé wọn rẹ́ tán yìí, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pè wọ́n, ni a ti rí tí a sì ti wá ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn. Lọ́nà pípẹtẹrí, Ìwé-Àfọwọ́kọ Alábala ti Argenteus lílókìkí, nínú èyí tí àwọn Ìhìnrere mẹ́rin wà ní ìtòtẹ̀léra báyìí Matteu, Johannu, Luku, àti Marku, ni a pamọ́ láìsí ohun tó ṣe é.
Ìwé-àfọwọ́kọ alábala títayọlọ́lá náà ni a rò pé ó ti níláti wá láti àwọn iyàrá ìṣàdàkọ Ravenna ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹfà C.E. A ń pè é ní Ìwé-Àfọwọ́kọ Alábala ti Argenteus, tí ó túmọ̀sí “Ìwé Onífàdákà,” nítorí pé a fi tàdáwà fàdákà kọ ọ́. Àwọn ewé-ìwé rẹ̀ tí ó jẹ́ ti ìwé-awọ ni a kùn ní àwọ̀ elésè àlùkò, tí ó fihàn pé ó ti ṣeéṣe kí a fi dá sàràkí ọba kan lọ́lá. Àwọn lẹ́tà olómi góòlù ni a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn ìlà mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìhìnrere kọ̀ọ̀kan àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ẹ̀ka-ìpín ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Orúkọ àwọn òǹkọ̀wé Ìhìnrere ni a tún fi omi góòlù kọ sí òkè àwọn “ìlà títẹ̀ kọrọdọ” gígùn mẹ́rin tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òpó ìlà kọ̀ọ̀kan nínú ìwé náà. Ìwọ̀nyí fúnni ní àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe sí àwọn apá àyọkà bíbáradọ́gba nínú àwọn Ìhìnrere náà.
Dídá Àwọn Ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Goth Padàsípò
Tẹ̀lé ìmúkúrò orílẹ̀-èdè Goth, Ìwé-Àfọwọ́kọ Alábala ti Argenteus ṣíṣeyebíye náà pòórá. A kò tún rí i mọ́ títí tí ó fi wá sójútáyé ní àárín ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ní ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti Werden, nítòsí Cologne, Germany.
Ní ọdún 1569, a tẹ ẹ̀dà ìtumọ̀ Àdúrà Oluwa ní èdè Goth jáde, ní dídarí àfiyèsí sí Bibeli náà láti inú èyí tí a ti mú un jáde. Orúkọ náà Ìwé-Àfọwọ́kọ Alábala ti Argenteus farahàn ní títẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní 1597. Láti Werden ìwé àfọwọ́kọ yìí di èyí tí ó wà nínú ìkójọpọ̀ àwọn ohun ọnà olú-ọba ní Prague. Bí ó ti wù kí ó rí, ní òpin Ogun Ọgbọ̀n Ọdún náà ní 1648, àwọn ọmọ ilẹ̀ Sweden tí wọ́n jagunmólú gbé e dání lọ pẹ̀lú àwọn ohun ìṣúra mìíràn. Láti ọdún 1669 ìwé-àfọwọ́kọ alábala yìí ní àyè wíwà títílọ ní Ibi Àkójọ Ìwé Kíkà Yunifásítì ní Uppsala, Sweden.
Ìwé-Àfọwọ́kọ Alábala ti Argenteus ní ewé-ìwé 336 ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, nínú èyí tí 187 wà ní Uppsala. Ewé-ìwé mìíràn—èyí tí ó gbẹ̀yìn nínú Ìhìnrere Marku—ni a ṣàwárí rẹ̀ ní 1970 ní Speyer, Germany.
Láti ìgbà tí ìwé-àfọwọ́kọ alábala náà ti tún farahàn, àwọn ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà láti wá ìtumọ̀ sí èdè Goth tí ó ti di ìgbàgbé náà. Ní lílo gbogbo ìwé-àfọwọ́kọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó àti àwọn ìgbìdánwò ìṣáájú láti dá àwọn ẹsẹ̀ náà padàsípò, ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Germany náà Wilhelm Streitberg ṣe ìkójọpọ̀ ó sì tẹ “Die gotische Bibel” (Bibeli Lédè Goth) jáde ní 1908, èyí tí ó ní àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí a kọ lédè Griki àti Goth ní àwọn ojú-ìwé tí ó dojúkọ ọ́.
Lónìí, àwọn ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní pàtàkì ni wọ́n lọ́kàn-ìfẹ́ sí Bibeli lédè Goth. Bí ó ti wù kí ó rí, òtítọ́ náà pé a mú un jáde tí a sì ṣìkẹ́ rẹ̀ ní àwọn ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí ṣètumọ̀ Bibeli jẹ́rìí sí ìfẹ́-ọkàn àti ìpinnu Ulfilas láti mú kí a túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sí ohun tí ó jẹ́ èdè òde-òní nígbà náà lọ́hùn-ún. Ó mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ pé lọ́nà yìí nìkanṣoṣo ni àwọn aráàlú Goth lè gbà lóye òtítọ́ Kristian.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìyọ̀ọ̀da onínúure ti Uppsala University Library, Sweden