ORIN 134
Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí
- 1. Tí tọkọtaya bá bímọ, - Tí àwọn méjèèjì wá di òbí, - Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà fún wọn - Pé kí wọ́n tọ́jú ọmọ náà. - Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni. - Òun ló dá wa, ó sì ní ìfẹ́ wa. - Ó fáwọn òbí ní ìtọ́ni - Kí wọ́n lè tọ́ ọmọ wọn dáadáa. - (ÈGBÈ) - Jèhófà ló ni ọmọ ‘wọ́ yín, - Ẹ̀bùn iyebíye ló jẹ́. - Ẹ̀bùn tó dáa jù tẹ́ ẹ lè fún un ni - Pé kẹ́ ẹ kọ́ ọ lófin Ọlọ́run. 
- 2. Ẹ̀yin òbí gbọ́dọ̀ máa fi - Gbogbo àṣẹ Ọlọ́run sọ́kàn yín. - Kẹ́ ẹ máa fi kọ́ àwọn ọmọ yín. - Ohun tẹ́ ẹ gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn. - Ẹ fi kọ́ wọn tẹ́ ẹ bá ń rìn lọ́nà, - Tí ẹ bá jí àti kí ẹ tó sùn. - Wọn yóò máa rántí nígbà gbogbo, - Wọn yóò sì múnú Jèhófà dùn. - (ÈGBÈ) - Jèhófà ló ni ọmọ ‘wọ́ yín, - Ẹ̀bùn iyebíye ló jẹ́. - Ẹ̀bùn tó dáa jù tẹ́ ẹ lè fún un ni - Pé kẹ́ ẹ kọ́ ọ lófin Ọlọ́run. 
(Tún wo Diu. 6:6, 7; Éfé. 6:4; 1 Tím. 4:16.)