ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/00 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 3/00 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 13

Orin 118

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: “Ìhìn Rere Là Ń Wàásù.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ àpẹẹrẹ àwọn kókó látinú Ìwé Mímọ́ tí a lè lò nínú ìwé Ìmọ̀ nígbà tí a bá ń fi í lọ àwọn èèyàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

20 min: “Ǹjẹ́ A Lè Mú Kí April 2000 Jẹ́ Oṣù Tí A Tíì Ṣe Dáadáa Jù Lọ?” (Ìpínrọ̀ 1 sí 11) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Mẹ́nu kan iye àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó pọ̀ jù lọ tí ìjọ ní ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Jẹ́ kí àwọn kan tó wà lára iye tí o mẹ́nu kàn yẹn sọ nípa àwọn àǹfààní tí àwọn fúnra wọn rí jẹ nígbà tí wọ́n túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Fún ìjọ níṣìírí pé kí wọ́n gbìyànjú kí iye àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tí ẹ óò ní ní oṣù April lè pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ohun tí a ń wò láti mọ̀ bóyá ẹnì kan tóótun, níbi tí a kọ ọ́ sí nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 113 àti 114. Àwọn akéde tó ń fẹ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè gba fọ́ọ̀mù lẹ́yìn ìpàdé.

Orin 187 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 20

Orin 21

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: “Kí Ni Mo Lè Ṣe?” Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan bá ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tàbí méjì jíròrò àpilẹ̀kọ yìí. Nítorí àwọn nǹkan kan tí kò lè jẹ́ kí àwọn akéde kan ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́, wọ́n lè máa ronú pé ìtìlẹ́yìn tí àwọn lè ṣe fún ìgbòkègbodò ìjọ kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí gbogbo wa fi lè ṣètìlẹ́yìn dáadáa fún fífún ìjọ lókun, kí a sì mú kí iṣẹ́ Ìjọba náà máa tẹ̀ síwájú. Parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa fífi hàn bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe lè ‘Nípìn-ín Nínú Ìròyìn Ìkẹyìn.’—Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 109 àti 110.

20 min: “Ǹjẹ́ A Lè Mú Kí April 2000 Jẹ́ Oṣù Tí A Tíì Ṣe Dáadáa Jù Lọ?” (Ìpínrọ̀ 12 sí 18) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àṣefihàn ṣókí kún un tó ń ṣàfihàn bí a ṣe lè ké sí ojúlùmọ̀ ẹni wá sí Ìṣe Ìrántí. Ṣàyẹ̀wò oṣù April lórí Kàlẹ́ńdà ti Ọdún 2000, kí o sì sọ àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn tí a wéwèé nínú ìjọ. Rán gbogbo ìjọ létí pé kí olúkúlùkù ṣètò tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó lóṣù náà, kí a ní i lọ́kàn pé gbogbo ìjọ ló fẹ́ kópa nínú rẹ̀. Fún gbogbo àwọn tó bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ níṣìírí pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì gba fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé.

Orin 65 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 27

Orin 119

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù March sílẹ̀. Ṣèfilọ̀ orúkọ àwọn tó máa ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April. Ṣàlàyé pé kò tíì pẹ́ jù láti forúkọ sílẹ̀. Mẹ́nu kan gbogbo ètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí a wéwèé fún oṣù náà. Fún gbogbo akéde níṣìírí láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lópin ọ̀sẹ̀ yìí, kí a tipa bẹ́ẹ̀ fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ oṣù April. Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó fi lọni lóṣù náà. Ṣàlàyé àpilẹ̀kọ kan àti àwọn kókó yíyẹ tí a lè jíròrò nípa rẹ̀, tí a lè lò lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti fi gbọ́rọ̀ kalẹ̀ nígbà tí a bá ń fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìtẹ̀jáde lọ́ọ́lọ́ọ́ náà lọni. Kí gbogbo akéde ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, kí a sì lò ó láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé pẹ̀lú àwọn tó bá fìfẹ́ hàn.

10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

25 min: “Lo Àwọn Ìwé Wa Lọ́nà Ọgbọ́n.” Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn jíjíròrò ìpínrọ̀ 7, jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn méjì tàbí mẹ́ta tí kò gùn jù nípa lílo díẹ̀ lára àwọn àbá tó wà ní ìpínrọ̀ 4 sí 7.

Orin 195 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 3

Orin 72

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò àti ìrírí tí a ní lóde ẹ̀rí. Lo àwọn ìrírí lọ́ọ́lọ́ọ́ tí o yàn, tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, tí yóò sì fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

17 min: “Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, ṣàlàyé bí a ó ṣe jàǹfààní látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwé Bíbélì, tí a ń pè ní Dáníẹ́lì. (Wo orí 1, ìpínrọ̀ 15 sí 17, nínú ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì.) Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti máa lọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ déédéé.

18 min: Ṣé Ó Yẹ Kí N Fẹjọ́ Ẹni Tó Hùwà Àìtọ́ Wíwúwo Sùn? Àsọyé tí alàgbà kan sọ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, ó darí rẹ̀ sí àwọn ọ̀dọ́. Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ti ṣẹlẹ̀ láwùjọ àwọn èèyàn lónìí, wọ́n sì ti ní ipa tò léwu lórí àwọn ọ̀dọ́: ìlànà ìwà rere tí ń bàjẹ́ sí i, ìwà ipá tí ń pọ̀ sí i, sísọ oògùn lílò di bárakú, àti ṣíṣàìbọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ. Àwọn ọ̀dọ́langba kan ń gbé ìgbésí ayé méjì, wọ́n sì ń fi ìwà àìtọ́ wọn pa mọ́. Èyí ń wu ìlera ìjọ lápapọ̀ nípa tẹ̀mí léwu. Àwọn kan dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, wọ́n sì fẹ́ láti bò ó mọ́lẹ̀. Bí o bá mọ̀ pé arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan nínú ìjọ ti ṣe ohun kan tó rú òfin Ọlọ́run lọ́nà wíwúwo, kí ló yẹ kí o ṣe? Jíròrò ìlànà tó wà ní Léfítíkù 5:1. (Wo Ilé Ìṣọ́, August 15, 1997, ojú ìwé 27 sí 30.) Tọ́ka sí ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, ojú ìwé 68 àti 69, kí o sì ṣàlàyé ohun tó yẹ kéèyàn ṣe nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.

Orin 68 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́