‘Kí Ni Mo Lè Ṣe?’
1 ‘Kí ni mo lè ṣe?’ Dájúdájú, ìbéèrè yìí ló wà lọ́kàn àwọn mẹ́ńbà àwùjọ kéréje tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn tí Charles Taze Russell kó jọ ní àwọn ọdún 1870. Bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń lóye ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìgbàanì á ti ṣe kàyéfì nípa ohun tí àwọ́n lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ ète Ọlọ́run. Ó dájú pé, sísọ́ fún gbogbo ayé nípa ìmọ̀ Bíbélì tí wọ́n ń jèrè jẹ́ iṣẹ́ bàǹtàbanta kan.
2 Inú wa dùn pé wọ́n borí ìpèníjà yẹn. Báwo ni wọ́n ṣe borí rẹ̀? Ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe ipa tirẹ̀, kódà bó tilẹ̀ dà bíi pé kò tó nǹkan, tó fi jẹ́ pé lónìí, wọ́n ti mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé—ètò àjọ àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà, tí ń pòkìkí Ìjọba náà, tí a sì ń sìn nínú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún [90,000] ìjọ ní igba àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀ àti àwọn erékùṣù òkun!—Aísá. 60:22.
3 Ṣètìlẹ́yìn Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́: Ó ṣe kókó pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa kópa nínú iṣẹ́ bàǹtàbanta tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé a ó ṣe ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. (Máàkù 13:10) Dájúdájú, a ò lè dá iṣẹ́ yìí dá ìwọ̀nba kéréje àwọn alàgbà nìkan; bẹ́ẹ̀ sì ni wíwàásù kì í ṣe iṣẹ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà nìkan. Ká sòótọ́, gbogbo Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ ló gbọ́dọ̀ kó ipa pàtàkì. Gbogbo wa ló lè lọ́wọ́ nínú onírúurú iṣẹ́ ìwàásù. (1 Tím. 1:12) Bí a bá ṣe lè ṣe é tó, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe máa ṣe ara wa àti àwọn ẹlòmíràn láǹfààní.—1 Tím. 4:16.
4 Ẹnì kọ̀ọ̀kan tún lè ti ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa lẹ́yìn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ní àwọn ọ̀nà pàtàkì mìíràn. A lè ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìpàdé ìjọ nípa lílọ sí ìpàdé déédéé àti nípa fífi ìtara ọkàn kópa nínú ìpàdé. (Sm. 122:1, 8, 9) A lè ṣe ipa tiwa láti mú kí ìjọ jẹ́ mímọ́ ní ti ìwà rere. Bí agbára wa bá ṣe tó, a lè fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé náà. A lè nípìn-ín nínú títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe kó mọ́ tónítóní. Gbogbo wa ló lè gbé ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí ìtara lárugẹ nínú ìjọ nípa ríran àwọn ẹni tuntun, àwọn èwe, àti àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́.—Kól. 3:12, 14.
5 Nítorí náà, o lè béèrè pé, ‘Kí ni mo lè ṣe?’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsapá tóo ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè dà bíi pé kò tó nǹkan, nípa ṣíṣe ipa tìrẹ, ṣe lo ń mú kí ìjọ lágbára, kó jáfáfá, kó sì lera. Nípa báyìí, gbogbo wa là ń kópa pàtàkì nínú bíbọlá fún orúkọ Jèhófà!