-
Àwọn Ẹlẹ́rìí Títí Dé Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ AyéIlé-Ìṣọ́nà—1996 | June 15
-
-
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Ní Ìlà Oòrùn Etíkun Greenland
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ àkókò kan náà tí àwùjọ akéde náà dé Thule, ni tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan, Viggo àti Sonja, rin ìrìn àjò lọ sí agbègbè ìpínlẹ̀ míràn tí a kò ṣe rí—Ittoqqortoormiit (Scoresbysund) ní ìlà oòrùn etíkun Greenland. Láti lè débẹ̀, wọ́n ní láti rin ìrìn àjò lọ sí Iceland, kí wọ́n wọ ọkọ̀ òfuurufú padà sí Constable Point lórí etíkun Greenland, wọ́n sì tibẹ̀ wọ hẹlikọ́pítà.
Àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì wọ̀nyí, tí èdè àbínibí wọn jẹ́ ti àwọn ará Greenlandic sọ pé: ‘Ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò wà síhìn-ín nìyí. Láìka pé wọ́n wà ní àdádó sí, orí àwọn ènìyàn náà pé lọ́nà tí ó yani lẹ́nu. Síbẹ̀, inú wọn tún dùn láti kọ́ ohun tuntun. Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lẹ́bùn ìtàn sísọ, wọ́n fi ìháragàgà sọ fún wa nípa bí wọ́n ṣe ń ṣọdẹ séálì àti àwọn ìrírí mìíràn nípa ìṣẹ̀dá.” Báwo ni wọ́n ṣe dáhùn padà sí iṣẹ́ ìwàásù náà?
“Nígbà tí a ń wàásù láti ilé dé ilé, a pàdé J——, ẹni tí í ṣe katikíìsì. Ó wí pé: “Mo dúpẹ́ púpọ̀ pé ẹ fi mi kún àwọn ti ẹ óò bẹ̀ wò.’ A fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa hàn án àti bí a ṣe lè lò ó. Ní ọjọ́ kejì, ó wá sọ́dọ̀ wa, ó sì fẹ́ láti kọ́ nípa orúkọ Jèhófà. A fi àlàyé kan nínú àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé hàn án nínú Bíbélì èdè àwọn ará Greenland tirẹ̀. Nígbà tí a kúrò, ó tẹ àwọn ọ̀rẹ́ wa láago ní Nuuk láti bá òun dúpẹ́ fún ìbẹ̀wò wa. A gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní ríran ọkùnrin yìí lọ́wọ́.
“A tún pàdé O——, olùkọ́ kan tí ó mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó fún wa ní wákàtí méjì láti bá kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀ tí ó ní àwọn ọmọ ọdún 14 sí 16. Nítorí náà, a fi fídíò wa hàn wọ́n, a sì dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Kíá ni wọ́n gba Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́a àti àwọn ìwé mìíràn. A pàdé mẹ́ta nínú àwọn ọmọbìnrin náà lẹ́yìn náà. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè, ọ̀kan nínú wọn sì ní ọkàn ìfẹ́ gan-an. Ó béèrè pé, ‘Báwo ni ẹnì kan ṣe lè di Ẹlẹ́rìí? Yóò jẹ́ ohun tí ó dára púpọ̀ láti dà bíi tiyín. Dádì mi pẹ̀lú fẹ́ràn ohun tí ẹ ń ṣe.’ A ṣèlérí láti kọ̀wé.
