ORIN 20
O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Nígbà tó dà bíi pé - Kò sírètí fún wa, - Jèhófà fi ẹ̀jẹ̀ - Ọmọ rẹ̀ rà wá! - Gbogbo ìgbé ayé - Wa lá ó máa fi sìn ọ́; - A ó sì sọ fáráyé, - Kí ìfẹ́ rẹ lè ṣẹ. - (ÈGBÈ) - Títí ayérayé, - A ó pa ohùn wa pọ̀ - Láti máa kọrin ọpẹ́ - pó o fún wa lọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n. 
- 2. Àánú rẹ, inúure, - Ń mú kí a sún mọ́ ọ. - À ń fi orúkọ rẹ - Pè wá, ó wù wá. - Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tó ga, - Tó ṣeyebíye jù - Ni ikú Ọmọ rẹ - Tó jẹ́ ká lè ríyè. - (Ègbè) - Títí ayérayé, - A ó pa ohùn wa pọ̀ - Láti máa kọrin ọpẹ́ - pó o fún wa lọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n. - (ÌLÀ ÀKỌPARÍ) - À ń fàdúrà dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà. - O ṣeun tí o fún wa ní Ọmọ rẹ ọ̀wọ́n. 
(Tún wo Jòh. 3:16; 15:13.)