ORIN 142
Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọ̀pọ̀ ọdún laráyé ti wà lókùnkùn. - Gbogbo ìsapá wọn lórí asán ni. - Aráyé kò lè gbara wọn là rárá; - Torí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wọn. - (ÈGBÈ) - Kọrin ayọ̀, Ìjọba náà dé tán! - Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. - Àkóso rẹ̀ yóò mú ìtura wá; - Fọkàn balẹ̀, má ṣe sọ̀rètí nù láé. 
- 2. À ń kéde pé ọjọ́ Ọlọ́run sún mọ́lé! - Gbogbo ìlérí Ọlọ́run ló máa ṣẹ. - Kò ní síbànújẹ́ mọ́ fún aráyé. - Kọrin ìyìn s’Olódùmarè. - (ÈGBÈ) - Kọrin ayọ̀, Ìjọba náà dé tán! - Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. - Àkóso rẹ̀ yóò mú ìtura wá; - Fọkàn balẹ̀, má ṣe sọ̀rètí nù láé. 
(Tún wo Sm. 27:14; Oníw. 1:14; Jóẹ́lì 2:1; Háb. 1:2, 3; Róòmù 8:22.)