ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/22 ojú ìwé 12-17
  • Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ṣe Inúnibíni sí Wa Nítorí Ìgbàgbọ́ Wa
  • Ìdánwò ti Bàbá
  • Ẹ̀dùn Ọkàn Màmá
  • Bíbẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún
  • Ìmúni àti Ìfinisẹ́wọ̀n
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Lábọ̀ Ẹ̀wọ̀n
  • Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tí A Ṣìkẹ́
  • Mo Gbọ́kàn Lé Jèhófà Pé Á Bójú Tó Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Kí Ni Mo Lè San Pa Dà Fún Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà Láti Ìgbà Èwe Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Mímú Ìlérí Mi Láti Sin Ọlọ́run Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/22 ojú ìwé 12-17

Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́

GẸ́GẸ́ BÍ HORST HENSCHEL ṢE SỌ Ọ́

“Kí inú rẹ dùn bí o bá rí lẹ́tà yìí gbà, nítorí pé mo ti forí tì í dé òpin. Ní wákàtí méjì sí ìsinsìnyí, wọn yóò pa mí.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí Bàbá fi bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tí ó kọ sí mi kẹ́yìn nìwọ̀nyẹn. Ní May 10, 1944, wọ́n pa á nítorí pé ó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hitler. Bí ó ṣe dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run, àti bí màmá mi àti arábìnrin mi, Elfriede, ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ ti nípa gidigidi lórí ìgbésí ayé mi.

NÍ 1932, ní déédéé àkókò tí a bí mi, Bàbá bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìtẹ̀jáde Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó rí àgàbàgebè àwùjọ àlùfáà àti àwọn nǹkan mìíràn. Ní ìyọrísí rẹ̀, kò ní ọkàn ìfẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì mọ́.

Wọ́n fi Bàbá sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Germany láìpẹ́ tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní 1939. Ó sọ fún Màmá pé: “Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti fi hàn, n kò gbọ́dọ̀ lọ. Ìpànìyàn yìí kò tọ́.”

Màmá fèsì pé: “Bí o kò bá lọ, wọn óò pa ọ́. Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sí ìdílé rẹ?” Nítorí náà, Bàbá di ọmọ ogun.

Lẹ́yìn náà ni Màmá, tí kò tí ì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí dìgbà náà, gbìyànjú láti kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìgbìyànjú kan tó léwu gan-an nígbà náà. Ó rí Dora, tí ọkọ rẹ̀ wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan nígbà náà nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Dora fún un ní ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan, ṣùgbọ́n ó lahùn fún Màmá pé: “Fi sọ́kàn pé a lè pa mí bí àwọn Gestapo (ọlọ́pàá inú) bá mọ̀ pé èmi ni mo fi èyí fún ọ.”

Níkẹyìn, Màmá gba àwọn ìtẹ̀jáde Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí i, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mọyì àwọn òtítọ́ Bíbélì tó wà nínú wọn. Láìpẹ́, Max Ruebsam, tó wá láti Dresden tó wà nítòsí, bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ wá wò nínú ilé wa ní Meissen. Ó bá wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní fífi ààbò ara rẹ̀ wewu gidigidi. Ní tòótọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi mú un.

Ní ìyọrísí bí Màmá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún un, ní fífi èyí hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi ní May, 1943. Èmi àti Bàbá ṣèrìbọmi lóṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà. Elfriede, arábìnrin mi, ọmọ 20 ọdún, tó ń ṣiṣẹ́ ní Dresden pẹ̀lú, ṣèrìbọmi ní déédéé àkókò kan náà. Nípa bẹ́ẹ̀, ní àárín Ogun Àgbáyé Kejì gan-an, àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà. Ní 1943, Màmá bí àbúrò wa obìnrin tó kéré jù, Renate.

A Ṣe Inúnibíni sí Wa Nítorí Ìgbàgbọ́ Wa

Kí n tó ṣèrìbọmi, mo yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Hitler. Nígbà tí mo kọ̀ láti lo ìkíni Hitler, tí a béèrè fún lójoojúmọ́ nílé ẹ̀kọ́, àwọn olùkọ́ mi lù mí. Bí ó ti wù kí ó rí, mo láyọ̀ láti mọ̀ pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí mi ti fún mi lókun, mo ti dúró ṣinṣin.

