ORIN 46
A Dúpẹ́, Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A dúpẹ́ Jèhófà, fún ìmọ́lẹ̀ rẹ - Tó ń tàn sórí wa ní ojoojúmọ́. - A dúpẹ́ pé a lè gbàdúrà sí ọ, - Tá a lè sọ gbogbo ‘ṣòro wa fún ọ. 
- 2. A dúpẹ́ Jèhófà fọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n, - Tó fìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣẹ́gun ayé yìí. - A dúpẹ́, ò ń tọ́ wa ká lè ṣèfẹ́ rẹ, - Ká sì lè mú àwọn ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. 
- 3. A dúpẹ́ pá a láǹfààní láti wàásù - Nípa òtítọ́ àt’orúkọ rẹ. - A dúpẹ́ pé ìṣòro máa tán láìpẹ́, - Ìbùkún ‘jọba rẹ yóò wà láéláé. 
(Tún wo Sm. 50:14; 95:2; 147:7; Kól. 3:15.)