ORIN 57
Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn
- 1. A fẹ́ fi ìwà jọ Ọlọ́run wa, - Torí Jèhófà kì í ṣojúsàájú. - Gbogbo onírúurú èèyàn ló ń pè, - Kí wọ́n dọ̀rẹ́ rẹ̀, kó lè gbà wọ́n là. - (ÈGBÈ) - Ibi yòówù kí wọ́n wà, - Ọkàn ló ṣe pàtàkì. - Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá. - Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ - Wàásù ní ibi gbogbo - Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run. 
- 2. Ibi yòówù kí a ti lè rí wọn, - Bí wọ́n ṣe rí kọ́ ló ṣe pàtàkì. - Ṣùgbọ́n bí inú ọkàn wọn ṣe rí - Ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà. - (ÈGBÈ) - Ibi yòówù kí wọ́n wà, - Ọkàn ló ṣe pàtàkì. - Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá. - Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ - Wàásù ní ibi gbogbo - Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run. 
- 3. Gbogbo àwọn tó ti ṣe ìpinnu - Láti fàwọn ìwà ayé sílẹ̀, - La mọ̀ pé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà, - À ń lọ wàásù kí aráyé lè mọ̀. - (ÈGBÈ) - Ibi yòówù kí wọ́n wà, - Ọkàn ló ṣe pàtàkì. - Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá. - Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ - Wàásù ní ibi gbogbo - Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run. 
(Tún wo Jòh. 12:32; Ìṣe 10:34; 1 Tím. 4:10; Títù 2:11.)