ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 7/8 ojú ìwé 10-14
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Àwọn Onígboyà Lójú Ewu Nazi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Àwọn Onígboyà Lójú Ewu Nazi
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọn Kò Bá Hitler Dọ́rẹ̀ẹ́
  • Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Sẹ́yìn
  • Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Nígbà Tí Hitler Gorí Àléfà?
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Gbé Ìgbésẹ̀ Onígboyà
  • Àpéjọpọ̀ Ìgboyà Tàbí ti Ìbánidọ́rẹ̀ẹ́?
  • Ìsọjáde Èrò Ọkàn
  • Àwọn Onígboyà Olùpàwàtítọ́mọ́ Borí Inúnibíni Ìjọba Násì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Dídúró Gbọn-in Nígbà Tí Ìjọba Násì Gba Netherlands
    Jí!—1999
  • “Wọ́n Kọ̀ Jálẹ̀ Ó Yẹ Ká Bọ̀wọ̀ fún Wọn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Jí!—1998
g98 7/8 ojú ìwé 10-14

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Àwọn Onígboyà Lójú Ewu Nazi

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GERMANY

ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ni a mọ̀ dunjú fún rírọ̀ tí wọ́n ń rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, láìyẹsẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí gba ìgboyà, ó sì dájú pé ó ń kan ìgbésí ayé wọn àti àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.

Bí àpẹẹrẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń bọ̀wọ̀ gidigidi fún àwọn ènìyàn ní gbogbo ẹ̀yà àti àṣà ìbílẹ̀. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn. (Mátíù 22:35-40) Dájúdájú, wọ́n fara mọ́ àpọ́sítélì Pétérù pátápátá, tí ó wí pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Kárí ayé, a tún mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fún òfin, ètò, àti àṣẹ ìjọba. Wọn kò fìgbà kankan jẹ́ orísun ìṣọ̀tẹ̀síjọba, wọn kò sì ní jẹ́ bẹ́ẹ̀ láé. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí a bá tilẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wọn ní àwọn ilẹ̀ kan pàápàá nítorí pé wọ́n mú ipò kan náà tí àwọn àpọ́sítélì mú pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29; Mátíù 24:9) Nígbà kan náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí mọ ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn láti jọ́sìn lọ́nà tí ẹ̀rí ọkàn wọn pinnu lámọ̀jẹ́wọ́.

Ipò onígboyà ti Kristẹni tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú ní Germany àti àwọn ilẹ̀ mìíràn tí Adolf Hitler ṣàkóso lé lórí wà nínú ìtàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó gbàfiyèsí ní Berlin, Germany, ní 1933 ṣàgbéyọ ìgboyà wọn, ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run àti aládùúgbò, àti ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fún òfin, ètò, àti òmìnira ìsìn.

Wọn Kò Bá Hitler Dọ́rẹ̀ẹ́

Ó lé ní 50 ọdún sẹ́yìn tí ìṣàkóso apániláyà ọlọ́dún 12, tí ó jẹ́ ti ẹ̀tanú ìran àti ìpànìyàn, ti Hitler, wá sópin. Síbẹ̀, sáà àkóso Nazi yẹn ṣe ìpalára tí ń ba ìran ènìyàn nínú jẹ́ títí dòní.

Ìtàn fi hàn pé àwùjọ ènìyàn mélòó kan péré ló ta ko ìpániláyà Nazi, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí i. Lára wọn ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí a ṣàpèjúwe bí “àwùjọ kéréje tí ó dúró gbọn-in [lórí ìwàrere] nídìí àtakò láàárín àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè kan tí ìpayà bá.” Àwọn òpìtàn tí a mọ̀ dunjú ti ṣàkọsílẹ̀ gan-an nípa ipò onígboyà wọn.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn alárìíwísí mélòó kan, tí àwọn kan tí wọ́n ti bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́ rí, tí wọ́n ti wá di apẹ̀yìndà wà lára wọn, ń fẹ̀sùn kan Àwọn Ẹlẹ́rìí pé wọ́n gbìyànjú láti bá àkóso Hitler lẹ̀dí àpò pọ̀ nígbà tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Wọ́n sọ pé àwọn aṣojú Watch Tower Society gbìyànjú láìṣàṣeyọrí láti rí ojúrere ìjọba tuntun náà, àti pé, ó kéré tán, fún àkókò kan, wọ́n fọwọ́ sí èròǹgbà ẹlẹ́yàmẹ̀yà àwọn Nazi, tó wá yọrí sí pípa mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Júù.

