ORIN 60
Wọ́n Máa Rí Ìyè Tí Wọ́n Bá Gbọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Lákòókò tá a wà yìí, - gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́ - Pé ọjọ́ ìbínú Jáà - máa dé, kò ní pẹ́ mọ́. - (ÈGBÈ) - Wọ́n máa ríyè, tí wọ́n bá gbọ́. - Àwa náà sì máa ríyè. - Ìgbọràn wọn ṣe pàtàkì. - Dandan ni ká sọ fáráyé, - Dandan ni. 
- 2. Ohun kan wà tí à ńsọ - fún gbogbo aráyé. - À ń pe gbogbo èèyàn wá - di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. - (ÈGBÈ) - Wọ́n máa ríyè, tí wọ́n bá gbọ́. - Àwa náà sì máa ríyè. - Ìgbọràn wọn ṣe pàtàkì. - Dandan ni ká sọ fáráyé, - Dandan ni. - (ÀSOPỌ̀) - Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì. - Ká tètè lọ, ká sọ fún wọn. - Ká kọ́ wọn ní òtítọ́ - Tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ríyè. - (ÈGBÈ) - Wọ́n máa ríyè, tí wọ́n bá gbọ́. - Àwa náà sì máa ríyè. - Ìgbọràn wọn ṣe pàtàkì. - Dandan ni ká sọ fáráyé, - Dandan ni. 
(Tún wo 2 Kíró. 36:15; Àìsá. 61:2; Ìsík. 33:6; 2 Tẹs. 1:8.)