Orin 139
Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in
- Bá a ṣé ń kọ́ àgùntàn Jèhófà - À ń láyọ̀ pé wọ́n ń dàgbà. - À ń rọ́wọ́ rẹ̀ bó ṣe ń darí wọn - Wọ́n ń sòótọ́ di tara wọn. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa - Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba. - Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege; - Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in. 
- ‘Joojúmọ́ là ń gbàdúrà fún wọn, - Kí ‘gbàgbọ́ wọn má ṣe yẹ̀. - À ń kọ́ wọn, a sì ń ṣìkẹ́ wọn; - Wọ́n ń lókun, Jáà ń bù kún wọn. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa - Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba. - Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege; - Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in. 
- Jọ̀ọ́ jẹ́ kí wọ́n máa gbẹ́kẹ̀ lé ọ, - Ìwọ àti Ọmọ rẹ. - Pẹ̀lú ‘fa-radà àtìgbọràn, - Kí wọ́n lè jogún ìyè. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa - Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba. - Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege; - Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in. 
(Tún wo Lúùkù 6:48; Ìṣe 5:42; Fílí. 4:1.)