Àwọn ẹ̀sùn eléwu wọ̀nyí jẹ́ irọ́ pátápátá. Àwọn àlàyé tí a ṣe síhìn-ín jẹ́ àtúpalẹ̀ aláìfọ̀rọ̀-bọpobọyọ̀ tí a gbé karí àwọn àkọsílẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ìtàn tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nípa àwọn ohun tí a ń sọ̀rọ̀ lé lórí náà.

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Sẹ́yìn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣiṣẹ́ ní Germany ti lé ní 100 ọdún. Ní 1933, nǹkan bí 25,000 Ẹlẹ́rìí ló ń sin Jèhófà Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jákèjádò Germany.

Láìnáání òmìnira ìsìn tó wà nínú àkọsílẹ̀ òfin Germany nígbà náà, lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn, ní pàtàkì, àwọn alátakò nípa ìsìn, máa ń ṣe ìpolongo ìbanijẹ́ lòdì sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kódà ní 1921, wọ́n fẹ̀sùn kan Àwọn Ẹlẹ́rìí, tí a ń pè ní Ernste Bibelforscher (Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Onítara) nígbà náà, pé wọ́n ń bá àwọn Júù lẹ̀dí àpò pọ̀ nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alòdìsíjọba. Wọ́n pe Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ní Kọ́múníìsì “ẹni ìríra Júù,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹ̀rí kankan tí wọ́n mú jáde rí nípa àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ọmọ ilẹ̀ Switzerland náà, Karl Barth, kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Ẹ̀sùn pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá àwọn Kọ́múníìsì lẹ̀dí àpò pọ̀ lè jẹ́ nítorí àìgbọ́niyé tí a ṣe tipátipá tàbí tí a mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nìkan ni.”

Ìwé ìròyìn ṣọ́ọ̀ṣì kan ní Germany fẹ̀sùn kan Àwọn Ẹlẹ́rìí pé wọ́n ń bá àwọn Júù ṣe nínú ìdìmọ̀ ẹgbẹ́ afipágbàjọba. Ní dídáhùn sí èyí, ìwé ìròyìn The Golden Age (aṣíwájú fún Jí!) lédè German, nínú ìtẹ̀jáde rẹ̀ ti April 15, 1930, wí pé: “Kò sí ìdí kankan fún wa láti ka ẹ̀sùn yìí sí èébú—nítorí pé ó dá wa lójú pé, ó kéré tán, Júù kan ṣe pàtàkì lọ́nà kan náà bí ẹnì kan tó pe ara rẹ̀ ní Kristẹni; ṣùgbọ́n a kò fara mọ́ irọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì pa yìí nítorí pé ó pète láti sọ iṣẹ́ wa di aláìníyelórí, bí pé àwọn Júù la ń ṣe é fún, kì í ṣe fún Ìhìnrere.”

Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀kọ́ ìtàn, John Weiss, kọ̀wé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́yàmẹ̀yà ti Germany, wọn kò sì dààmú nípa ìkùnà àwọn Júù láti yí padà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣì rọ̀ mọ́ ojúlówó ìgbàgbọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti Kristẹni láti rọ gbogbo ẹni tí ó bá lè yí padà sọ́dọ̀ Kristi láti ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá ṣeé ràn lọ́wọ́.”

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Nígbà Tí Hitler Gorí Àléfà?

Ní January 30, 1933, wọ́n yan Adolf Hitler bí olórí tuntun fún ìjọba ilẹ̀ Germany. Níbẹ̀rẹ̀, ìjọba Hitler tiraka láti fi ìwà jàgídíjàgan àti àṣejù rẹ̀ pa mọ́. Nítorí náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí, pa pọ̀ pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará Germany mìíràn ní ìbẹ̀rẹ̀ 1933, gba Ẹgbẹ́ Àjùmọ̀ní Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí ìjọba alákòóso tó bófin mu ní àkókò náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí retí pé ìjọba Ẹgbẹ́ Àjùmọ̀ní (Nazi) náà yóò mọ̀ pé ẹgbẹ́ Kristẹni alálàáfíà, tí ń pòfin mọ́ yìí, kì í ṣe ewu kankan fún Orílẹ̀-Èdè náà. Èyí kì í ṣe fífi ìlànà Bíbélì báni dọ́rẹ̀ẹ́ lọ́nàkọnà. Bí ó ti ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ń fẹ́ láti jẹ́ kí ìjọba náà mọ òtítọ́ náà pé ìsìn wọn kì í ṣe ti ìṣèlú.