Ṣùgbọ́n, bóyá nítorí ìjìyà ti ara tàbí nítorí ìbẹ̀rù, àwọn ìgbà kan wà tí mo máa ń wí pé “Heil Hitler!” N óò wá sunkún relé, àwọn òbí mi yóò sì gbàdúrà pọ̀ pẹ̀lú mi pé kí n lè ní ìgboyà kí n sì dojú kọ ìkọlù ọ̀tá náà nígbà mìíràn. Nítorí ìbẹ̀rù, mo fà sẹ́yìn láti ṣe ohun tí ó tọ́ ju ìgbà kan lọ, ṣùgbọ́n Jèhófà kò kọ̀ mí sílẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, àwọn Gestapo wá, wọ́n sì tú ilé wa wò. Aṣojú Gestapo kan bi Màmá pé: “Ṣé ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́?” Mo ṣi lè rí bí Màmá ṣe fara ti àtẹ́rígbà ilẹ̀kùn, tí ó sì sọ láìmikàn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni”—bí ó tilẹ̀ mọ̀ pé èyí túmọ̀ sí pé wọn yóò wá mú òun nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, Màmá ń ṣètọ́jú Renate, tí kò ì pé ọmọ ọdún kàn lọ́wọ́, nígbà tí àwọn Gestapo dé láti mú un. Màmá sọ pé: “Mo ń fún ọmọ mi lóúnjẹ lọ́wọ́!” Bí ó ti wù kí ó rí, obìnrin tí o bá ọlọ́pàá náà wá gba ọmọ náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì pàṣẹ pé: “Ó yá! Máa lọ.” Ó dájú pé kò rọrùn fún Màmá.

Níwọ̀n bí wọn kò tí ì mú Bàbá, èmi àti àbúrò mi obìnrin wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀. Ní àárọ̀ ọjọ́ kan, ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí wọ́n ti mú Màmá lọ, mo gbá Bàbá mọ́ra típẹ́típẹ́ kí n tó lọ sílé ẹ̀kọ́. Ọjọ́ náà ni wọ́n wá mú Bàbá nítorí pé ó kọ̀ láti padà sẹ́nu iṣẹ́ ológun. Nítorí náà, nígbà tí mo padà délé lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn, wọ́n ti mú un lọ, n kò sì tún padà rí i mọ́.

Àwọn òbí mi àgbà àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa tó kù—tí gbogbo wọn kò fara mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí àwọn kan nínú wọn sì jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Nazi—bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó èmi àti àbúrò mi. Wọn kò yọ̀ǹda fún mi láti ka Bíbélì. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo ti yọ́ gba ẹ̀dà kan lọ́dọ̀ obìnrin kan ládùúgbò, n óò kà á. N óò tún kúnlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì àbúrò mi, n óò sì gbàdúrà.

Láàárín àkókò kan náà, arábìnrin mi, Elfriede, ti forí ti àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó kọ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nìṣó nílé iṣẹ́ kan tí ń ṣe àwọn nǹkan ìjà ogun ní Dresden, ṣùgbọ́n ó ṣàṣeyọrí láti rí iṣẹ́ bíbójútó àwọn ọgbà ohun alààyè àti ọgbà ìtura ní Meissen. Nígbà tí ó bá lọ gba owó rẹ̀ ní ọ́fíìsì, ó ń kọ̀ láti kí ni pé “Heil Hitler!” Láìpẹ́, wọ́n mú un, wọ́n sì tì í mọ́lé.

Lọ́nà oníjàábá, àrùn gbọ̀fungbọ̀fun àti akọ ibà mú Elfriede, ó sì kú ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n tì í mọ́lé. Ọmọ ọdún 21 péré ni. Nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tó kọ kẹ́yìn, ó fa ọ̀rọ̀ Lúùkù 17:10 yọ pé: “Nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn lé yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun: ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’” Bí ó ṣe dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run ti ń jẹ́ ìrànlọ́wọ́ afúnnilókun fún mi nígbà gbogbo.—Kólósè 4:11.

Ìdánwò ti Bàbá

Láàárín àkókò tí Bàbá wà lẹ́wọ̀n, bàbá mi àgbà—bàbá ìyá mi—lọ bẹ̀ ẹ́ wò láti gbìyànjú láti mú kí ó yí ọkàn rẹ̀ padà. Pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀ ni wọ́n mú Bàbá déwájú rẹ̀. Láìyẹhùn, Bàbá kọ gbogbo ìdámọ̀ràn pé kí ó gba iṣẹ́ ológun nítorí àwọn ọmọ rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ẹ̀wọ̀n náà sọ fún Bàbá Àgbà pé: “Bí ọkùnrin yìí bá tilẹ̀ ní ọmọ mẹ́wàá, síbẹ̀síbẹ̀, kò ní yí padà.”

