ORIN 140
Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìn-Gbẹ́yín!
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Fi ojú inú rẹ wo - Àwọn tó ń gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀. - Kò sẹ́kún mọ́; wọ́n ń láyọ̀. - Ìrora kò sí mọ́. - (ÈGBÈ) - Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin! - Ayé tuntun dé tán. - Títí láéláé la ó máa gbé - Inú ayé tuntun. 
- 2. A ò ní máa darúgbó mọ́. - Àlàáfíà ni yóò jọba. - Wàhálà kò ní sí mọ́. - Kò ní síbẹ̀rù mọ́. - (ÈGBÈ) - Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin! - Ayé tuntun dé tán. - Títí láéláé la ó máa gbé - Inú ayé tuntun. 
- 3. A ó gbádùn Párádísè. - Ògo Jáà yóò máa tàn yòò. - Gbogbo ọjọ́ ayé wa - La ó máa kọrin ìyìn. - (ÈGBÈ) - Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin! - Ayé tuntun dé tán. - Títí láéláé la ó máa gbé - Inú ayé tuntun. 
(Tún wo Jóòbù 33:25; Sm. 72:7; Ìfi. 21:4.)