Kíákíá ló ti hàn pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tí ìjọba Nazi yóò kọ́kọ́ fẹ́ tẹ̀ lórí ba tipátipá. Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n pe Àwọn Ẹlẹ́rìí ní alájọṣe nínú ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ àjọṣe àwọn Kọ́múníìsì òun Júù kan. Ìpolongo inúnibíni sì bẹ̀rẹ̀.

Èé ṣe tí irú àwùjọ onísìn kékeré kan bẹ́ẹ̀ fi rí ìbínú ìjọba tuntun náà? Òpìtàn Brian Dunn tọ́ka sí ìdí pàtàkì mẹ́ta: (1) bí iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe jẹ́ kárí ayé, (2) bí wọ́n ṣe ta ko ẹlẹ́yàmẹ̀yà, àti (3) àìdásí-tọ̀túntòsì wọn nínú ọ̀ràn Orílẹ̀-èdè. Nítorí èrò wọn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, Àwọn Ẹlẹ́rìí ará Germany kọ̀ láti kí Hitler ní ìkí ìjúbà, wọn kò ti Ẹgbẹ́ Àjùmọ̀ní Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn, wọn kò sì gba iṣẹ́ ológun níkẹyìn.—Ẹ́kísódù 20:4, 5; Aísáyà 2:4; Jòhánù 17:16.

Ní ìyọrísí rẹ̀, àwọn ọlọ́pàá àti àwọn SA (Sturmabteilung ti Hitler, àwọn ọlọ́pàá àdáni oníjàgídíjàgan ti Nazi, àwọn Aláṣọ-aláwọ̀-ilẹ̀) halẹ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí náà, wọ́n fipá wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn, wọ́n tú ilé wọn wò, wọ́n sì fòòró wọn ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Ní April 24, 1933, àwọn aláṣẹ gbẹ́sẹ̀ lé ọ́fíìsì Watch Tower ní Magdeburg, Germany, wọ́n sì tì í pa. Lẹ́yìn tí wọ́n ti tú u wò, tí wọn kò rí ẹ̀rí akóbáni kankan, tí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Orílẹ̀-Èdè United States sì ń dúnkookò mọ́ wọn, àwọn ọlọ́pàá dá ilé náà padà. Bí ó ti wù kí ó rí, ní May 1933, wọn fòfin de iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ Germany.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Gbé Ìgbésẹ̀ Onígboyà

Láàárín sáà ìbẹ̀rẹ̀ yìí, Hitler fara balẹ̀ gbé ara rẹ̀ kalẹ̀ bí agbẹnusọ ìsìn Kristẹni. Ó kéde ìmúratán rẹ̀ láti fún àwọn ènìyàn ní òmìnira ìsìn, ó sì lérí pé òun yóò fún àwọn ẹ̀yà ìsìn Kristẹni ní “ẹ̀tọ́ aláìṣègbè.” Láti fìdí ipò rẹ̀ yìí múlẹ̀, olórí ìjọba tuntun náà lọ sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì. Àkókò yìí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò padà wá bá Germany jagun ń kókìkí àwọn àṣeyọrí Hitler.

Nítorí bí ipò àìfararọ náà ṣe ń peléke sí i ní Germany, Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, àti Paul Balzereit, alábòójútó ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Germany, pinnu láti gbé ìpolongo kan kalẹ̀ tí yóò jẹ́ kí Olórí Hitler, àwọn lọ́gàálọ́gàá nínú ìjọba, àti àwọn ará ìlú lápapọ̀ mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ewu kankan fún àwọn ará Germany àti Orílẹ̀-èdè náà. Ní kedere, Rutherford gbà gbọ́ pé Hitler kò mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń kọlu Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí pé àwọn ẹ̀ka ìsìn mìíràn ti purọ́ fún un nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí náà.

