ORIN 18
A Mọyì Ìràpadà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A wá síwájú rẹ - lónìí yìí, Jèhófà, - Torí ìfẹ́ tó ga jù - tí o fi hàn sí wa. - O fọmọ rẹ ọ̀wọ́n rúbọ, - ká lè ríyè. - Ẹ̀bùn tó ga jù lọ táa lè - rí gbà lèyí jẹ́. - (ÈGBÈ) - Ẹ̀jẹ̀ tó ṣe iyebíye - ni Jésù fi rà wá pa dà. - Títí ayé, - la ó máa dúpẹ́ oore ńlá tóo ṣe yìí. 
- 2. Ikú àtẹ̀ṣẹ̀ sọ wá - d’aláìnírètí. - Torí ìfẹ́ ni Jésù - ṣe fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. - A ti wá nírètí - ìyè àìnípẹ̀kun. - Ó ti dá wa nídè, - a ti bọ́ lọ́wọ́ ikú. - (ÈGBÈ) - Ẹ̀jẹ̀ tó ṣe iyebíye - ni Jésù fi rà wá pa dà. - Títí ayé, - la ó máa dúpẹ́ oore ńlá tóo ṣe yìí. 
(Tún wo Héb. 9:13, 14; 1 Pét. 1:18, 19.)