ORIN 103
Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jáà fún wa ní àwọn ọkùnrin; - Ẹ̀bùn nínú èèyàn. - Wọ́n ń fàpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀; - Wọ́n máa ń tọ́ wa sọ́nà. - (ÈGBÈ) - Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́ - Ni Ọlọ́run yàn fún wa - Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀; - Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn. 
- 2. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wa - Kì í fọ̀rọ̀ wa ṣeré. - Tí ìṣòro bá sì dé bá wa, - Wọ́n máa ń bójú tó wa. - (ÈGBÈ) - Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́ - Ni Ọlọ́run yàn fún wa - Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀; - Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn. 
- 3. Wọ́n máa ń gbà wá nímọ̀ràn tó dáa - Ká lè ṣohun tó tọ́. - Wọ́n máa ń pèsè ‘rànwọ́ tá a nílò - Ká lè máa jọ́sìn Jáà. - (ÈGBÈ) - Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́ - Ni Ọlọ́run yàn fún wa - Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀; 
Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn.
(Tún wo Àìsá. 32:1, 2; Jer. 3:15; Jòh. 21:15-17; Ìṣe 20:28.)