Nítorí náà, ọ́fíìsì tó wà ní Magdeburg ṣètò fún àpéjọpọ̀ kan láti lo ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Germany láti sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn jáde. Láàárín àkókò tí kò tó nǹkan náà, a ké sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò Germany láti wá sí Wilmersdorfer Tennishallen ní Berlin ní June 25, 1933. A retí nǹkan bí 5,000 ènìyàn. Láìka ojú ọjọ́ tí kò báradé náà sí, tìgboyàtìgboyà, àwọn tó lọ lé ní 7,000. Àwọn tó wà níbẹ̀ náà fọwọ́ sí ìpinnu kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ìkéde Òtítọ́.” Àkọsílẹ̀ yìí ké gbàjarè lòdì sí bí wọ́n ṣe ń dí iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́. Ó mú kí ipò wọn ṣe kedere, ó sì sẹ́ àwọn ẹ̀sùn àjọṣe ìlòdìsíjọba nítorí ọ̀ràn òṣèlú èyíkéyìí. Ó wí pé:

“Wọ́n fi ẹ̀sùn èké kàn wá lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ tí ń ṣàkóso ìjọba yìí . . . Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, a rọ àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè àti àwọn ènìyàn láti fiyè sí àwọn gbólóhùn òtítọ́ tí a kọ jáde yìí láìṣe ojúsàájú àti láìṣègbè.”

“A kò bá ẹnikẹ́ni tàbí olùkọ́ ìsìn kankan jà, ṣùgbọ́n a ní láti pàfiyèsí sí òtítọ́ náà pé ní gbogbogbòò, àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣojú Ọlọ́run àti Kristi Jésù, ni àwọn tí ń ṣenúnibíni sí wa, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ èké nípa wa fún ìjọba.”

Àpéjọpọ̀ Ìgboyà Tàbí ti Ìbánidọ́rẹ̀ẹ́?

Àwọn kan nísinsìnyí ń sọ pé àpéjọpọ̀ Berlin ti 1933 àti “Ìkéde Òtítọ́” náà jẹ́ ìgbìyànjú tí àwọn abẹnugan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún ìjọba Nazi àti ìkórìíra tí ìjọba náà ní fún àwọn Júù. Àmọ́ ohun tí wọ́n sọ yìí kì í ṣe òtítọ́. Wọ́n gbé wọn karí àṣìrò àti àṣìtúmọ̀ nípa àwọn òtítọ́ náà.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn alárìíwísí sọ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí fí àwọn àsíá Nazi ṣe Wilmersdorfer Tennishallen lọ́ṣọ̀ọ́. Ní kedere, àwọn àwòrán àpéjọpọ̀ 1933 náà fi hàn pé wọn kò gbé àsíá Nazi kankan sínú gbọ̀ngàn náà. Àwọn tó wà níbẹ̀ ń fọwọ́ sọ̀yà pé kò sí àsíá kankan nínú ilé náà.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeé ṣe kí àwọn àsíá ti wà ní ìta ilé náà. Ẹgbẹ́ ológun Nazi kan ti lo gbọ̀ngàn náà ní June 21, ọjọ́ Wednesday tó ṣáájú àpéjọpọ̀ náà. Lẹ́yìn náà, ní ọjọ́ tó ṣáájú àpéjọpọ̀ náà gan-an, àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ kan àti àwọn ẹ̀ka SS (Schutzstaffel, tó jẹ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ Aláṣọ-dúdú ti Hitler níbẹ̀rẹ̀), àwọn SA, àti àwọn mìíràn ti ṣayẹyẹ ọjọ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó gùn jù lọ láàárín ọdún, nítòsí. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n débẹ̀ fún àpéjọpọ̀ náà ní Sunday ti bá ilé náà ní ipò pé wọ́n fi àwọn àsíá Nazi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.

Ká ní Àwọn Ẹlẹ́rìí náà bá àwọn àsíá Nazi tí a fi ṣe ìta, àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀, kódà inú ilé náà lọ́ṣọ̀ọ́ níbẹ̀, wọn kò jẹ́ fọwọ́ kàn wọ́n. Kódà lónìí pàápàá, nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá háyà àwọn ilé tí àwọn ará ìlú lápapọ̀ ń lò fún àwọn ìpàdé àti àpéjọpọ̀, wọn kì í palẹ̀ àwọn àmì orílẹ̀-èdè mọ́ kúrò. Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí náà fúnra wọn gbé àsíá kankan ró tàbí pé wọ́n kí àsíá.

