ORIN 56
Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ
- 1. Ọ̀nà òtítọ́ ló dára jù láti rìn, - Àmọ́ ìwọ lo máa ṣèpinnu. - Torí náà, ó sàn kó o gbàmọ̀ràn Jèhófà. - Gbà pé òótọ́ ló ń sọ fún ọ. - (ÈGBÈ) - S’òótọ́ di tìrẹ. - Kó hàn nínú ayé rẹ. - Jèhófà yóò jẹ́ - Kó o láyọ̀ tòótọ́, - Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ. 
- 2. Bó o ṣe ńgbìyànjú, tóò ńlo ọ̀pọ̀ àkókò - Lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, - Yóò mérè ńlá wá àtìyè àìnípẹ̀kun - Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. - (ÈGBÈ) - S’òótọ́ di tìrẹ. - Kó hàn nínú ayé rẹ. - Jèhófà yóò jẹ́ - Kó o láyọ̀ tòótọ́, - Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ. 
- 3. Lójú Ọlọ́run, ọmọ kékeré la jẹ́. - Ó yẹ ká jẹ́ kó tọ́ wa sọ́nà. - Ká b’Ọ́lọ́run rìn lójoojúmọ́ ayé wa; - Yóò bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀. - (ÈGBÈ) - S’òótọ́ di tìrẹ. - Kó hàn nínú ayé rẹ. - Jèhófà yóò jẹ́ - Kó o láyọ̀ tòótọ́, - Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ. 
(Tún wo Sm. 26:3; Òwe 8:35; 15:31; Jòh. 8:31, 32.)