ORIN 106
Bá A Ṣe Lè Ní Ìfẹ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. À ń gbàdúrà s’Ọ́lọ́run wa pé - Ká lè f’ànímọ́ rẹ̀ ṣèwà hù. - Ìfẹ́ ló gbawájú nínú wọn; - Ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́. - Bá a tiẹ̀ lẹ́bùn, tá a sì nígboyà, - Tá a nímọ̀, àmọ́ tá a kò nífẹ̀ẹ́, - Asán ni gbogbo ẹ̀bùn náà jẹ́. - Torí náà, kífẹ̀ẹ́ máa darí wa. 
- 2. Ìfẹ́ máa ń fúnni látọkàn wá. - Ìfẹ́ kì í mọ tara rẹ̀ nìkan. - Kì í fàyè gba èrò tí kò dáa; - Ó ń mú ká máa dárí jira wa. - Ìfẹ́ ń fara da ohun gbogbo; - Ó ń jẹ́ ká lè gbẹ́rù tó wúwo. - Ká fìfẹ́ hàn ní gbogbo ọ̀nà; - Ìfẹ́ tòótọ́ kò ní yẹ̀ láéláé. 
(Tún wo Jòh. 21:17; 1 Kọ́r. 13:13; Gál. 6:2.)