“Nínú ọ̀kan nínú àwọn ìletò náà, a pàdé katikíìsì míràn, M——, a sì ní ìjíròrò fífani mọ́ra pẹ̀lú rẹ̀. Ó sọ pé òun yóò rí i dájú pé àwọn ọkùnrin tí wọ́n ṣọdẹ lọ yóò rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa gbà láìpẹ́ bí wọ́n bá ti ń padà dé. Nítorí náà, òun ni ‘akéde’ wa ní àdádó yẹn.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìrìn àjò aláyìípoyípo, tí ó sì ń tánni lókun, àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì náà nímọ̀lára pé a bù kún ìsapá wọn ní jìngbìnnì.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
-
-
“Ẹ Máa Mọyì Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀”Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | June 15
-
-
“Ẹ Máa Mọyì Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀”
NǸKAN kò fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán nínú ìjọ Kọ́ríńtì. Ọ̀ràn ìwà pálapàla tí ń múni gbọ̀n rìrì àti ìyapa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ará. Àwọn kan dojú kọ àwọn ìṣòro ara ẹni, tàbí àwọn ìbéèrè tí ń fẹ́ ìdáhùn. Àwọn ará kan ń gbé ara wọn lọ sí ilé ẹjọ́; àwọn mìíràn pàápàá sẹ àjíǹde.
Àwọn ìbéèrè pàtàkì dìde pẹ̀lú. Ó ha yẹ kí àwọn tí wọ́n ní agbo ilé tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ní ti ìsìn máa gbé pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó wọn tí kò gbà gbọ́, tàbí ó yẹ kí wọ́n pínyà? Kí ni ipa iṣẹ́ àwọn arábìnrin nínú ìjọ? Ó ha yẹ láti jẹ nínú ẹran tí a fi rúbọ sí òrìṣà bí? Báwo ni ó ṣe yẹ kí á darí àwọn ìpàdé—títí kan Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?—Kọ́ríńtì Kìíní 1:12; 5:1; 6:1; 7:1-3, 12, 13; 8:1; 11:18, 23-26; 14:26-35.
Láìsí iyè méjì, bí wọ́n ti ń ṣàníyàn nípa ire àwọn ará ní irú ipò àyíká tẹ̀mí tí ó jẹ́ onídààmú bẹ́ẹ̀, Ákáíkọ́sì, Fọ́túnátù, àti Sítéfánásì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò kan láti bẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wò ní Éfésù. Ní àfikún sí mímú ìròyìn tí ń yọni lẹ́nu bẹ́ẹ̀ wá, ó ṣeé ṣe pé wọ́n mú lẹ́tà tí ìjọ kọ, tí ó ní àwọn ìbéèrè lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí nínú wá fún Pọ́ọ̀lù. (Kọ́ríńtì Kìíní 7:1; 16:17) Ó dájú pé, àwọn arákùnrin mẹ́ta wọ̀nyí nìkan kọ́ ní ń ṣàníyàn nípa ipò náà. Ní tòótọ́, Pọ́ọ̀lù ti gbọ́ ìròyìn láti ẹnu “awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ará ilé Kílóè” pé ìyapa wà láàárín àwọn mẹ́ḿbà ìjọ. (Kọ́ríńtì Kìíní 1:11) Láìsí iyè mejì, ìròyìn àwọn ońṣẹ́ náà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ipò náà ní kedere, láti pinnu ìmọ̀ràn tí ó yẹ láti fún wọn, àti bí ó ti yẹ láti dáhùn àwọn ìbéèrè tí a gbé dìde. Ó dà bí ẹni pé lẹ́tà tí a mọ̀ sí Kọ́ríńtì Kìíní nísinsìnyí ni èsì Pọ́ọ̀lù, èyí tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run darí. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Ákáíkọ́sì, Fọ́túnátù, àti Sítéfánásì ni wọ́n fi èsì lẹ́tà náà jíṣẹ́.
Ta ni Ákáíkọ́sì, Fọ́túnátù, àti Sítéfánásì? Kí ni a lè rí kọ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa wọn?
