ORIN 135
Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́bìnrin, - Múnú mi dùn. - Jẹ́ kígbèésí ayé - Rẹ bá ìfẹ́ mi mu. - Kó o lo àkókò ọ̀dọ́ - Rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n, - Kó o lè dójú tọ̀tá - Tó ń gan orúkọ mi. - (ÈGBÈ) - Àyànfẹ́ ọmọ mi ọkùnrin, - Àtolùfẹ́ ọmọbìnrin; - Jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, kó o sì fi - Ìgbésẹ̀ rẹ yìn mí lógo. 
- 2. Máa fi ayọ̀ ṣe ìfẹ́ mi - Látọkàn wá. - Jẹ́ kí àwọn èèyàn - Mọ̀ pé tèmi ni ọ́. - Ẹni fọwọ́ kàn ẹ́ - Ń wá ojú pípọ́n mi, - Bó o bá tiẹ̀ ṣubú, - Èmi yóò gbé ọ dìde. - (ÈGBÈ) - Àyànfẹ́ ọmọ mi ọkùnrin, - Àtolùfẹ́ ọmọbìnrin; - Jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, kó o sì fi - Ìgbésẹ̀ rẹ yìn mí lógo. 
(Tún wo Diu. 6:5; Oníw. 11:9; Àìsá. 41:13.)