ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÉFÉSÙ 1-3
Iṣẹ́ Àbójútó Jèhófà àti Ohun Tó Wà Fún
Jèhófà ṣètò iṣẹ́ yìí láti mú kí gbogbo ẹ̀dá rẹ̀ olóye wà ní ìṣọ̀kan.
- Ọlọ́run múra ìjọ àwọn ẹni àmì òróró sílẹ̀ láti lọ gbé lọ́run, wọ́n sì máa wà lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi tí Ọlọ́run yàn ṣe Orí wọn 
- Ọlọ́run ń múra àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé sílẹ̀, lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà 
Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ètò Jèhófà?