Tìbínú-tìbínú ni Bàbá Àgbà padà délé. Ó ń pariwo pé: “Ọ̀daràn yìí! Aláìwúlò kan lásánlàsàn yìí! Báwo ló ṣe lè pa àwọn ọmọ ara rẹ̀ tì?” Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé inú bí Bàbá Àgbà, inú tèmi dùn láti mọ̀ pé Bàbá dúró ṣinṣin síbẹ̀.

Níkẹyìn, wọ́n dájọ́ ikú fún Bàbá, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí. Ní àkókò kan lẹ́yìn náà, mo gba lẹ́tà ìkẹyìn tí ó kọ yẹn. Níwọ̀n bí kò ti mọ ẹ̀wọ̀n tí Màmá wà, èmi ló kọ̀wé sí. Mo wọ iyàrá tí mo ń sùn sí lọ, mo sì ka àwọn ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà náà tí a fà yọ nínú ìnasẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Inú mi bà jẹ́, mo sì sunkún, ṣùgbọ́n mo láyọ̀ láti mọ̀ pé ó ti dúró ṣinṣin ti Jèhófà.

Ẹ̀dùn Ọkàn Màmá

Wọ́n ti fi Màmá sẹ́wọ̀n ní gúúsù Germany de ìgbà ìgbẹ́jọ́ rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ẹ̀ṣọ́ kan wọ iyàrá ẹ̀wọ̀n rẹ̀ lọ, ó sì sọ lọ́nà ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pé kí Màmá jókòó. Ṣùgbọ́n Màmá dìde dúró, ó sì wí pé: “Mo mọ̀ pé wọ́n ti pa ọkọ mi.” Lẹ́yìn náà, wọ́n kó aṣọ Bàbá tí ẹ̀jẹ̀ ti bà jẹ́ ránṣẹ́ sí Màmá, ẹ̀rí ìyà tí o ti jẹ kí wọ́n tó pà á.

Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, wọ́n pe Màmá lọ sí ọ́fíìsì ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì sọ fún un ṣákálá pé: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Báwo lo ṣe fẹ́ ká sin òkú rẹ̀?” Ìtúfọ̀ náà bá Màmá lójijì, kò sì retí rẹ̀, tí kò fi kọ́kọ́ mọ ohun tí ó lè sọ. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ lílágbára tí ó ní nínú Jèhófà fún un lókun.

Ní gbogbogbòò, àwọn ìbátan mi bójú tó èmi àti àbúrò mi dáradára. Wọ́n ní inú rere sí wa. Ní gidi, ọ̀kan lára wọn kàn sí àwọn olùkọ́ mi, ó sì bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n mú sùúrù fún mi. Nítorí náà, àwọn olùkọ́ náà di ẹni bí ọ̀rẹ́ gan-an, wọn kì í sì í jẹ mí níyà bí mo bá kùnà láti kí wọn pé “Heil Hitler!” Ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣe gbogbo inú rere yìí láti yí mi lọ́kàn padà kúrò nínú ìgbàgbọ́ mi lílágbára tí a gbé karí Bíbélì. Ó sì bani nínú jẹ́ pé wọ́n ṣàṣeyọrí dé àyè kan.

Ní oṣù díẹ̀ kí ogun náà tó parí ní May 1945, mo yọ̀ǹda ara mi láti lọ síbi àwọn iṣẹ́ àjọ Ọ̀dọ́ Nazi kan. Mo kọ̀wé sí Màmá nípa èyí, ohun tí ó kà nínú lẹ́tà mi sì fún un ní èrò pé mo ti pa ìlépa mi láti sin Jèhófà tì. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé, àwọn lẹ́tà wọ̀nyí da òun lọ́kàn rú ju gbígbọ́ tí òun gbọ́ nípa ikú Bàbá àti Elfriede lọ.

Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ogun parí, Màmá padà dé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti tún jèrè ìwàdéédéé mi nípa tẹ̀mí.

Bíbẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Nígbà tí 1949 ń parí lọ, ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, alábòójútó arìnrìn-àjò kan jíròrò ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú Málákì 3:10 pé: “‘Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, kí oúnjẹ bàa lè wà nínú ilé mi; kí ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò nínú ọ̀ràn yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” Ó mú kí n fọwọ́ sí ìwé ìwọṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún. Nípa bẹ́ẹ̀, ní January 1, 1950, mo di aṣáájú ọ̀nà, bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lẹ́yìn náà, mo kó lọ sí Spremberg, níbi tí a ti nílò àwọn aṣáájú ọ̀nà púpọ̀ sí i.

Ní August ọdún yẹn, mo gba ìkésíni kan láti wá ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Magdeburg, ní Ìlà Oòrùn Germany. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọjọ́ méjì péré lẹ́yìn tí mo débẹ̀, ní August 31, àwọn ọlọ́pàá ya dé orí ilẹ̀ wa, tí wọ́n sọ pé àwọn ọ̀daràn fara pa mọ́ síbẹ̀. Wọ́n mú ọ̀pọ̀ jù lọ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n sì kó wọn lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, ṣùgbọ́n mo rọ́nà sá lọ, mo sì rinrin àjò lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Berlin, níbi tí Watch Tower Society ní ọ́fíìsì kan sí. Níbẹ̀, mo sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Magdeburg. Nígbà kan náà, wọ́n sọ fún mi pé ńṣe ni wọ́n ń mú Àwọn Ẹlẹ́rìí jákèjádò Ìlà Oòrùn Germany. Kódà, mo gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá ń wá mi ní Spremberg lọ́hùn-ún!

Ìmúni àti Ìfinisẹ́wọ̀n

A yàn mí sí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Ìlà Oòrùn Berlin. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí mo ń kó ẹrù ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti Ìwọ̀ Oòrùn Berlin lọ sí Ìlà Oòrùn Germany, wọ́n mú mi, wọ́n sì gbé mi lọ sí ìlú ńlá Cottbus, níbi tí wọ́n ti gbẹ́jọ́ mi, tí wọn sì fi mí sẹ́wọ̀n ọdún 12.

Láfikún sí àwọn ohun mìíràn, wọ́n fẹ̀sùn dídógunsílẹ̀ kàn mí. Níbi ìgbẹ́jọ́ mi, mo sọ nínú ọ̀rọ̀ ìkẹyìn mi pé: “Báwo ni èmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lè jẹ̀bi gẹ́gẹ́ bí adógunsílẹ̀, nígbà tí bàbá mi kọ̀ láti kópa nínú ogun nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ẹ sì tìtorí rẹ̀ bẹ́ ẹ lórí?” Àmọ́, dájúdájú, àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn kò lọ́kàn ìfẹ́ sí òtítọ́.

Kò rọrùn fún mi láti ronú bí èmi tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 19 ṣe lè lọ sẹ́wọ̀n ọdún 12. Síbẹ̀, mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ti gba irú ìdájọ́ kan náà. Nígbà mìíràn, àwọn aláṣẹ máa ń ya Àwọn Ẹlẹ́rìí nípa kúrò lọ́dọ̀ ara wọn; ṣùgbọ́n nígbà náà, a óò bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn jíròrò òtítọ́ Bíbélì, àwọn díẹ̀ sì di Ẹlẹ́rìí.

Ní àwọn àkókò mìíràn, wọ́n ń kó àwa Ẹlẹ́rìí sí agbo ilé ẹ̀wọ̀n kan náà. A máa ń pọkàn pọ̀ sórí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lọ́nà sísunwọ̀n sí i nígbà náà. A ń kọ́ odindi orí Bíbélì sórí, a sì tilẹ̀ gbìyànjú láti kọ́ àwọn odindi ìwé Bíbélì sórí. A gbé àwọn góńgó ohun tí a ní láti ṣe kí a sì kọ́ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ara wa. Nígbà mìíràn, ọwọ́ wa máa ń dí tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnì kíní wa ń sọ fún èkejì pé “A kò ráyè,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn iyàrá ẹ̀wọ̀n wa la wà látàárọ̀ ṣúlẹ̀ láìsí pé wọ́n yan iṣẹ́ kankan fún wa láti ṣe!