Agbo Ilé Sítéfánásì
Agbo ilé Sítéfánásì ni “àkọ́so” iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ní Ákáyà, ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù, ní Gúúsù Ilẹ̀ Gíríìkì, ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ni ó sì batisí wọn. Dájúdájú, Pọ́ọ̀lù kà wọ́n sì ẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ, ipa ìdarí adàgbàdénú tí ó ṣeé gbára lé fún àwọn ará Kọ́ríńtì. Ó fi ìtara gbóríyìn fún wọn nítorí ìgbòkègbodò tí wọ́n ń ṣe nítorí ìjọ pé: “Wàyí o mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará: ẹ mọ̀ pé agbo ilé Sítéfánásì ni àkọ́so Ákáyà ati pé wọ́n ṣètò ara wọn láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́. Kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa mú ara yín juwọ́ sílẹ̀ ní ìtẹríba fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ àti fún gbogbo ẹni tí ó bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tí ó sì ń ṣe òpò.” (Kọ́ríńtì Kìíní 1:16; 16:15, 16) Ní ṣàkó, a kò sọ àwọn tí ó para pọ̀ di “agbo ilé” Sítéfánásì. Gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà ní ṣákálá lè túmọ̀ sí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé, ṣùgbọ́n ó tún lè ní àwọn ẹrú àti àwọn òṣìṣẹ́ nínú. Níwọ̀n bí Ákáíkọ́sì ti jẹ́ orúkọ ède Latin tí a ń lò fún ẹrú, tí a sì ń lo Fọ́túnátù fún ẹni òmìnira, àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan wòye pé ó ṣeé ṣe kí àwọn méjèèjì jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé kan náà yẹn.
Ohun yòówù kí ọ̀ràn náà jẹ́, Pọ́ọ̀lù ka agbo ilé Sítéfánásì sí àwòfiṣàpẹẹrẹ. Àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ti “ṣètò ara wọn lati ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́.” Ìdílé Sítéfánásì ti ní láti mọ̀ pé iṣẹ́ wà tí wọ́n ní láti ṣe fún ire ìjọ, wọ́n sì fínnú fíndọ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn yìí gẹ́gẹ́ bí ẹrù iṣẹ́ ara ẹni. Ìfẹ́ ọkàn wọn láti ṣe irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹni mímọ́ yẹ fún ìtìlẹ́yìn àti ìkàsí.
“Wọ́n Ti Tu Ẹ̀mí Mi àti Tiyín Lára”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn nípa ipò tí ń bẹ ní Kọ́ríńtì, dídé àwọn ońṣẹ́ mẹ́ta náà mú un láyọ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo yọ̀ lórí wíwà níhìn-ín Sítéfánásì àti Fọ́túnátù àti Ákáíkọ́sì, nítorí pé wọ́n ti dí àlàfo àìsí níhìn-ín yín. Nítorí wọ́n ti tu ẹ̀mí mi àti tiyín lára.” (Kọ́ríńtì Kìíní 16:17, 18) Ní gbígbé àyíká ipò náà yẹ̀ wò, ó ṣeé ṣe pé àìsí lọ́dọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì nípa ti ara ti jẹ́ àníyàn fún Pọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, rírí àwọn ikọ̀ wọn ṣojú fún gbogbo ìjọ. Ìròyìn wọn ti ní láti mú kí Pọ́ọ̀lù mọ bí ipò náà ti rí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, kí ó sì mú kí ìbẹ̀rù rẹ̀ dín kù díẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn nǹkan kò burú tó bí ó ti ronú tẹ́lẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ, kì í ṣe kìkì pé ìhìn iṣẹ́ àwọn mẹ́ta náà tu ẹ̀mí rẹ̀ lára nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ṣèrànwọ́ láti ru ẹ̀mí ìjọ Kọ́ríńtì sókè. Kò sí iyè méjì pé ó jẹ́ ìtùnú fún wọn láti mọ̀ pé àwọn ikọ̀ wọn ti ṣàlàyé bí gbogbo ipò ọ̀ràn náà ti rí fún Pọ́ọ̀lù yékéyéké, tí wọn yóò sì gba ìmọ̀ràn rẹ̀ bọ̀.
