Orin 144
Wọ́n Á Rí Ìgbàlà
- Lákòókò àánú - Ọlọ́run yìí, ká sọ fáyé - Pé ọjọ́ ìbínú - rẹ̀ yóò dé, ó ti dé tán. - (ÈGBÈ) - Jáà yóò gbà wọ́n, ṣáwọn nìkan? - Àwa náà máa rígbàlà. - Wọ́n á rígbàlà, tí wọ́n bá gbọ́, - Dandan ni ká sọ fáráyé; - Dandan ni. 
- Iṣẹ́ kan wà tó, - yẹ ká jẹ́ fún gbogbo ayé. - À ń pe gbogbo èèyàn - kí wọ́n dọ̀rẹ́ Ọlọ́run. - (ÈGBÈ) - Jáà yóò gbà wọ́n, ṣáwọn nìkan? - Àwa náà máa rígbàlà. - Wọ́n á rígbàlà, tí wọ́n bá gbọ́, - Dandan ni ká sọ fáráyé; - Dandan ni. - (ÌSOPỌ̀) - Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì, - Kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n bàa lè yè. - À ń kọ́ wọn, à ń sọ fún wọn; - À ń kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ ìyè. - (ÈGBÈ) - Jáà yóò gbà wọ́n, ṣáwọn nìkan? - Àwa náà máa rígbàlà. - Wọ́n á rígbàlà, tí wọ́n bá gbọ́, - Dandan ni ká sọ fáráyé; - Dandan ni. 
(Tún wo 2 Kíró. 36:15; Aísá. 61:2; Ìsík. 33:6; 2 Tẹs. 1:8.)