ORIN 44
Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ẹ̀dùn ọkàn mi pọ̀, ọrùn wọ̀ mí, - ayé sú mi. - Jèhófà, jọ̀wọ́, “Gbọ́ àdúrà mi,” - ràn mí lọ́wọ́. - Àròkàn mú mi sọ̀rètí nù, - mo rora mi pin. - Ọlọ́run ìtùnú, jọ̀ọ́ fi - ojúure hàn sí mi. - (ÈGBÈ) - Fún mi lókun, kí n má bọ́hùn, - Tíyèméjì bá fẹ́ bò mí. - Ràn mí lọ́wọ́; mo sá di ọ́. - Ọlọ́run mi, fún mi lókun. 
- 2. Bíbélì máa ń tù mí nínú - tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì. - Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tí mò ń kà - máa ń mọ́kàn mi fúyẹ́. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé ọ, - kí n sì nígbàgbọ́. - Kí n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ mi gan-an - ju bí mo ṣe rò lọ. - (ÈGBÈ) - Fún mi lókun, kí n má bọ́hùn, - Tíyèméjì bá fẹ́ bò mí. - Ràn mí lọ́wọ́; mo sá di ọ́. - Ọlọ́run mi, fún mi lókun. 
(Tún wo Sm. 42:6; 119:28; Róòmù 8:26; 2 Kọ́r. 4:16; 1 Jòh. 3:20.)