ORIN 10
Ẹ Yin Jèhófà Ọlọ́run Wa!
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ẹ fìyìn fún Ọlọ́run wa! - Sọ orúkọ rẹ̀ fáráyé! - Ẹ kìlọ̀ fún gbogbo èèyàn, - Pé ọjọ́ ńlá rẹ̀ ti sún mọ́lé. - Torí ìṣàkóso ọmọ rẹ̀ ti - Bẹ̀rẹ̀ bó ti ṣe sọ tẹ́lẹ̀. - A ó ròyìn rẹ̀ f’ónírúurú èèyàn, - Àti ìbùkún tó ń mú bọ̀! - (ÈGBÈ) - Ẹ fìyìn fún Ọlọ́run wa! - Ròyìn ọlá ńlá rẹ̀ fáráyé! 
- 2. Ẹ kọrin! Fi orin ayọ̀ - Gbórúkọ ńlá rẹ̀ lárugẹ! - Ọkàn wa kún fún ọpẹ́ gan-an, - À ń fìgboyà kéde ògo rẹ̀. - Jèhófà tóbi, iṣẹ́ rẹ̀ pọ̀ gan-an, - Síbẹ̀ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. - Oore rẹ̀ pọ̀ gan-an, ó máa ńtọ́jú wa, - Ó sì máa ń gbọ́ àdúrà wa. - (ÈGBÈ) - Ẹ fìyìn fún Ọlọ́run wa! - Ròyìn ọlá ńlá rẹ̀ fáráyé! 
(Tún wo Sm. 89:27; 105:1; Jer. 33:11.)