MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Bí A Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
- Ka ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí, tá a sì fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ, èyí táá jẹ́ kí onílé rí kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ náà. 
- Ka ìpínrọ̀ tó wà nísàlẹ̀ ìbéèrè náà. 
- Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fi lẹ́tà wínníwínní kọ, kó o sì fi ọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí onílé rí bí Ìwé Mímọ́ ṣe dáhùn ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí náà. 
- O lè tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà ní kókó 2 àti 3 tí ìbéèrè náà bá ní ìpínrọ̀ míì. Tí fídíò kan bá wà lórí ìkànnì jw.org/yo tó bá ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí tí ẹ̀ ń jíròrò mu, o lè fi han ẹni náà láàárín kan nínú ìjíròrò yín. 
- Sọ pé kí onílé dáhùn ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí kó o lè mọ̀ bóyá ó ti lóye ohun tẹ́ ẹ kọ́.