ORIN 15
Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ẹ yin Jésù Kristi, - Àkọ́bí Ọlọ́run wa. - Jèhófà ti fi jọba, - Yóò sì bù kún aráyé. - Yóò jẹ́ kó hàn gbangba pé - Jèhófà l’Aláṣẹ. - Yóò dá Jèhófà láre - Torí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. - (ÈGBÈ) - Ẹ yin Jésù Kristi, - Àkọ́bí Ọlọ́run wa! - Ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀. - Ó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in! 
- 2. Ẹ yin Jésù Kristi, - Tó kú ká lè ní ìyè. - Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ rà wá - Ká lè rí ‘dáríjì gbà. - Jésù máa tó gbéyàwó, - Aya rẹ̀ ti ṣe tán. - Gbogbo ẹ̀dá yóò wá mọ̀ - P’Ọ́lọ́run laláṣẹ. - (ÈGBÈ) - Ẹ yin Jésù Kristi, - Àkọ́bí Ọlọ́run wa! - Ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀. - Ó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in!