Àwọn alárìíwísí tún sọ pé orin ògo orílẹ̀-èdè Germany ni Àwọn Ẹlẹ́rìí fi bẹ̀rẹ̀ àpéjọpọ̀ náà. Ní gidi, orin “Ìrètí Ológo ti Síónì,” Orin 64 nínú ìwé orin ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí, ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ àpéjọpọ̀ náà. Àwọn ọ̀rọ̀ orin yìí bá ohùn orin tí Joseph Haydn gbé kalẹ̀ ní 1797 mu. Ó kéré tán, orin 64 ti wà nínú ìwé orin Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti 1905 wá. Ni 1922, ìjọba ilẹ̀ Germany mú ohùn orin Haydn àti àwọn ọ̀rọ̀ orin tí Hoffmann von Fallersleben kó jọ bí orin ògo orílẹ̀-èdè wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Germany máa ń kọ Orin 64 wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Ó ṣòro láti sọ pé kíkọ orin kan nípa Síónì lè jẹ́ ìsapá láti pẹtù sí àwọn Nazi lọ́kàn. Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìlòdìsí tí àwọn Nazi ọ̀tá Júù ń sọ, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mìíràn yọ àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù bí “Júdà,” “Jèhófà,” àti “Síónì” kúrò nínú àwọn ọ̀rọ̀ orin àti ààtò ìsìn wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dájú nígbà náà pé àwọn tó ṣètò àpéjọpọ̀ náà kò retí láti rí ojúrere ìjọba náà nípa kíkọ orin kan tí ń gbé Síónì lékè. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan tó wà ní àpéjọpọ̀ náà ti lọ́ra láti kọ orin “Ìrètí Ológo Síónì” nítorí ohùn orin tí Haydn gbé kalẹ̀ yìí bá ohùn orin ògo orílẹ̀-èdè dọ́gba.

Ìsọjáde Èrò Ọkàn

Bí ìjọba ṣe ń yí padà, tí orílẹ̀-èdè náà sì ń kojú ipò ìdàrúdàpọ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ń fẹ́ ṣe ìpolongo kedere nípa ipò wọn. Nípasẹ̀ “Ìkéde” náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí sẹ́ àwọn ẹ̀sùn àjọṣe ọ̀ràn ìnáwó tàbí ti ìṣèlú pẹ̀lú àwọn Júù tagbáratagbára. Nípa bẹ́ẹ̀, àkọsílẹ̀ náà sọ pé:

“Àwọn ọ̀tá wa fẹ̀sùn èké kàn wá pé a ti gba ìtìlẹyìn owó fún iṣẹ́ wa láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù. Irọ́ kan kò tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ. Títí di wákàtí ọ̀wọ̀ yìí, àwọn Júù kò tí ì dá kọ́bọ̀ tó yọ́ fún iṣẹ́ wa.”

Níwọ̀n bí ó ti mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ owó, “Ìkéde” náà ń bá a lọ láti sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn àṣà àìtọ́ nínú ìṣòwò ńlá. Ó wí pé: “Àwọn Júù oníṣòwò láti ilẹ̀ ọba Britain òun Amẹ́ríkà ló ti gbé Ẹgbẹ́ Ìṣòwò Tó Ń Nípa Lórí Àwùjọ Ènìyàn àti Ìṣèlú kalẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe é láti fi kó àwọn ènìyàn ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nífà àti láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.”

Ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ yìí kò tọ́ka sí àwọn Júù ní gbogbogbòò, ó sì ṣe wá láàánú bí ẹnikẹ́ni bá ṣi gbólóhùn yìí lóye tàbí bí ó bá ti fa ìbínú fún ẹnikẹ́ni. Àwọn kan ti sọ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara mọ́ ìkógunti àwọn Júù tí wọ́n fi ń kọ́ni lọ́nà wíwọ́pọ̀ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Germany nígbà náà. Irọ́ pátápátá ni èyí. Nípasẹ̀ àwọn ìwé wọn àti ìwà wọn nígbà ìṣàkóso Nazi, Àwọn Ẹlẹ́rìí kọ àwọn èrò tó lòdì sí àwọn Júù sílẹ̀, wọ́n sì dá ìwà ìkà tí àwọn Nazi hù sí àwọn Júù lẹ́bi. Dájúdájú, a rí ẹ̀rí tó lágbára gidi lòdì sí ẹ̀sùn yìí nínú inúrere tí wọ́n ní fún àwọn Júù tí wọ́n jọ wà nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.

Ní kedere, “Ìkéde” náà fi iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí hàn pé ó jẹ́ ti ìsìn, ó wí pé: “Àjọ wa kì í ṣe ti ìṣèlú lọ́nàkọnà. A wulẹ̀ ń rin kinkin mọ́ kíkọ́ àwọn ènìyàn ní Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni.”

“Ìkéde” náà tún rán ìjọba létí àwọn ìlérí tó ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí fara mọ́ àwọn ètò rere kan, ìjọba ilẹ̀ Germany sì ṣètìlẹ́yìn fún ìwọ̀nyí ní gbangba. Lára ìwọ̀nyí ni ohun ìníyelórí ti ìdílé àti òmìnira ìsìn.