Ìwádìí tí àwọn ọlọ́pàá inú náà ń ṣe lè tánni lókun. Wọ́n lè máa bá a lọ tọ̀sántòru, ní lílo onírúurú ìhalẹ̀mọ́ni. Nígbà kan, ó rẹ̀ mí gidigidi, ó sì sú mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣòro fún mi láti gbàdúrà pàápàá. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta, láìsí ìdí gúnmọ́ kankan, mo yọ bébà nínípọn tí wọ́n kọ àwọn òfin ẹ̀wọ̀n sí, tó wà lára ògiri iyàrá ẹ̀wọ̀n tí mo wà kúrò lára ògiri. Bí mo ti yí i sẹ́yìn, mo rí ohun kan tí wọ́n kọ síbẹ̀. Bí mo ṣe gbé e sí ojú ìwọ̀nba ìmọ́lẹ̀ tó wà níbẹ̀, mo rí àwọn ọ̀rọ̀ náà: “Má bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara,” àti “N ó pa ìránṣẹ́ olóòótọ́ mọ́, bíi ti ẹyin ojú mi.” Ìwọ̀nyí jẹ́ apá kan ọ̀rọ̀ orin nọ́ńbà 27 nínú ìwé orin Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nísinsìnyí!

Ó ṣe kedere pé arákùnrin mìíràn ní irú ipò kan náà ti wà nínú iyàrá ẹ̀wọ̀n yìí rí, Jèhófà Ọlọ́run sì ti fún un lókun. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo tún lókun tẹ̀mí padà, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìṣírí yìí. N kò fẹ́ láti gbàgbé ẹ̀kọ́ yìí nígbà kankan, nítorí pé ó kọ́ mi pé, bí n kò tilẹ̀ lè kẹ́sẹ járí nípasẹ̀ okun tèmi fúnra mi, kò sí ohun tí kò ṣeé ṣe pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà Ọlọ́run.

Màmá ti kó lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Germany, nítorí náà, kò gbọ́ nípa mi rárá ní àkókò náà. Bí ó ti wù kí ó rí, Hanna, ẹni tí a ti jùmọ̀ dàgbà nínú ìjọ kan náà, tí ó sì sún mọ́ ìdílé wa dáradára, wà níbẹ̀. Ó bẹ̀ mí wò ní gbogbo ọdún tí mo fi wà lẹ́wọ̀n wọ̀nyẹn, ó sì kọ àwọn lẹ́tà afúnnilókun sí mi, bẹ́ẹ̀ ni ó fi àwọn ẹrù oúnjẹ wíwúlò ránṣẹ́ sí mi. Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n ní 1957, lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún 6 nínú ọdún 12 tí wọ́n dá fún mi tẹ́lẹ̀, mo gbé e níyàwó.

Gẹ́gẹ́ bí aya mi ọ̀wọ́n, Hanna ti fìdúróṣinṣin sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú mi nínú oríṣiríṣi iṣẹ́ àyànfúnni wa, ó sì ti jẹ́ alátìlẹ́yìn gidigidi fún mi. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni ó lè san èrè fún un ní ti àwọn ohun tí ó ti ṣe nítorí mi jálẹ̀jálẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí a jọ ń ṣe.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Lábọ̀ Ẹ̀wọ̀n

Èmi àti Hanna jọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní ọ́fíìsì tí Watch Tower Society ń lò nígbà náà ní Ìwọ̀ Oòrùn Berlin. Wọ́n yàn mí sí iṣẹ́ ìkọ́lé níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi gbẹ́nàgbẹ́nà kan. Lẹ́yìn náà, a jọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Ìwọ̀ Oòrùn Berlin.

Willi Pohl, tí ń bójú tó iṣẹ́ wa ní Ìwọ̀ Oòrùn Berlin nígbà náà, fún mi níṣìírí láti tẹ̀ síwájú láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Mo dáhùn pé: “N kò ráyè.” Síbẹ̀, ẹ wo bí mo ti láyọ̀ tó pé mo ṣègbọràn láti máa kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì nìṣó! Àbáyọrí rẹ̀ ni pé, ní 1962, a pè mí sí ẹ̀kọ́ olóṣù mẹ́wàá ti kíláàsì kẹtàdínlógójì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, ní Brooklyn, New York. Lẹ́yìn tí mo padà sí Germany ní December 2, 1962, èmi àti Hanna lo ọdún 16 nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò, ní bíbẹ àwọn ìjọ wò jákèjádò Germany. Lẹ́yìn náà, ní 1978, wọ́n ké sí wa láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Wiesbaden. Nígbà tí a kó iṣẹ́ ẹ̀ka náà lọ sí ilé lílò ńlá tuntun ní Selters ní àárín àwọn ọdún 1980, a ṣiṣẹ́ ní ilé lílò rírẹwà yẹn fún ọdún mélòó kan.

Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tí A Ṣìkẹ́

Ní 1989, ohun kan tí a kò retí rárá ṣẹlẹ̀—Ògiri Berlin wó, Àwọn Ẹlẹ́rìí ní àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìlà Oòrùn Yúróòpù sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn òmìnira ìjọsìn. Ní 1992, wọ́n ké sí èmi àti Hanna láti lọ sí Lviv, ní Ukraine, láti ṣètìlẹ́yìn fún iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba tí ń pọ̀ sí i ní àgbègbè yẹn.

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ní kí a lọ sí Rọ́ṣíà láti ṣèrànwọ́ nínú ìṣètò iṣẹ́ Ìjọba náà níbẹ̀. Nígbà náà ni a kọ́ ọ́fíìsì kan sí Solnechnoye, abúlé kan tí ó tó 40 kìlómítà lẹ́yìn ìlú St. Petersburg, láti máa bójú tó iṣẹ́ ìwàásù náà jákèjádò ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira mìíràn tó wà lára Soviet Union àtijọ́. Nígbà tí a gúnlẹ̀ síbẹ̀, iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn ilé ibùgbé àti ilé ńlá kan fún ọ́fíìsì àti ibi ìkóǹkansí.

Ayọ̀ wa kún rẹ́rẹ́ nígbà ìyàsímímọ́ ẹ̀ka wa tuntun ní June 21, 1997. Àpapọ̀ 1,492 ènìyàn láti orílẹ̀-èdè 42 ló pé jọ sí Solnechnoye fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ àrà ọ̀tọ̀ náà. Lọ́jọ́ kejì, ògìdìgbó ènìyàn tí ó lé ní 8,400 pé jọ ní Pápá Ìṣeré ní Petrovsky ní St. Petersburg, fún àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà àti àwọn ìròyìn afúnni-níṣìírí láti ẹnu àwọn olùbẹ̀wò tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Ẹ wo bí ìbísí tí a ti ń gbádùn ní àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira 15 tó wà lára Soviet Union àtijọ́ ṣe gadabú tó! Ní 1946, nǹkan bí 4,800 olùpòkìkí Ìjọba ló ń wàásù ní àgbègbè ìpínlẹ̀ yìí. Ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 40 ọdún lẹ́yìn náà, ní 1985, iye náà ti lọ sókè sí 26,905. Lónìí, àwọn olùpòkìkí Ìjọba ní àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó wà lára Soviet Union àtijọ́, tí ẹ̀ka wa níhìn-ín ní Solnechnoye ń bójú tó, lé ní 125,000, àwọn tó ń wàásù ní àwọn ilẹ̀ olómìnira márùn-ún yòókù tó wà lára Soviet àtijọ́ sì lé ní 100,000! Ẹ wo bí a ti láyọ̀ tó láti mọ̀ pé ní àwọn ilẹ̀ olómìnira 15 tó wà lára Soviet àtijọ́, àwọn ènìyàn tó pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ní March to kọjá lé ní 600,000!

Ó máa ń yà mí lẹ́nu nígbà tí mo bá rí bí Jèhófà Ọlọ́run ti ṣe darí ìkójọ àti ìṣètò àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà kíkọyọyọ tó ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (2 Tímótì 3:1) Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù inú Bíbélì náà ṣe wí, Jèhófà ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye, ó ń fún wọn ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí wọn yóò máa tọ̀, ó sì ń fún wọn ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú rẹ̀ lára wọn. (Sáàmù 32:8) Mo kà á sí àǹfààní kan láti jẹ́ ara ètò àjọ àwọn ènìyàn Jèhófà kárí ayé!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Èmi àti àwọn arábìnrin mi méjèèjì, ní 1943

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Wọ́n bẹ́ Bàbá lórí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Màmá ràn mí lọ́wọ́ láti tún jèrè ìwàdéédéé nípa tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Èmi àti ìyàwó mi, Hanna

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Nígbà ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ẹ̀ka ti Rọ́ṣíà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àgbàlá àti àwọn fèrèsé ilé oúnjẹ ní ẹ̀ka wa tuntun ní Rọ́ṣíà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́