Nítorí náà, a fi tìtaratìtara gbóṣùbà fún Sítéfánásì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ méjì fún òpò wọn nítorí àwọn ará Kọ́ríńtì. Pọ́ọ̀lù mọrírì àwọn ọkùnrin wọ̀nyí débi pé, lẹ́yìn pípadà sílé, wọ́n ní láti pèsè ìdarísọ́nà nínú ìjọ Kọ́ríńtì tí ó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Àpọ́sítélì náà rọ àwọn ará pé: ‘Ẹ máa mú ara yín juwọ́ sílẹ̀ ní ìtẹríba fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ àti fún gbogbo ẹni tí ó bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tí ó sì ń ṣe òpò. . . . Ẹ máa mọyì irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀.’ (Kọ́ríńtì Kìíní 16:16, 18) Irú ìgbóṣùbà tìtaratìtara bẹ́ẹ̀, fi ìdúróṣinṣin pátápátá tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní láìka pákáǹleke tí ń bẹ láàárín ìjọ sí hàn kedere. Ó yẹ kí a ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.—Fílípì 2:29.
Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Oníṣòtítọ́ Ń Mú Àbájáde Àtàtà Wá
Kò sí iyè méjì nípa rẹ̀, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ètò àjọ Jèhófà àti àwọn aṣojú rẹ̀ ń mú àbájáde àtàtà wá. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà tí a mọ̀ sí Kọ́ríńtì Kejì nísinsìnyí, kété lẹ́yìn lẹ́tà àkọ́kọ́, nǹkan ti ń sunwọ̀n sí i nínú ìjọ. Ìgbòkègbodò onísùúrù tí ń bá a nìṣó ti àwọn ará bíi Ákáíkọ́sì, Fọ́túnátù, àti Sítéfánásì, títí kan ìbẹ̀wò Títù, tí mú àbájáde rere wá.—Kọ́ríńtì Kejì 7:8-15; fi wé Ìṣe 16:4, 5.
Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí lè jàǹfààní nípa ṣíṣàṣàrò lórí ìròyìn kúkúrú tí a ṣe nínú Ìwé Mímọ́ nípa àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ wọ̀nyí. Fún àpẹẹrẹ, jẹ́ kí á sọ pé fún àwọn ìdí kan, a kò lè yanjú ipò ọ̀ràn kan tí ń bá a nìṣó nínú ìjọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tí ó sì mú kí àwọn ará máa ṣàníyàn. Kí ni ó yẹ kí á ṣe? Fara wé Sítéfánásì, Fọ́túnátù, àti Ákáíkọ́sì, tí wọn kò sá fún ẹrù iṣẹ́ wọn láti fi ipò ọ̀ràn náà tó Pọ́ọ̀lù létí, lẹ́yìn náà, kí o sì fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ fún Jèhófà. Lọ́nàkọnà, wọn kò jẹ́ kí ìtara fún òdodo mú wọn gbé ìgbésẹ̀ dídá ìpinnu ṣe tàbí láti “bínú sí Olúwa.”—Òwe 19:3.
Ìjọ jẹ́ ti Jésù Kristi, àti ní àkókò yíyẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní Kọ́ríńtì, òun yóò gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú ìṣòro èyíkéyìí tí ó lè wu ire àti àlàáfíà wọn nípa tẹ̀mí léwu. (Éfésù 1:22; Ìṣípayá 1:12, 13, 20; 2:1-4) Ní báyìí náà, bí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà tí Sítéfánásì, Fọ́túnátù, àti Ákáíkọ́sì fi lélẹ̀, tí a sì ń bá a nìṣó láti ṣòpò nínú ṣíṣiṣẹ́ sin àwọn ará wa, àwa pẹ̀lú yóò máa fi ìṣòtítọ́ ti ìṣètò ìjọ lẹ́yìn, ní gbígbé àwọn ará wa ró, àti ní ‘ríru wọ́n lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’—Hébérù 10:24, 25.
-