Nípa èyí, “Ìkéde” náà fi kún un pé: “Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìwé àti ìtẹ̀jáde wa fínnífínní yóò fi òtítọ́ náà hàn pé, a la àwọn ètò jíjọjú, tí ìjọba tó wà lórí àléfà lórílẹ̀-èdè yìí ní báyìí ní, tí wọ́n sì gbé kalẹ̀, lẹ́sẹẹsẹ, a sì tẹnu mọ́ wọn nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, tí a sì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run yóò rí i dájú pé ọwọ́ gbogbo àwọn olùfẹ́-òdodo tẹ àwọn ètò rere wọ̀nyí láìpẹ́.”

Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí ìgbà kankan tí Àwọn Ẹlẹ́rìí sọ pé àwọn ti Ẹgbẹ́ Nazi lẹ́yìn. Síwájú sí i, ní lílo òmìnira ìsìn, wọn kò fìgbà kankan pète láti ṣíwọ́ iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe ní gbangba.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó wà nínú ìwé 1974 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ṣe fi hàn, ó dun Àwọn Ẹlẹ́rìí ará Germany díẹ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú “Ìkéde” náà kò ṣàlàyé kíkún tó ṣe kedere jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣé alábòójútó ọ́fíìsì ẹ̀ka náà, Paul Balzereit, ni kò jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ inú àkọsílẹ̀ náà lágbára tó? Ó tì o, nígbà tí a fi àkọsílẹ̀ náà lédè German wé ti Gẹ̀ẹ́sì, a rí i pé, kò rí bẹ́ẹ̀. Ní kedere, a gbé èrò tó yàtọ̀ sí ìyẹn karí àkíyèsí tí èrò ara ẹni nípa lórí rẹ̀, tí àwọn kan tí kò kópa tààrà nínú kíkọ “Ìkéde” náà sílẹ̀ ṣe. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti dé orí èrò yẹn nítorí òtítọ́ náà pé ní ọdún méjì péré lẹ́yìn náà, Balzereit kọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ sílẹ̀.

A ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé wọ́n ti gbé àṣẹ ìfòfinde Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Germany kalẹ̀ ní Saturday, June 24, 1933, ọjọ́ kan péré ṣáájú àpéjọpọ̀ Berlin náà. Àwọn tó ṣètò àpéjọpọ̀ náà àti àwọn ọlọ́pàá wá mọ̀ nípa ìfòfindè náà ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà. Lójú ipò tí kò fara rọ àti ìkóguntini láti ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ Nazi, ó gbàfiyèsí pé wọ́n tilẹ̀ lè ṣe àpéjọpọ̀ náà rárá. Kì í ṣe àsọdùn láti sọ pé àwọn 7,000 Ẹlẹ́rìí tó lọ sí àpéjọpọ̀ yẹn fi òmìnira wọn wewu tìgboyàtìgboyà.

Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí pín mílíọ̀nù 2.1 ẹ̀dà “Ìkéde” náà. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n mú Àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀, tí wọ́n sì kó wọn lọ sí àwọn àgọ́ ìfìyàjẹni oníṣẹ́ àṣekára. Nípa bẹ́ẹ̀, ìjọba Nazi ṣàfihàn ìwà ìgbonimọ́lẹ̀ oníkà rẹ̀, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí ó fi bẹ̀rẹ̀ ìkọlù àjàkú akátá rẹ̀ lòdì sí àwùjọ kékeré ti àwọn Kristẹni yìí.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Christine King kọ̀wé pé: “Àwọn Nazi wá mọ̀ pé ìwà ipá kò lè tẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí rì.” Ó rí bí “Ìkéde” náà ṣe sọ gan-an pé: “Agbára Jèhófà Ọlọ́run ló ju agbára gbogbo lọ, kò sì sí agbára kankan tó lè ṣàṣeyọrí ní dídènà rẹ̀.”a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a  A kò ní àyè tó láti kọ gbogbo àkọsílẹ̀ onítàn yìí jáde. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìwé ìtọ́kasí wà ní kíkún tí àwọn tó ṣe ìwé yìí jáde lè pèsè bí a bá béèrè fún un. O tún lè mọ púpọ̀ sí i nípa wíwo fídíò Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn fọ́tò tí a yà níbi àpéjọpọ̀ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní 1933 ní Tennishallen gan-an

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́