ORIN 6
Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Sáàmù 19)
- 1. Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà táà ńrí - Kéde ògo rẹ̀ gan-an - lójú òfuurufú. - Ojoojúmọ́ ni wọ́n ńfìyìn fún ọ, - Ìràwọ̀ ń fagbára rẹ hàn, - Ìfẹ́ àtọgbọ́n rẹ. 
- 2. Òfin rẹ pé, ó ń mú káyé wa dára. - Tọmọdé tàgbà ni - o sì ń fi ṣamọ̀nà. - Ìṣàkóso rẹ tọ́, òdodo ni. - Òfin rẹ mọ́, Ọ̀rọ̀ rẹ ń ṣẹ, - Wọ́n ńṣe wá láǹfààní. 
- 3. Àwọn òfin rẹ máa wúlò títí láé. - Tí a bá ń pa wọ́n mọ́, - wọ́n máa dáàbò bò wá. - Èyí ń fi hàn pé a níbẹ̀rù rẹ. - Ògo, iyì, ọlá yẹ ọ́; - A gbórúkọ rẹ ga. 
(Tún wo Sm. 111:9; 145:5; Ìfi. 4:11.)