ORIN 32
Dúró Ti Jèhófà!
- 1. Nígbà kan, a kò mohun táa fẹ́ ṣe. - Ìsìn èké sì ń darí ayé wa. - Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run - Mú káyọ̀ kún ọkàn wa. - (ÈGBÈ) - Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ. - Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀. - Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà, - Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá. 
- 2. A dúró ti Ọlọ́run níṣọ̀kan. - À ń wàásù Ìjọba rẹ̀ fáráyé. - Àkókò tó kí kálukú wọn yàn - Láti wá sin Ọlọ́run. - ((ÈGBÈ) - Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ. - Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀. - Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà, - Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá. 
- 3. A kò bẹ̀rù ohun t’Èṣù lè ṣe - Torí Jèhófà ni agbára wa. - Báwọn ọ̀tá tilẹ̀ pọ̀ jù wá lọ, - Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé. - (ÈGBÈ) - Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ. - Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀. - Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà, - Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá. 
(Tún wo Sm. 94:14; Òwe 3:5, 6; Héb. 13:5.)