ORIN 50
Àdúrà Ìyàsímímọ́ Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Màá sìn ọ́ tọkàntọkàn. - Fún mi lọ́gbọ́n àtòye. - Màá fi ohùn mi yìn ọ́; - Màá fi kọrin ìyìn rẹ. 
- 2. Gba ọwọ́ àtẹsẹ̀ mi; - Kí wọ́n máa pàṣẹ rẹ mọ́. - Gba gbogbo ìṣúra mi; - Mo fún ọ pátápátá. 
- 3. Mo fi ayé mi fún ọ. - Màá ṣohun tó o bá ti fẹ́. - Jẹ́ kí n máa múnú rẹ dùn - Jálẹ̀ ọjọ́ ayé mi. 
(Tún wo Sm. 40:8; Jòh. 8:29; 2 Kọ́r. 10:5.)