-
Àwọn Ìfilọ̀Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | July
-
-
Àwọn Ìfilọ̀
Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù July àti August: Èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí ni kẹ́ ẹ lò: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọ́run Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la ó lò. Ẹ sì lè lo ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà bí àfirọ́pò. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ni kẹ́ ẹ lò. Báwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn, jọ̀wọ́ fún onílé ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Bó o bá sì ń padà lọ, kó o ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Láti oṣù September lọ, ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo èèyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni, “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Jẹ́ Kí Bíbélì Máa Ṣamọ̀nà Rẹ̀?”
◼ Kí gbogbo ìjọ tá a ní kí wọ́n lọ ṣèpàdé ní Àpéjọ Àgbègbè ti Uzuakoli 9 jọ̀wọ́ kíyè sí i pé àpéjọ náà yóò wáyé lédè Gẹ̀ẹ́sì, kò ní jẹ́ lédè Ìgbò mọ́ báa ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 2005. Bákan náà, Àpéjọ Àgbègbè ti Dálùwọ́n 6 yóò jẹ́ lédè Yorùbá.
◼ A fi fọ́ọ̀mù nípa àwọn tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, ìyẹn Literacy Report, méjì-méjì ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Bẹ́ ẹ bá ti kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù méjèèjì, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní August 1. Kẹ́ ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì ìjọ. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè si pé bí gbogbo akéde ìjọ yín bá tiẹ̀ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, tàbí tí ẹ kò bá ní kíláàsì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà kankan, a ṣì máa fẹ́ kẹ́ ẹ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù méjèèjì, kẹ́ ẹ sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì kí ìsọfúnni tá a ní lọ́wọ́ lè péye.
◼ A dábàá pé kẹ́ ẹ máa fi àwọn ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán, lóṣù kan ṣáájú déétì tí akéde náà fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀. Kí akọ̀wé rí i pé àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn fọ́ọ̀mù náà pé pérépéré. Báwọn tó fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà ò bá lè rántí ọjọ́ tí wọ́n ṣèrìbọmi, kí wọ́n fojú bu déétì kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ síbì kan. Kí akọ̀wé kọ déétì náà sórí káàdì Congregation’s Publisher Record (S-21), ìyẹn àkọsílẹ̀ akéde ìjọ.
◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé lẹ́tà tá a fi yan àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ, ìyẹn Pioneer Appointment Letter (S-202), wà lọ́wọ́. Bí ti aṣáájú ọ̀nà èyíkéyìí ò bá sí nínú fáìlì ìjọ, kí wọ́n jọ̀wọ́ kọ̀wé láti béèrè fún un ní ẹ̀ka ọ́fíìsì.
-
-
Bó O Ṣe Lè Mú Káwọn Ọmọ Rẹ Máa Tẹ̀ Síwájú Lẹ́nu Iṣẹ́ ÌwàásùIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | July
-
-
Bó O Ṣe Lè Mú Káwọn Ọmọ Rẹ Máa Tẹ̀ Síwájú Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
1 Ojúṣe àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti kékeré. Onírúuru ọ̀nà ni wọ́n sì lè gbà ṣe é. Àwọn ọmọ kan wà tí wọ́n lẹ́bùn àtimáa ka ẹsẹ Bíbélì lórí kódà kí wọ́n tó mọ̀wé kà pàápàá. Èyí sì máa ń wú àwọn tá à ń wàásù fún lórí. Báwọn ọmọ kéékèèké yìí bá dàgbà, wọ́n á lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù náà ju bá a ṣe rò. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wàásù? Ó ṣeé ṣe káwọn àbá tó tẹ̀lé e yìí ṣèrànwọ́ síwájú sí i.
2 Lẹ́yìn tó o bá ti kí onílé, ó lè sọ pé:
◼ “Ọ̀rọ̀ pàtàkì kan wà nínú Ìwé Mímọ́ tí ọmọkùnrin mi yìí, [dárúkọ rẹ̀], fẹ́ fi hàn ọ́.” Ọmọ rẹ lè sọ pé: “Ọ̀rọ̀ inú Sáàmù yìí ló jẹ́ kí n mọ orúkọ Ọlọ́run. [Kí ọmọ náà ka Sáàmù 83:18 látinú Bíbélì tàbí kó kà á lórí.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run máa ṣe fún wa. Ṣé kí n kúkú fi eléyìí sílẹ̀ fún yín?” O lè kádìí ìfèròwérò náà pẹ̀lú àlàyé nípa báwọn èèyàn ṣe ń ti iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn.
3 Tàbí kó o sọ ọ́ báyìí:
◼ “Ẹ ǹlẹ́ ńbí o. Mò ń kọ́ ọmọbìnrin mi yìí, [dárúkọ rẹ̀], kó lè mọ bó ṣe yẹ kéèyàn máa ro tàwọn aládùúgbò rẹ̀ mọ́ tiẹ̀ ni. Ó máa fẹ́ báa yín sọ̀rọ̀ ṣókí nípa Bíbélì.” Ọmọbìnrin náà lè sọ pé: “Ọ̀nà kan tí mo fẹ́ láti máa gbà ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ni pé kí n máa ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú fún wọn. [Kí ọmọ náà ka Ìṣípayá 21:4 látinú Bíbélì tàbí kó kà á lórí.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún wa. Mo mọ̀ pé wàá gbádùn kíkà àwọn ìwé ìròyìn náà.”
4 Tẹ́ ẹ bá ń fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó ṣe ṣókí kọ́ àwọn ọmọ, á jẹ́ kí wọ́n lè ní ìgboyà láti lè sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Bí wọ́n bá ń ṣe ìdánrawò nípa bí wọ́n á ṣe máa sọ̀rọ̀ sókè lọ́nà tó lè yéni yékéyéké, á múra wọn sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀ níbikíbi àti nígbàkigbà. Tẹ́ ẹ bá sì ń jẹ́ kí wọ́n máa múra sílẹ̀ dáadáa ṣáájú àkókò, tẹ́ ẹ sì ń yìn wọ́n, á túbọ̀ ran àwọn ògo wẹẹrẹ wọ̀nyí lọ́wọ́ láti máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn.
5 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló jẹ́ pé irú ìṣírí báyìí ti mú kí wọ́n di akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa ń dùn tó báwọn ọmọ wa bá ń tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni!—Sm. 148:12, 13.
-